Ìlú kan nìyí tó ní orúkọ mẹ́ta àti ọba mẹ́ta

Àkọlé fídíò, Ìlú kan ní ilẹ̀ Yorùbá tó ní orúkọ mẹ́ta àti ọba mẹ́ta
Ìlú kan nìyí tó ní orúkọ mẹ́ta àti ọba mẹ́ta

Ni ile Yoruba, ohun ti awọn agba maa n sọ ni pe ijoye le pe meji laafin ṣugbọn ọba kii ju ọkan ṣoṣo lọ ni ilu.

Bẹẹkọ lọrọ ṣe ri pẹlu ilu Ajaṣẹ, ọkan lara awọn eekan ilu ni ilẹ Yoruba.

Ko si si bi wọn ṣe n sọ itan itankalẹ ilẹ Yoruba lai ni darukọ ilu Ajaṣẹ.

Lootọ orilẹede Benni Republic ni ilu Ajaṣẹ bọ si lẹyin pinpin aala ilẹ awọn orilẹede ni Afrika eyi ti awọn oyinbo amunisin ṣe lọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Titi di oni ohun kan to ṣi n kọ ọpọ ni kayeefi ni bi ilu naa ṣe di eyi to n ni orukọ mẹta ati ọba mẹta.

Nigba ti BBC ṣe abẹwo si ilu Ajaṣẹ alaye to ba bọ ni wi pe, awọn iṣẹlẹ kan lo ti waye sẹyin to sọ ilu naa di Ọba mẹta, orukọ mẹta.

Orukọ mẹta ti ilu naa n jẹ bayii ni Ajaṣẹ, Porto Novo ati Hogbonu.

Ọba Abdulrahaman Sanni, Alajaṣẹ tni ọba ilu Ajaṣẹ ile.

Roi TOFA Ayontinmin IX ni ọba ilu Porto Novo

Roi KPODAGBA HAKPON IX lo jẹ Ọba ni ilu Hogbonu.

Bawo ni Ajaṣẹ ṣe di olorukọ mẹta ati ọlọba mẹta?

Abawọle aafin Ajaṣẹ

Ninu alalye ti Ọba Abdulrahaman Sanni, Alajaṣẹ ti ilu Ajaṣẹ ile ṣe, ‘awọn abonilẹdulẹ’ ni wọn pin ilu naa yẹlẹyẹlẹ. Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ilu Ajaṣẹ ti bẹrẹ itẹdo ki o to di pe awọn to n jẹ ọba yoku wa. O ni gẹgẹ bi odu ifa to tẹ ilu ọhun do, ilu abiyamọ ni ilu naa to si gba ọpọlọpọ ajeji mọra.

Ọba Sanni ni ọrọ iṣakọlẹ sisan lo fa wahala nigba ti alejo ti wọn gba mọra faake kọri nigba kan pe oun ko san iṣakọlẹ kankan mọ.

Ọba Sanni ni Hogbonu ki i ṣe ilu to da duro, ilẹ ti awọn babanla oun fun awọn alejo tẹlẹri ni

Amọṣa Ni tirẹ, Ọba ni Porto-Novo, Roi TOFA Ayontinmin IX ni “awọn iṣẹlẹ kan gboogi lo waye nigba aye awọn babanla wa.” O ni ogun nla kan lo ṣẹlẹ ti o fa ayipa orukọ rẹ si ‘Hogbonu’ eyi ti wọn n pe e ni isisinyi.

Aworan manigbagbe kan lati ilu Ajaṣẹ.

O ni igba ti awọn babanla oun kọ ahere akọkọ ni wọn pe ibẹ ni Hogbonu. Agbekalẹ rẹ jẹ Họ tumọ si Ahere nigbati ‘gbo’tumọ si nla ninu ede wọn.

O ni nigba ti wọn bori ogun to waye laarin Nango ati awọn Eegun nigba naa ni wọn sọ orukọ rẹ ni ‘Aja temi’ ti o wa pada di ‘Ajaṣẹ’ loni yii.

Ninu ọrọ tirẹ, Ọba Roi KPODAGBA HAKPON IX sọ pe Ọba kan lo wa, ọrọ ọba jijẹ lo si fa edeaiyede. O fi kun un pe Te-Agbani lo yi orukọ ilu naa pada si ‘Hogbonu’nigba to jẹ ọba. O ni aṣẹ wa lati ilu Ajatado ti wọn n pe ni Ajaṣẹ -Diye bayii eyi to tumọ si, ‘Ajaṣẹ temi leleyi lede Yoruba’.

Ẹkunrẹrẹ alaye pọ ninu fidio yii.