Wo abúlé kan ní India, tó ní ọmọ òun ni Kamala Harris, tó sì ń bẹ̀bẹ̀ àdúrà fún láti di ààrẹ Amẹ́ríkà

Oríṣun àwòrán, Janarthannan/BBC
Lati igba ti Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden, ti fa Kamala Harris, igbakeji rẹ kalẹ lati du ipo aarẹ orilẹede naa ni iroyin oriṣiiriṣii ti n jade lati ṣalaye ẹni ti Kamala jẹ.
Awọn ara abule kekere kan Thulasendrapuram, to wa ni orilẹede India, ti ṣafihan Kamala Harris bayii bii ọmọ wọn.,
Wọn ṣe etutu nitori rẹ ko le baa de ipo aarẹ ilẹ America.
Thulasendrapuram jẹ abule kekere kan to to kilomita ẹgbẹrun mẹrinla keeyan too de Washiton DC.
Abule yii ni awọn obi to bi Iya Kamala Harris ti wa.
Bi eeyan ba de aarin gbungbun abule Thulasendrapuram bayii, niṣe ni wọn gbe aworan to n kede Kamala Harris, ẹni ọdun mọkandinlọgọta (59) si gbagede abawọle ibẹ.
Yatọ si eyi, awọn ara abule tun ṣeto adura ati ipese fun ooṣa ibilẹ wọn nitori Kamala.
Wọn darukọ Kamala Harris bii ẹni tawọn tori rẹ se ipese naa.
Wọn tọrọ fun pe ko jawe olubori lati di aarẹ America, wọn si pin suuti (sweet) fawọn eeyan lati bawọn ṣajọyọ oriire ọmọ wọn to fẹ ẹ di aarẹ.
Bakan naa ni wọn ni Baba Iya Kamala wa lara awọn eeyan to maa n ṣe ipese fun ojubọ abule .
‘Ọmọ tá a fi ń yangàn ni, àwa ló kàn báyìì tí à ń darí àwọn ìlú alágbára’

Oríṣun àwòrán, Janarthannan/BBC
Gẹgẹ bi awọn ara abule ṣe wi, wọn ni ọmọ awọn ni Kamala Harris, ko si dẹrun lati de ipo nla to wa bayii l’America.
‘’Ki i ṣe ohun to dẹrun lati de ipo to wa bayii lorilẹde to lagbara julọ lagbaaye.
‘’Ọmọ ta a fi n yangan gidi ni, igba kan ni awọn ajoji n darii India, asiko tiwa naa lo de bayii. India naa ti n dari awọn ilu nla lagbaaye’’
Oṣiṣẹfẹyinti kan ni banki, Krishnamurthi, lo sọ bẹẹ.
Latigba ti Joe Biden ti fa Kamila Harris kalẹ ni awọn ara abule yii ti n ṣe atilẹyin fun obinrin naa, wọn si n fi gbogbo ara da si i.
‘Àwa obìnrin faramọ́ Kamila Harris, a mọ̀ ọ́ dáadáa’
Lawujọ awọn obinrin agbegbe naa bayii, wọn n ri Kamila Harris bii ọkan lara wọn.
“Gbogbo wa la mọ ọ daadaa, titi kan awọn ọmọde. ‘Anti mi, maami’, bi gbogbo wọn ṣe maa n pe e niyẹn.
‘’Inu wa dun pe ko gbagbe orirun rẹ, a si n fi idunnu wa han si eyi’’
bẹẹ ni obinrin kan, Arulmozhi Sudhakar, aṣoju abule naa sọ.
Tẹ ẹ o ba gbagbe, iru ayọ bayii ni awọn ara abule ọhun fi han nigba ti Kamila di Igbaleji aarẹ Amerika.
Niṣe ni wọn se àsè nla ti gbogbo araalu jẹ awọn ounjẹ pataki to jẹ ti ibilẹ, awọn ounjẹ bii Sambar ati eyi ti wọn n pe ni Idli.
Orírun Kamila Harris ní India

Oríṣun àwòrán, Janarthannan/BBC
Shyamala Gopalana ni iya to bi Kamila Harris.
Oluwadii nipa jẹjẹrẹ ọyan ni iya naa to wa lati Guusu Tamil Nadu, ko too lọ si orilẹede Amerka lọdun 1958.
Awọn obi to bi Gopalan yii ni wọn wa lati abule Thulasendrapuram.
Gẹgẹ bi Kamala funra rẹ ṣe kọ ọ si ori ayelujara lọdun to kọja, o ni,
“iya mi, Shyamala, da wa si U.S funra rẹ nigba to wa lọmọ ọdun 19. ‘’Ajafẹtọọ ọmọniyan ni, onimọ ijinlẹ ni pẹlu, o si kọ awa ọmọbinrin rẹ mejeeji ni ẹkọ idaraẹniloju.”
Lẹyin iku iya rẹ, Kamala ati ikeji rẹ, Maya, ṣabẹwo si ilu Chennai, wọn si ki eeru oku iya wọn bọ omi gẹgẹ bi ilana isinku awọn Hindu.
Gẹgẹ bi ẹka iroyin Hindu kan ṣe ro o.
Ẹgbọn iya Kamala, Gopalan Balachandran, jẹ olukọ.
PV Gopalan, ni Baba iya Kamala Harris.
O di ọkan ninu awọn alẹnulọrọ ninu ijọba, o si figba kan jẹ oludamọran fun aarẹ orilẹede Zambia ni nnkan bii ọdun 1960.















