Wo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣe àtàwọn èyí tó lulẹ̀ nípa Tinubu ṣáájú ìbúrawọlé rẹ̀

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, @officialABAT

Bola Ahmed Tinubu ti di Aarẹ Naijria lẹyin iburawọle rẹ to waye ni gbagede Eagles Sqaure niluu Abuja lọjọ Aje.

Amọ iburawọle naa ko waye lai si awọn ti ko fẹ ko ṣeeṣe.

Yatọ si awọn ọmọ ẹgbẹ alatako bii awọn alatilẹyin oludije fun ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour ti wọn ko fẹ ri Tinubu lori oye, oniruru awọn alufaa atawọn wolii lo ti sọ asọtẹlẹ nipa ọjọ naa pe ko ni waye.

Bi awọn wolii kan ṣe sọ pe eto idibo Aarẹ ko ni waye rara, lawọn mii sọ pe Tinubu ko ni wọle, bẹẹ lawọn mii ẹwẹ n sọ pe atimọle ni Tinubu yoo wa lọjọ iburawọle rẹ.

BBC ṣe akojọpọ awọn asọtẹlẹ to jade ṣaaju ọjọ iburawọle Tinubu.

Peter Obi lo maa gbajọba lẹyin Buhari - Odumeje Chukwuemeka (Indaboski)

Wolii Odumeje Chukwuemeka ti ọpọ mọ si Indaboski sọ pe Peter ni yoo ṣe ijọba lẹyin Aarẹ ana, Muhammadu Buhari, ati pe yoo nu omije awọn ọmọ Naijiria nu.

Indaboski lo sọ ọrọ naa lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin isin kan to waye ninu ijọ Mountain of Holy Ghost Intervention and Deliverance Ministry, niluu Onitsha, ni Anambra, ninu oṣu Kẹta ọdun yii.

Iburawọle Tinubu ko ni waye, koda wọn yoo fi si atimọle ni May 29 – Feyi Daniels

Oludasilẹ ijọ ‘I Reign Christian Ministry’, Feyi Daniels, ti sọ asọtẹlẹ pe Tinubu ni yoo bori ibo Aarẹ, amọ kaka ki wọn burawọle fun, ṣe ni yoo dero atimọle lọjọ inurawọle naa.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji, ọdun 2023 yii ni Feyi Daniels sọ asọtẹlẹ naa ninu fidio kan loju opo YouTube rẹ, amọ aṣọtẹle ọhun ko wa si imuṣẹ.

Ko si ohun ti yoo yẹ iburawọle Tinubu – Wolii Joshua Iginla

Alufaa agba ijọ Champions Royal Assembly, Joshua Iginla, lo sọ ọrọ yii lọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun un ti a wa yii ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin PM News.

O ni bo tilẹ jẹ pe Peter Obi loun ṣatilẹyin fun, Ọlọrun ti sọ fun oun lọdun 2020 pe Tinubu ni yoo di Aarẹ Naijiria lẹyin Buhari.

Ijọba fidihẹ ni yoo tukọ Naijiria lati May 29 - Godfrey Chidi

Alakoso ẹgbẹ Holy National Covenant of Divine Intervention in Nigeria’s Affairs, Wolii Godfrey Chidi sọ ninu oṣu Keje, ọdun 2022 pe ohun ri iran ti ko dara nipa eto oṣelu Naijiria lọdun 2023.

O ni Tinubu ko ni dori oye Aarẹ amọ ijọba fidihẹ ni yoo di ipo naa mu.

Wọn ko ni ṣe iburawọle fun Tinubu - Kingsley Okwuwe

Pasitọ ọhun ti nnkan bii 850,000 eeyan tẹle lori YouTube lo sọ asọtẹlẹ naa, ti ọpọ awọn ololufẹ si gbagbọ pe bẹẹ ni yoo ri.

Amọ lẹyinorẹyin, Tinubu ti di Aarẹ Naijiria.