Ẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn tó ń dúnkokò ikú mọ́ mi o! Yinka Alaseyori ké gbàjarè pẹ̀lú omijé lójú

Oríṣun àwòrán, Adeyinka Alaseyori/Facebook
Gbajugbaja akọrin ẹmi, Adeyinka Alaṣeyori, ti ke gbajare pẹlu omije loju wi pe awọn eeyan kan n dunkoko iku mọ oun.
Alaseyori sọrọ yii ninu fidio kan to fi lede loju opo ayelujara rẹ lopin ọsẹ to kọja.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọsẹ to lọ ni ilumọọka akọrin ẹmi miran, Aduke Ajayi Morounkola ti ọpọ mọ si Aduke Gold jade laye lẹyin to ṣe aisan fun igba diẹ.
Alaseyori sọ ninu fidio naa pe ‘’o to ki n bẹru eeyan, idi ni pe iku ko ni pa mi laipe ọjọ.
O di eewọ! Ọpọ lo n fi oriṣiiriṣii atẹjiṣẹ buruku ranṣẹ si mi lori itakun ayelujara.
Ọpọ lo n fi ẹnu wọn pe ipekupe si mi, emi naa si n da a pada fun wọn.
Ni ṣe ni mo maa n rẹrin in ti mo ba ti ri irufẹ atẹjiṣẹ bẹẹ, tori ẹnikẹni to ba ro iku ro mi naa n ti fẹẹ ku niyẹn.
Iwọ ti o ba ro iku ro mi, iwọ naa fẹ ku iku gbigbona niyẹn - Alaseyori
Alaseyori ni ẹnikẹni to ba ko awọn eeyan jọ lati maa gbadura odi le oun lori, iku maa le onitọun naa kaakiri ni.
‘’Iku a maa le ẹ kiri ni, ti o ba duro, iku ni, ti o ba jokoo pẹrẹ, ori iku ni wa a jokoo le, ti o ba sọrọ, o maa ṣorọ sori iku ni.
E ye wa si oju opo DM mi lori ayelujara lati wa sọrọ odi si mi mọ, ma sọ ọrọ ibi nipa mi fun ẹnikẹni.
Mi o ni ku lẹnu, ayanmọ mi o ni ku,’’ Alaseyori lo sọ bẹẹ.
Gbajugbaja akọrin ẹmi naa sọ pe ‘’o di eewọ fun ẹnikẹni lati wa si DM mi lati wa ro iku ro mi.
Ẹ le maa ṣe e fawọn ẹlomiran ki ẹ maa mujẹ, amọ, o di eewọ lori emi Adeyinka Alaseyori, ẹ gbọ eyi ki ẹ kọ ọ silẹ.
Angẹli apanirun ni yoo maa le gbogbo eeyan to n pe iku le mi lori kaakiri.
Koda, to ba jẹ wooli lo n ro iku ro mi, angẹli apanirun a gba odo lori wọn, a jẹ ki ọfa ba wọn laya,’’ Alaseyori ṣalaye.
O rọ gbogbo eeyan lati gbadura lori gbogbo nnkan to n fun wọn layọ.
Akọrin ẹmi Alaseyori ni awọn eeyan ni lati gbadura gidi tori aye le ju bi ọpọlọpọ eeyan ti ro lọ.
Alaseyori ni ‘’mi o le sọkun tori ọrọ naa bani ninu jẹ pupọ ju.
Ọpọ eeyan ni ko mọ ohun to n lọ labẹlẹ, oriṣiiriṣii nnkan lo n ṣẹlẹ ti ọpọ eeyan ko mọ.
Ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni tan ọ wi pe o nilo adura, asiko niyi lati gbadura gigi.
Ọpọ nnkan lo ti n ṣẹlẹ lati bi oṣu mẹfa sẹyin bayii, ti mi o tiẹ sọrọ rara.
Ohun ti mo mọ ni pe Ọlọrun lo ni ẹmi onikaluku lọwọ, tori naa, maa fi Ọlọrun silẹ nigba kankan.
Mo fẹ ki ẹ gbadura pẹlu mi ki ẹ si gbadura fun ara yin naa,’’ Alaseyori ṣalaye.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post















