Báyìí ni mo ṣe ye jẹjẹrẹ inú kórópọ̀n tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi-Ebenezer Obey

Aworan Ebenezer Obey

Oríṣun àwòrán, Instagram/ebenezerobeymfr

Gbajugbaja agba ninu orin kikọ lorilẹede Naijiria, Ebenezer Obey ti sọrọ lori bi o ṣe moribọ ninu aarun jẹjẹrẹ inu koropọn to fẹ gba ẹmi rẹ.

Obey salaye iriri rẹ fun Ileeṣẹ iroyin abẹle, The Punch Saturday Beats pe oore-ọfẹ Ọlọrun lo jẹ ki oun moribọ ninu aarun jẹjẹrẹ naa ni ẹni ọdun mejilelọgọrin.

“Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun to yọ mi kuro ninu aarun jẹjẹrẹ inu koropọn yii lẹyin ti mo ṣe iṣẹ abẹ ni ile iwosan kan niluu Eko.

O ni oun dupẹ lọwọ awọn ọrẹ, mọlẹbi, awọn ololufẹ mi ati awọn eeyan Ọlọrun fun adura wọn. Awọn eeyan wa ki mi nigba ti mo wa ni ile iwosan. Mo dupẹ lọwọ gbogbo wọn.

Oloye Ebenezer Obey sọ pe Ọlọrun sọ fun oun pe, oun ko ti i pari nnkan to ni ki oun wa ṣe lori ilẹ aye. "O ni oun si ni iṣẹ fun mi lati ṣe. Mo ti pinnu lati ṣe ọpọlọpọ fun Ọlọrun. Ma a jẹri iṣẹ Ọlọrun lasiko ọjọbi bi ni ọjọ kẹta ninu oṣu kẹrin."

O fikun pe pẹlu bi ẹru ṣe n ba ọpọlọpọ eeyan lori ilera oun, awọn dokita Naijiria lo ra oun pada.

Obey ni oun ti n gbero lati gbe orin sita lati salaye aarun jẹjẹrẹ inu koropọn lati sọ iriri oun fun awọn eeyan.

“Inu mi dun pe mo lakọja, ti mo si moribọ.”

Nnkan to yẹ ki o mọ nipa Prostate Cancer

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹya ara kekere to wa lapa iṣalẹ nkan ọmọ ọkunrin loloyinbo n pe ni Prostate.

Lede Yoruba a le pe ni isetọ tabi orisun oloje agbara atọ.

Prostate jẹ ọkan ninu awọn ẹya to wa ninu egungun ibara idi, o si jẹ ara nnkan ọmọkunrin.

Ẹya ara yii kere pupọ, debi pe ko tobi ju koro ahusa lọ.

O si wa laarin nnkan ọmọkunrin ati ile itọ, o si yi ọpa to n gbe itọ jade ninu ara ka.

Prostate yi lo ma n sẹto eroja to n pese atọ ọmọkunrin.

Bi ọkunrin ba ti n dagba si, o ṣeeṣe ki Prostate rẹ yi maa tobi ju ti tẹlẹ.

Amọ ti kokoro aisan jẹjẹrẹ ba wọ inu rẹ, o di Prostate Cancer niyẹn.

Ohun to maa n ṣokunfa aisan jẹjẹrẹ Prostate ko lakọsilẹ ṣugbọn o ni awọn nkankan to le jẹ ki eeyan wa ninu ewu aisan jẹjẹrẹ yii.

Ko si alaye lori rẹ ṣugbn awọn ọkunrin alawọdudu lo maa n ṣaba ni aisan jẹjẹrẹ Prostate yi ju awọn alawọfunfun lọ.

Awọn ọkunrin ti baba wọn tabi ọmọ iya wọn lọkunrin ba ko aisan yi naa a maa saba ko aisan jẹjẹrẹ yii.

Iwadii tun fi han pe awọn ọkunrin to ba sanra wa ninu ewu kiko aisan jẹjẹrẹ Prostate ju awọn ti ko sanra pupọ.

Iye awọn to n ba aisan yi lọ ni Naijiria

Gẹgẹ bi a ṣe salaye ṣaaju pe aisan jẹjẹrẹ Prostate yi a maa saba daamu awọn ọkunrin alawọdudu ju awọn alawọ funfun lọ.

Nilẹ Africa Naijiria ni ibi tawọn eeyan pọ si julọ toiri naa ninu awọn alawọdudu to n ba aisan yi lọ ti Naijiria ko kere.

Akọsilẹ taa ri sọ pe ida meji lo wa ninu ewu aisan jẹjẹrẹ yii.

Lọdọọdun o sọ pe eeyan ẹgbẹrun lọna ogun ni aisan jẹjẹrẹ yi maa n pa ni Naijiria.

Lọpọ igba ayẹwo ile iwosan a maa fihan pe awọn ti aisan yi ti wle siwọn lara lo pọ julọ.