Agbébọn ṣíná ìbọn bolẹ̀ níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, èèyàn mẹ́tàlá jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ Hunduras, Xiomara Castro, kede ofin konile-o-gbele lẹyin ti agbebọn kan dede ṣina ibọn bolẹ nibi ayẹyẹ ọjọ ibi, ti eeyan mẹtala si di doloogbe.
Ọkunrin mejila ati obinrin kan lo ba iṣẹlẹ naa lọ lasiko ti wọn n gbadun ayẹyẹ ọjọ ibi naa lọwọ.
Yatọ si awọn mẹtala yii, wọn tun ṣekupa awọn eeyan mi lagbegbe Sula Valley, eyii to mu ki apapọ iye eeyan ti wọn pa lọjọ naa jẹ ogun.
Ijọba orilẹ-ede naa sọ pe o ṣeeṣe ki iṣẹlẹ ọhun lọwọ awọn to n gbe egboogi oloro ninu.
O ti wa kede igbele lati aago mẹsan an alẹ si aago mẹrin owurọ fun o kere tan, ọjọ marundinlogun gbako bayii.
Ijọba fi kun pe igbele naa yoo tan de ilu San Pedro Sula lọjọ kẹrin, oṣu to n bọ.
Castro ni igbesẹ naa ko ṣẹyin ati fopin si iṣekupani lọna aitọ ti awọn to n gbe oogun oloro n da silẹ.
O ni “a ti gbe igbesẹ lati maa mu awọn ti a fura si.”
O fi kun pe ijọba yoo tun da ẹgbẹrun kan awọn agbofinro si agbegbe ti ikọlu naa ti waye, awọn yoo tun fun ẹnikẹni to ba le ṣe amọna bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn afurasi ọhun ni owo ti iye rẹ to ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn dọla.
Honduras jẹ orilẹ-ede kan ti awọn to n gbe oogun oloro maa n lo lọpọ igba.
Awọn to n gbe ogun oloro tun maa n lo awọn orilẹ-ede mii to sunmọ Honduras bii El Savador ati Guatemala lati maa ko egboogi oloro wọ ilẹ Amẹrika.
Ẹwẹ, iṣẹlẹ yii lo waye lẹyin ọsẹ kan ti awọn agbebọn kan ṣina ibọn bole niluu Tegucigalpa, nibi ti obinrin mẹrindinlogoji ti jade laye.












