Wo nǹkan tí ìjọba fẹ́ẹ́ máa ṣe fáwọn tó ń ṣè'gbọ̀nsẹ̀ ní gbangba lágbègbè Mowe, Magboro, Warewa, Kara àti Isheri

Aworan ẹnikan to n yagbẹ nita gbangba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun ti sọ pe ẹnikẹni tọwọ ba ti tẹ lori ẹsun wi pe o n ya igbẹ nita gbangba, paapaa lawọn ibi ti ko tọ yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

Oludamọran pataki fun gomina lori idaabobo eto eyika, Oluwadare Kehinde lo sọ eyi di mimọ lọsẹ to kọja nibi ipade oniroyin to waye nibi abẹwo to ṣe pẹlu akẹgbẹ lati ipinlẹ Eko, Ọmọwe Tunde Ajayi lọ si Berger.

Ipinlẹ Ogun ati ipinlẹ Eko ni wọn ti kede sita wi pe awọn ti bẹrẹ ajọṣẹpọ lati bẹrẹ sii fi kele ofin gbe awọn to n yagbẹ nita gbangba, paapaa lawọn agbegbe ẹnubode to so ipinlẹ mejeeji papọ.

Nigba to n sọrọ, Kehinde sọ pe erongba wọn ni lati gbogun ti ajakalẹ arun bii kọlẹra, igbẹ-gbuuru ati oniruuru aisan to le jẹyọ lati ara yiya igbẹ sibi ti ko tọ.

O ni iwa yii wọpọ lawọn agbegbe bii Mowe, Magboro, Warewa, Kara ati Isheri, to si ni ko bojumu to.

Kehinde ni igbimọ ti wọn gbe dide lati bojuto iwa yii yoo bẹrẹ iṣẹ lẹyin ipolongo lati fi to gbogbo araalu leti lati dẹkun iwa ibajẹ naa ba pari.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Eyi yoo jẹ ikilọ fun gbogbo awọn tọwọ ba tẹ, nitori pe ẹni ti ọwọ palaba rẹ ba segi yoo foju winna ofin, ti yoo si fẹnu fẹra bi abẹbẹ.

“Iwa ki awọn eeyan maa yagbẹ nita gbangba, paapaa lawọn aarin opopona to so ipinlẹ mejeeji yii papọ ko le jẹ itẹwọgba mọ nipinlẹ Ogun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Fun idi eyi, ọna abayọ lati dẹkun iwa ibajẹ bayii ni lati bẹrẹ sii fi idi ofin mulẹ lati bẹrẹ sii mu gbogbo awọn to n huwa ibajẹ naa, leyi to pọnpọn dandan lati kọkọ ṣe ilanilọyẹ.

“Igbesẹ yii ṣe koko nitori pe ijọba ipinlẹ Ogun ti ṣagbekalẹ awọn ṣalanga igbalode tuntun fun lilo araalu, paapaa lawọn agbegbe ẹnubode ilu, fun idi eyi, a ko nii foju aanu wo ẹni tọwọ ba tẹ.

“Ohun to n jẹ wa logun ni awọn atubọtan ohun ti yiyagbẹ nita gbangba maa n da silẹ lara araalu, ati pe ko tun bu iyi to tọ fun ipinlẹ naa, a ko si ni faaye gba iwa buruku yii mọ.”

Bakan naa ni Kehinde wa ṣe ikilọ fun gbogbo awọn to lọwọ ninu iwa ibajẹ naa lati jawọ, ki wọn si bẹrẹ sii lo awọn ṣalanga tijọba ti gbe kalẹ, nitori pe ika abamọ ni wọn yoo ti bọ ẹnu bi ọwọ ba tẹ wọn.

Nigba toun naa n sọrọ, alakoso ileeṣẹ to n ṣabojuto eto ayika nipinlẹ Eko, Ọmọwe Tunde Ajayi sọ pe o ṣe pataki lati kọkọ ṣe ipolongo ikilọ ko to di pe wọn bẹrẹ igbesẹ ọhun.

Ajayi jẹ ko di mimọ pe ‘awifunni ko too da ni, agba ijakadi ni’, lawọn ṣe gbe ipolongo naa wa sita gbangba fun awọn to lọwọ ninu yiya igbẹ nita gbangba lati jawọ.

O ni lati agbegbe bii OPIC Plaza, Kara, Berger ati afara Ọtẹdọla titi de opin opopona Eko si Ibadan lawọn yoo bojuto daadaa, nitori pe ibẹ ni awọn oṣiṣẹ igbimọ ti wọn gbe kalẹ yoo ti maa ṣiṣẹ.

Bẹẹ lo kadi ọrọ rẹ nilẹ pe awọn ti bẹrẹ imọtoto gbogbo ibi ti awọn eeyan ti fi igbẹ bajẹ lopopona marosẹ Eko si Ibadan.