"Bí mo ṣe ń rọbí lọ́wọ́ ní Gaza ni àdó olóró orílẹ̀-èdè Israel ń dún léraléra"

Oríṣun àwòrán, Jumana Emad
- Author, By Dalia Haider
- Role, BBC Arabic
Oṣu kan sẹyin ni asiko ikunlẹ to fun Jumana Emad, to jẹ alaboyun.
Pẹlu idunnu ati ayọ lo fi n pin aworan oyun rẹ pẹlu ikun nla fun awọn ọrẹ ati mọlẹbi rẹ, to si n duro de ọjọ ikunlẹ naa.
Ayẹwo ti fi han ṣaaju pe ọmọbinrin lo wa ninu rẹ, pẹlu ayọ si ni ọkọ rẹ fi di ẹru ọmọ silẹ lọna ati lọ sile iwosan, toun pẹlu ọmọ wọn to jẹ ọmọmọdun mẹrin.
Amọ lojiji ni gbogbo eto naa dojude lẹyin ti ẹgbẹ agbesumọmi Hamas kọlu Israel.
Ninu ikọlu naa ni Hamas ti ṣekupa eeyan 1,400 ti wọn tun ji eeyan 200 mii gbe lọ lọjọ keje, oṣu keje, ọdun 2023.
Ṣugbọn orilẹ-ede Israel ko duro rara ki oun naa to bẹrẹ si n da ado oloro pada si agbegbe Gaza, ninu eyii ti Hamas ti sọ pe eeyan 7,000 ti dagbere faye.
Jumana sọ fun BBC pe “Ẹru ba mi gidi. Bi mo ṣe n rọbi lọwọ ni mo n gbọ iro ado oloro to n dun leralera.”
Ẹni ọdun marundinlọgbọn naa, to jẹ akọroyin sa kuro nile rẹ gẹgẹ bii aṣẹ ijọba Israel.
Ọjọ keji ti Israel bẹrẹ si n ju ado oloro si Gaza lo kuro nibẹ lọ si agbegbe Guusu.
Aṣọ kan ṣoṣo, baagi kekere pẹlu agolo miliki kan ṣoṣo ni Jumana mu kuro nile ko to salọ si ọdọ ibatan rẹ kan.

Oríṣun àwòrán, Jumana Emad
Jumana ṣalaye siwaju si pe “A ko le sun loru nitori bi ọpọ ado oloro ṣe n dun lẹmọlemọ.
“Nigba to ya, a kuro nibi ti a wa lọ si ibomiran. Mo ri awọn alaboyun bii temi ti awọn naa n rin kaakiri nitori o ṣoro fun wa lati lọ ra ounjẹ.”
O ṣalaye nipa bi wọn ko ṣe ri ina mọnamọna lo ati bi okun ẹrọ ayelujara ṣe ja.
Yatọ si inu ibẹrubojo ti wọn wa, o ni wọn ko tun ri omi mu.
Nigba ti yoo di ọjọ kẹtala, oṣu Kẹwaa yii ni Jumana bẹrẹ si n rọbi.
Ṣaaju ikọlu naa lo ti kọkọ murasilẹ lati lọ sile iwosan Al-Shifa niluuu Gaza lati bimọ amọ erongba rẹ ko bọ si bo ṣe lero.
Lẹyinorẹyin, o lọ sile iwosan Al-Awda to wa nilu Nuseirat, eyii t jẹ ile iwosan kekere.
O ni o ṣoro lati ri dokita ti yoo gbẹbi oun nibẹ.
“Awọn awakọ ero n bẹru bẹẹ ni awọn ọkọ ile iwosan ‘ambulance’ ko ri aye lati gbọ ti alaboyun kankan.”
Ninu ọrọ rẹ, asiko ikunlẹ naa nira gidi nitori bi ado oloro ṣe n balẹ n itosi ile iwosna.
O ni “Ado oloro n balẹ sori ile to wa lẹba ile iwosan naa, ado oloro ọhun dun to bẹẹ ti mo ro pe o ti balẹ sile iwosan ti mo wa.”
“Iṣẹju-iṣeju ni wọn n gbe awọn to farapa wọ ile iwosan ọhun, bẹẹ ni mo n gbọ ti awon eeyan n kigbe lọtun-losi.”
Lẹyinorẹyin, Jumana bi ọmọ obinrin jojolo.

Oríṣun àwòrán, Jumana Emad
Ajọ United Nations Population Fund (UNFPA) ni nnkan bii ẹgbẹrun lọna aadọta alaboyun lo wa ni Gaza, ti ẹgbẹrun marun un abọ ninu wọn yoo si bi ọmọ laarin ọgbọn ọjọ si asiko yii.
UNFPA sọ pe ọpọ ile iwosn lo kun fọfọ, ti oogun atawọn ohun elo itọju mii i ti n tan nibẹ.
Lẹyin ọjọ kan to bi ọmọ tan, Jumana fi fidio ara rẹ ati ọmọ naa ranṣẹ ninu ọkọ ero kan.
O ti kuro nile iwosan bayii lati darapọ mọ awọn mọlẹbi rẹ, amọ o ni oun ko le ṣalaye tan ohun ti oju oun ri lariko irọbi.
Jumana ni ko rọrun lati bimọ niru asiko bayii, paapaa latari ohun ti oun la tun la kọja.
O ni “Ti kii ba ṣe ti ogun to waye ni, yoo wu mi lati ṣe ajọyọ nla lẹyin ọsẹ kan ti mo bimọ tan.”
“Yoo wu mi lati fiwe pe gbogbo awọn mọlẹbi mi sibi ayẹyẹ naa lati ṣe Aqiqah fun ọmọ naa.”
Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ lọjọ iwaju nipa ogun to n lọ lọwọ, o ni inu oun dun fun ọmọ tuntun jojolo naa nitori pe “ọmọ naa ni ireti mi lẹyin ti ogun ba pari.”








