Wo àwọn àpẹrẹ méjìlá tó ń ṣàfihàn pé èèyàn ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú

Àkọlé fídíò, Wo àwọn àpẹrẹ méjìlá tó ń ṣàfihàn pé èèyàn ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú
Wo àwọn àpẹrẹ méjìlá tó ń ṣàfihàn pé èèyàn ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú

Arun jẹjẹrẹ jẹ ọkan lara awọn arun to buru julọ lagbaye.

Arun naa buru to bẹẹ ti awọn onimọ sọ pe ko din miliọnu mẹwaa eeyan ti arun ọhun n pa lọdọdun.

Oniruru arun jẹjẹ rẹ lo wa, lara re ni arun jẹjẹrẹ ọmu, eyii to maa n ba awọn obinrin finra.

Lọdun 2020 nikan, nnkan bii 685,000 obinrin ni arun naa mu ẹmi wọn lọ kaakiri agbaye gẹgẹ bii atẹjade ajọ WHO.

Awọn apẹrẹ arun jẹjẹrẹ ọmu ree

Breast cancer

Oríṣun àwòrán, Pexels/Klaus Nielsen

  • Lile awọ ara
  • Tọrọ ẹrẹkẹ
  • Apa lori ọmu
  • Omi to n jade lori ọmu
  • Inira ọmu
  • Isunki ọmu
  • Yiyọ koko
  • Iṣan to n farahan lara ọmu
  • Iyipada bi ọmu ṣe tobi si

O ṣe pataki fun obinrin lati mọ bi ọmu rẹ ṣe ri ko si maa ṣe ayẹwo rẹ loorekoore.

Amọ o gbọdọ kan si dokita rẹ ti o ba n ri iyatọ ninu ọmu rẹ tabi ti o ba n ri ọkan tabi ju bẹẹ lọ lara awọn apẹrẹ wọnyii lara ọmu rẹ.