Kí ló ṣẹlẹ̀ láàrín Peter Obi àti agbẹnusọ Ààrẹ Tinubu, tí Obi ṣe ń bèèrè N5bn owó ‘gbà má bínú’?

Obi/Tinubu

Oríṣun àwòrán, Obi/Tinubu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹnu ọjọ mẹta yii ni ẹnu bẹrẹ si n kun Bayo Onanuga to jẹ agbẹnusọ Aarẹ Bola Tinubu ati Peter Obi to jẹ oludije fun ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Labour lọdun 2023 ori ayejura.

Eredi isẹlẹ naa ko ṣẹyin oko ọrọ tawọn mejeeji n sọ si ara wọn, koda, o ṣeeṣe ki ọrọ naa dele ẹjọ laipẹ yii.

Iroyin ni họwuhọwu naa bẹrẹ latari bi eto ọrọ aje Naijiria ṣe dẹnukọlẹ ati bi awọn kan ṣe n pe fun ifẹhonunhan kaakiri Naijiria.

Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ ree...

Lati igba ti wọn ti burawọle fun Bola Tinubu ni Obi ti maa n sọko ọrọ si ijọba Naijiria gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ alatako.

Awọn ọrọ ti Obi maa n sọ lọpọ igba lo da lori ibi ti nnkan de duro ni Naijiria ati eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ.

Pupọ ninu ọrọ Peter Obi ọhun lo tako ijọba ti kii tẹ awọn alatilẹyin ijọba to wa lode atawọn ololufẹ Aarẹ Bola Tinubu lọrun.

Ifehonuhan to n rugbo bọ

Latari bi nnkan ṣe wọngogo ati inira ti araalu n dojukọ, awọn ọmọ Naijiria kan ti n pe fun ifẹhonuhan.

Ninu atẹjade ti awọn to n ṣagbatẹru iwọde naa fi lede, wọn ni yoo bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii, lati aago mẹfa aarọ si aago mẹfa irọlẹ.

Lara awọn nnkan ti awọn oluwọde naa n bere fun ni pe ki ijọba apapọ da owo epo bẹntiro pada si N100/lita, ki ijọba wa ojutu si eto abo to mẹhẹ, ko bẹrẹ si n san N300,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ni Naijiria, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Amọ awọn kan ti n tako ifẹhonuhan naa latari igbagbọ pe yoo da omi alafia Naijiria ru.

Onanuga

Oríṣun àwòrán, Onanuga

Ohun to fa wahala ree laarin Peter Obi ati Bayo Onanuga

Lọjọ kejilelogun, oṣu ti a wa yi ni Peter Obi sọrọ nipa idagbasoke ọrọ aje Naijiria pẹlu ẹri, to si ṣalaye pe gbogbo nnkan lo ti dojuru labẹ Aarẹ Bola Tinubu.

Lẹyin ọrọ naa to fi lede loju opo X rẹ ni agbẹnusọ Tinubu, Bayo Onanuga fun lesi pada.

Onanuga sọ oko ọrọ si Obi pe ara lo n ta lẹyin to lulẹ ninu idibo ọdun 2023.

O sọ siwaju si pe Obi atawọn ‘Obidient’ rẹ fẹ mọọmọ da Naijiria ru mọ ijọba to wa lode lori nipa iwọde naa ni.

Agbẹnusọ Aarẹ naa ṣalaye siwaju si pe ki awọn agbofinro fi ofin mu Obi ti wahala kankan ba bẹ silẹ latari iwọde naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn to n mura silẹ fun iwọde ọhun lawọn eeyan to dana sun ilu lasiko iwọde EndSARS to waye lọdun 2020, eyii ti Nnamdi Kanu ṣe onigbọwọ fun.

Peter Obi

Oríṣun àwòrán, Alex Ejemsieme & Co

Obi n beere biliọnu marun naira, Onanuga yari pe oun setan lati lọ sile ẹjọ

Wayi o, Peter Obi ti fun Onanuga ni ọjọ mẹta pere lati tọrọ aforijin lọwọ oun lori ẹsun pe oun loun wa lẹyin ifọhonunan n to n bọ laipẹ.

Obi ṣeleri pe oun yoo gba ile ẹjọ lọ ti Onanuga ba kọ lati tọrọ aforijin naa.

Gomina ipinlẹ Anmabra nigba kan ri naa tun beere owo ti iye rẹ jẹ biliọnu marun un naira gẹgẹ bii owo gba ma binu fun bi Onanuga ṣe ba oun lorukọ jẹ.

Amọ ṣa, Onanuga ti sọ pe oun ko tii gba lẹta kankan lati ọwọ awọn agbẹjọro Obi nipa ẹjọ naa ati N5b to ni ki oun san.

Onanuga sọ pe “ki n kuku sọ fun Obi ati agbẹjọro rẹ: mi o bẹru lati ṣe ẹjọ. A o pade nile ẹjọ.