Pàtàkì ilé Abẹ́sàn-án, tí aya Onikoyi ti bí ọmọ mẹ́sàn-án tó wà ní Porto-Novo
Ọpọ itan agbayanu lo wa nilẹ Yoruba eyi to n fi ye wa pe ilẹ Yoruba fẹ titi to fi de ilẹ Dahomey ni.
Ni ilu Porto Novo to wa ni orilẹede Benin, ilu Yoruba pọnbele lo jẹ, asọ, ede, iwa ati ounjẹ ilẹ Yoruba si ni wọn n jẹ.
Orukọ ilu naa ni ilu Ajasẹ ile to wa ni orilẹede olominira Benin.
Ilu Ajasẹ yii si ni ibudo kan to gbajugbaja wa, ti wọn n pe ni ibudo Abẹsan.
Ki lo de ti wọn n pe orukọ ibudo naa ni ilu Abẹ́sàn-án, bawo si ni Ajasẹ ti ibudo naa wa, se tan mọ ilẹ Yoruba eyi to mu ki ede, asa ati ise wọn jẹ ti Yoruba pọnbele.
BBC Yoruba de ilu naa lati wa idahun sawọn ibeere yii. Abọ wa ree.

Alajasẹ tilu Ajasẹ ile, Ọba Abdulrahman Sanni, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori pataki ibudo Abẹsan, sọ ẹkunrẹrẹ itan to rọ mọ idasilẹ ibudo naa.
Gẹgẹ bi Kabiyesi ti wi, ibudo naa ni aya ọmọ Onikoyi, to jẹ jagunjagun nla nilẹ Yoruba ti bi ọmọ mẹsan.
Nigba to n salaye ohun to gbe aya ọmọ Onikoyi de ilu Ajasẹ naa to wa ni orilẹede olominira Benin, to fi bimọ mẹsan.
Alajasẹ ni " Ọmọ mẹta ni Onikoyi bi, orukọ wọn ni Anata ọmọ Olukoyi Obaganju
Ẹnikeji ni Akapo nigba ti ẹnikẹta jẹ Ọgbọn.
Jagunjagun ni awọn mẹtẹẹta lati ilẹ Awori, ti wọn si jẹ ọmọ Onikoyi, wọn se ọdẹ lọ si Ajasẹ ni.
Ọdun 1485 si ni wọn ko awọn ẹbi ati aya wọn wa silu naa lati tẹdo si."
Bawo wa ni aya ọmọ Onikoyi yii se de ilu Ajasẹ lati bimọ?

"Bi aya ọmọ Onikoyi se bi ibẹsan ree..."
Nigba to n salaye bi aya ọmọ Onikoyi se bi ibẹsan nilu Ajasẹ, Alajasẹ tilu Ajasẹ ni aya Anata tii se ọmọ Onikoyi lo bi ibẹsan naa.
"Iyawo Anata, aya ọmọ Onikoyi wa ninu oyun, ti ko si le e fi silẹ sinu ile pẹlu oyun nitori ko si ẹnikan nile.
Nigba to n lọ se ọdẹ nilu Ajasẹ, lo ba mu alaboyun naa lọwọ lọ se ọdẹ ko maa baa bimọ sile lai si ẹni ti yoo sugba rẹ.
Bi wọn se de ibudo ti ile abẹsan naa wa, ni ọmọ mu oloyun naa, to si bi ọmọ mẹsan.
Awọn ọmọ mẹsẹẹsan naa si jẹ obinrin marun ati ọkunrin mẹta.
Ara meeriri gbaa ni isẹlẹ yii, isẹ Oluwa si ni."
Alajasẹ ni ibi ti ọmọ ọba Onikoyi ti mu iyawo rẹ b si kọrọ lati bimọ, obinrin naa bi ọmọ si ni wọn sọ di ojubọ eyi ti wọn n pe ni ile Abẹsan.

"Aya ọmọ Onikoyi to bi mẹsan ko kuro nibi mọ, o di irunmọlẹ ti a n bọ ni"
Nigba toun naa n salaye bi ile Abẹsan ti se pataki to, onitan to mọ nipa ibudo abẹsan naa, salaye idi ti wọn se sọ ibudo naa di ojubọ.
"Wọn se ile yii ni ile iki, ibẹ si ni iya wa wa lẹyin to bi ibẹsan, ti ko si kuro nibẹ.
O di irunmọlẹ sibẹ ni lẹyin ọpọ ọdun eyi to mu ki awọn eeyan maa bọ ọ.
Idi si ree ti wọn se n pe ile naa ni ile Abẹsan, awọn ọmọ Onikoyi ti wọn ba bi lo si maa n jẹ oye Arole.
Ọmọ kunrin ti obinrin to jẹ ọmọ Onikoyi ba bi si lo maa n jẹ oye Arole ile Abẹsan naa"







