"Jẹjẹrẹ ọyàn mú mi nígbà méjì lẹ́ni ọdún 23, wọ́n fi iṣẹ́ abẹ fá ọmú mi méjèèjì, ọkọ àfẹ́sọ́nà kọ̀ mí sílẹ̀"
Aisan jẹjẹrẹ jẹ aisan to maa n mu ẹmi ọpọ eeyan lọ, paapaa nilẹ adulawọ nitori eeyan perete lo maa n ye aisan naa.
Lara aisan jẹjẹrẹ to si wọpọ ni aisan jẹjẹrẹ ọyan ( Breast Cancer), jẹjẹrẹ ile ọmọ (Cervical Cancer) jẹjẹrẹ ti inu ẹjẹ (Leukemia) ati aisan asetọ (Prostate Cancer).
Owo nla si ni itọju aisan jẹjẹrẹ maa n ba lọ, ti awọn eeyan to ba lugbadi aisan naa yoo si maa n ta ọpọ dukia nigba mii, jẹ gbese tabi maa beere fun iranwọ owo kaakiri.
Bi o tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan ti ba aisan yii lọ, ti owo si tan ni kẹlẹ, ki wọn to dagbere faye amọ obinrin kan ree, Abisayo Fagbohunlu, ti ori ko yọ lọwọ aisan aisan jẹjẹrẹ ọyan ni igba meji.
Yoruba ni iku ti yoo ba pa ni, to ba si ni ni fila, se lo yẹ ka maa dupẹ, bẹẹ ni ọrọ arabinrin naa ri tori o ti bọ lọwọ aisan asekupani naa.
N jẹ bawo ni aisan naa se bẹrẹ, awọn isoro wo lo la kọja lasiko yii ati pe ki ni awọn ọna to gba to fi ri iwosan lọwọ aisan yii, bawo si ni adun se gbẹyin ewuro fun.
Abisayo Fagbohunlu ba BBC sọrọ lati pese idahun si awọn ibeere yii.

“Koko marun tun sọ lori ọyan ti wọn ti fa tẹlẹ, aisan aisan jẹjẹrẹ ọyan tun suyọ fun iga keji”
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori bi aisan jẹjẹrẹ ọyan naa se bẹrẹ, Abisayọ Fagbohunlu ni ẹni ọdun mẹtalelogun ni oun wa, ọmọge ni oun nigba ti koko s lori yan oun.
“Wọn fa ọyan mi naa lati dena aisan jẹjẹrẹ ọyan ọhun.
Amọ lẹyin ọdun marun ti isẹlẹ naa waye, ti mo gbe ẹni ọdun mejidinlọgbọn, aisan jẹjẹrẹ ọyan naa tun suyọ.
Ọkọ afẹsna mi n mura lati yọju sile wa fun Mọ mi, n mọ ọ ni koko marun tun sọ pada lori ọyan ti wọn ti fa tẹlẹ.
Mo sọ ohun to n sẹlẹ fun ọkọ afẹsọna mi naa amọ ori opopona marosẹ Eko si Ibadan ti a wa, lo fi mi si, o si lọ.
Titi di oni olonii, n ko fi oju mi kan ọkunrin naa mọ.”
Abisayo wa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe lẹyin ti oun bori isoro naa, Ọba oke fun oun ni ọkọ ti oun.

Mo gbọ ohun kan to ni ki n lọ wo oju foonu mi, mo se bẹẹ, orukọ ati aworan Abisayo ni mo kọkọ ri lori Whatsapp sọọsi ti a n lọ nigba ti a wa ni fasiti – kọ Abisayo
Nigba toun naa n ba BBC Yoruba sọ̀rọ, Olusọaguntan Gbemileke Fagbohunlu, to gbe Abisayo niyawo ni ẹnikeji oun ni obinrin naa.
Oju opo ikanni sọọsi ti awọn mejeeji dijọ lọ lasiko ti wọn wa nile ile ẹkọ fasiti si ni wọn ti pade ara wọn.
“Ẹnikeji mi ni Abisayo, iyawo mi, ọrẹ mi timọtimọ ati ẹbun pataki ti o ga julọ ti Ọlọrun fun mi.
Mo kan gbọ ohun yẹn lọjọ naa ni, nigba ti mo de lati sọọsi, to si sọ fun mi pe ki n lọ mu ẹrọ ibaraẹnisọrọ mi.
Mo se bẹẹ amọ ohun akọkọ ti maa ri ni whatsapp ẹgbẹ sọọsi wa ti awa mejeeji wa nile ẹkọ fasiti nigba naa.
Orukọ ati ati aworan rẹ ni maa kọkọ ri, mo si fi ọrọ ransẹ si.”
Gbemileke ni o kọkọ le fun awọn tẹlẹ ri, amọ ki n to ba sọrọ rara, Ọlrun sọ fun mi pe isẹ iriju mi ni.
“Lẹyin naa lo sọ awọn ohun to ti la kọja nipa aisan jẹjẹrẹ fun mi, fun ọsẹ meji, n ko pe lori aago amọ lo lọ ba awọn ojisẹ Ọlọrun la ti la mi lọyẹ ni.”

“Mo ti ni iporuru ọkan amọ mo dupẹ pe n ko pa ara mi”
Nigba to n fi ayọ rẹ han lori bi adun se gẹyin ewuro rẹ, Abisayọ ni oun ti ni iporuru ọkan lasiko ti aisan jẹjẹrẹ yan mu oun.
Amọ o ni oun dupẹ pe oun ko pa ara oun lasiko naa.
“Awọn eeyan ko fi mi silẹ, titi kan awọn ẹbi mi, n ko fi ara mi silẹ, awọn eeyan ko dẹ fi mi silẹ
Mo maa gba awọn eeyan to n la nnkan ti mo la kọja pe ki wọn ma fi Ọlọrun wọn silẹ.
“Pe Ọlrun rẹ, gba ile iwosan lọ, ki o si sọ fun asaaju ẹsin rẹ nipa ohun to n sẹlẹ.”
Abisayo wa n sọ bi inu rẹ se dun to lasiko to ni oyun, eyi to fi bi ọmọbinrin jojolo kan.




