Kí ló fa ariwo, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì faraya torí Orò tí yóò jáde lásìkò ìwọ́de ebi ń pa wá?

Aworan awon Oniṣẹṣe

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ariwo ti gba ori ayelujara kan, ti ọpọ eeyan si n fapa janu bi iroyin kan se jade sori ayelujara pe ọdun Oro ti ọdun yii yoo bẹrẹ nilu Eko.

Atẹjade kan to bọ sori ayelujara X lo fidi igbesẹ naa mulẹ ọdun Oro tọdun yii yoo waye, bẹrẹ lati ọjọ akọkọ si ọjọ kẹẹẹdogun oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii.

Akoko ti wọn fẹ se ọdun Oro yika ipinlẹ Eko naa si lo se pẹki n pẹki pẹlu akoko ti awọn ọdọ lorilẹede Naijiria n gbero lati se iwọde fi fopin si isejọba buruku

Idi si ree ti awọn alakoso iwọde naa se n fapa janu lori ayelujara pe awọn Oloro mọọmọ fi ọdun Oro si akoko ti iwọde naa yoo maa waye ni lati da awọn lẹkun.

Wọn fi kun un pe bo ṣe jẹ ẹtọ fawọn to faramọ iwọde tako ijọba buburu, bẹẹ naa ni ofin ṣe faaye gba awọn oloro pẹlu lati gbe Oro jade lasiko kan naa.

Amọ ọpọ eeyan lo n fi ibẹru han pe rogbodiyan le waye ti Oro ba jade lasiko ti iwọde n waye.

BBC Yoruba si kan si agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko lati mọ nipa igbaradi rẹ lori rogbodiyan to le su yọ naa.

Amọ Benjamin Hundeyin, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, ko tii fesi pada si ibeere lori ọdun Oro yii titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

Èrò àwọn aráàlú ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àríyànjiyàn bẹ̀ sílẹ̀

Gẹgẹ bo ṣe wa loju opo X ẹnikan to pe ara rẹ ni Nononsense, ni ẹtọ ọmọniyan ni iwọde ati Oro sise jẹ.

O kọ ọ sibẹ pe lati ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹjọ, ọdun 2024, Oro yoo waye kaakiri ilẹ Yoruba.

Ati pe eni to ba wo o firi yoo ku pii ni.

Bakan naa, Lagospedia, loju opo X kan naa, sọ ni tiẹ pe kawọn olugbe Eko lọọ mọ pe Oro yoo jade lọjọ kin-in-ni si ikẹẹẹdogun , oṣu kẹjọ ọdun 2024.

O ni oriṣiiriṣii eto ni Oro ko sinu, kawọn eeyan to gbọ sọ fẹni ti ko gbọ, ki kaluku si fi ti Oro fun Oro.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Lasiko ti ọpọ eeyan n sọ ero ọkan wọn si ikede ọdun Oro naa to n waye lasiko ti iwọde Ebi n pa wa n waye, se ni ero wọn se ọtọọtọ.

Bi awọn kan se fara mọ pe awọn le se iwọde ni ojumọ mọmọ, ki awọn oloro si se oro wọn ni oru dudu, ni awọn kan ni ko ri bẹẹ.

Wọn ni ilu lee maa fara rọ ti iwọde ba n waye lasiko ti ọdun oro n lọ lọwọ.

Bakan naa ni wọn fikun pe bi wọn se gbe Oro jade naa ree lasiko idibo to kọja lati se idiwọ fun awọn lati dibo fun oludije to wu awọn.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3

Ẹnikẹni ko wa ba ijọba Eko lati gbe Oro jade, ko sohun to kan ijọba pẹlu Oro - Kọmisana feto iroyin

Lati tan imọlẹ si ọrọ ti wọn n gba bii ẹni gba igba ọti lori ayelujara yii, BBC Yoruba kan si kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbenga Omotoso.

Nigba to n dahun si ibeere pe ṣe ijọba mọ nipa Oro ti wọn lo fẹ jade naa, Omotoso sọ pe, ‘’ẹnikẹni ko wa ba ijọba Eko lati gbe Oro jade’’

Kọmiṣanna eto iroyin Eko naa sọ pe ko sohun to kan ijọba pẹlu Oro.

O ni ijọba kọ lo n ṣe Oro, awọn oloro lo mọ nipa Oro, ko kan ijọba rara.

Fun idi eyi, akọsilẹ Oro ko si ninu ohun tijọba Eko n ro lasiko yii bo ṣe sọ.

Se lootọ ni Ọdun Oro yoo waye yika ilẹ Yoruba?

Bakan naa, awọn eeyan kan ti n gbe iroyin kaakiri pe kii se ipinlẹ Eko nikan ni Ọdun Oro yii yoo ti waye, yika ilẹ Yoruba ni.

Ọna lati fidi otitọ ọrọ mulẹ nipa ikede yii lo mu ki BBC Yoruba tun kan si awọn onisẹse lawọn ipinlẹ miran nilẹ Yoruba.

Nigba to n dahun ibeere lori boya ọdun Oro yoo waye yika ilẹ Yoruba, Aarẹ ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Iṣẹṣe nipinlẹ Ọṣun, ọmọwe Oluṣeyi Atanda, sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ nipinlẹ naa.

Dokita Atanda sọ pe awọn agbesunmọmi ni wọn wa nidii iroyin ọhun.

‘’Awọn agbesunmọmi ni wọn n sọ iyẹn, ko sibi ti wọn ti ṣepade rẹ.

Nipinlẹ Ọṣun o, ko sohun to jọ ọ. Mi o dẹ ri ẹlomi-in to pe mi lati ipinlẹ mi-in.

‘’Boya awọn asorun-iwaju-pọ-mọ-tipakọ ti wọn kan fẹẹ da ilu ru, tabi ti wọn kan tun fẹẹ kawọn eeyan tun ri nnkan maa sọrọ le lori pe wọn gbe Oro jade ni wọn n sọ ọ.’’

Ni bayii ṣaa, ọrọ Oro naa ṣi n ja ran-in lori ayelujara, bẹẹ ni ọpọ eeyan lo n royin iwọde agbayanu ti wọn lo tun fẹẹ waye loṣu kẹjọ kan naa.