Ìbò kíkà ti bẹ̀rẹ̀ báyìí ní Senegal lẹ́yìn tí ìdìbò wà s'òpin

Aworan to ṣafihan bi wọn ṣe n ka ibo ni Senegal

Kika esi ibo ti gbera sọ ni orileede Senegal lẹyin ti awọn eeyan ilẹ naa tiu yaya jade lati kopa ninu idibo aarẹ to waye lọjọ Aiku.

Nkan bi ago mẹfa irọlẹ ni idibo wa si opin ti awọn ibudo idibosi fi opin si ibo didi.

Lọpọ awọn ibudo idibo si ni kika ibo naa ti bẹrẹ nibi ti awọn aṣoju ẹgbẹ kọọkan naa si ti n bojuto bi nkan ṣe n lọ.

Ko yọ awọn onwoye eto idibo naa ti wọn wa niikalẹ lati ri pe gbogbvo nkan lọ letoleto.

Idibo to n waye yi lati yan aarẹ mii ni wọn ti ṣaaju dawọ rẹ duro fun ọsẹ meloo kan ti eleyi si fẹ da họwu họwu silẹ ki gbogbo nkan to pada niyanju.

Jakejado orileede naa ni awọn eeyan kun ori ila ti wọn ti fe dibo yan aarẹ laarin awọn

oludije mẹtadinlogun to kopa ninu idije naa.

O le ni oludibo miliọnu meje ti akọroyin wa jabọ pe wọn tuyaya jade lati wa kopa ninu idiboyi.

O mu iroyin wa bakan naa pe ko si wahala lọpọ ibi ti idiboti waye yatọ si awọn ibi kọọkan ti ikọlu ti waye laarin awọn oludibo kọokan ati awọn ọlọpaa.

O tun ṣo pe o le ni awọn onwoye idibo ẹgbẹrun kan labẹle ati lẹyinodi to kopa ninu eto yii.

Ninu awọn oludibo tojade lati kopa ninu idibo yila ti ri ọpọ awọn ọdọ ati obinrin to tu jade lati wa dibo.

Aworan awọn oludibo to kopa ninu idibo aarẹ Senegal
Wo bí ètò ìdìbò ààrẹ orílẹ̀èdè Senegal yóò ṣe wáyé lónìí
Apoti idibo ati ami idanimọ Senegal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oni, ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024, ni eto idibo aarẹ orilẹede Senegal yoo waye nibi ti oludije mẹtadinlogun yoo ti dije lati mọ ẹni ti yoo gba eto iṣejọba lọwọ Aarẹ Macky Sall.

Ọpọlọpọ iwọde ati ifẹhonuhan lo waye lati ọdọ araalu lẹyin ti Aarẹ Sall sun eto idibo naa siwaju l'osu to kọja.

Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Keji lo yẹ ki eto idibo naa waye sugbọn ile igbimọ aṣofin kọ lati buwọlu aba naa.

Eyi ni eto idibo kejila ti yoo waye ni orilẹede Senegal lati igba ti wọn ti gba ominira lọdun 1960.

Oludibo to le ni miliọnu meje ni igbagbọ wa pe, yoo kopa ninu eto idibo naa laarin apapọ miliọnu mejidinlogun eeyan to n gbe ni orilẹede naa.

Gẹgẹ bii ajọ eleto idibo Senegal ṣe sọ, aago mẹjọ owurọ ni eto idibo yoo bẹrẹ, ti yoo si pari ni ago mẹfa irọlẹ.

Bakan naa ni ajọ naa fi ọkan awọn araalu balẹ pe lakọ ni awọn wa lati ri i pe awọn ṣe ojuṣe to yẹ nipa eto idibo yii.

Eto idibo aarẹ yii lo jẹ igba akọkọ ti Aarẹ to wa lori oye ko ni kopa gẹgẹ oludije ninu eto idibo.

Ninu oṣu Keje to kọja ni Aarẹ Macky Sall kede lẹyin ọpọlọpọ ijiroro pe oun ko ni kopa ninu eto idibo ti ọdun yii.

Oludije mẹtadinlogun n dije fun ipo Aarẹ Senegal sugbọn awọn meji lo n lewaju, iyẹn, oludije ẹgbẹ oṣelu alatako, Bassirou Diomaye Faye ati Amadou Ba, olootu ijọba tẹlẹ.

Awọn oludije mẹta kan ti juwọlẹ silẹ fun Faye, paapa ọmọ Aarẹ tẹlẹ, Abdoulaye Wade, ẹni ti wọn fi ofin de pe ko le díje.

Gbogbo awọn oludije naa lo ti ṣe ileri pe awọn yoo gbe ogun ti bi ko ṣe si iṣẹ ni ilu fun awọn ọdọ ati atunṣe eto ọrọ aje to mẹhẹ.

Ki lo ti sẹlẹ ṣaaju?

Awọn oludije to n lewaju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu oṣu Keji ni ile aṣòfin ni Senegal fọwọ si aba ofin kan ti Aarẹ Macky Sall gbe kalẹ lati fi sun jọ saa rẹ siwaju to si tun sun ọjọ idibo to yẹ ko waye ni ọsẹ mẹta sẹyin.

Khalifa Sall to jẹ eekan ẹgbẹ alatako ati olori ilu Dakar sọ pe idiwọ yi jẹ ''iditẹgbajọba nipa lilo ofin'' to si kesi araalu lati tako igbesẹ yii.

Agbarijọpọ ẹgbẹ alatako rẹ ti lawọn yoo gba ile ẹjọ lọ lori ọrọ yii.

Thierno Alassane Sall juwe rẹ gẹgẹ bi iwa ''iditẹgabjọba to lagbara'' to si sọ fun awọn alatilẹyin ti rẹ naa pe, ki wọn pejọ ṣe iwọde niwaju ile aṣofin.