Wo àwọn tó ń gbọ̀nà tó léwu jápa lọ sí Canary Islands nílẹ̀ Yúrópù láti Áfíríkà, ọ̀pọ̀ ló b'ómi lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Irinajo sí Canary Islands jẹ iriri kan ti Aboubacar Drame ko le gbagbe laelae bi o ti wu ki ọdun gori ọdun to.
Otutu, ẹru pẹlu omije l'oju agbami ninu ọkọ oju omi onipako.
Ọgọọgọrun un awọn eeyan lati ilẹ Afirika lo bẹrẹ irinajo sí orilẹ ede Spain lati le wọ ilẹ Yuroopu.
Drame jẹ ọkan lara wọn.
Ni ọmọ ọdun metadinlogun ni o fi ẹkun Kayes lorilẹ ede Mali.
O bẹrẹ irinajo lori omi lati orilẹ ede Mauritania, leyin ọjọ mẹrin lo de Gran Canarias.
Ori lo ko o yọ tori ọpọ lo ku l'ọna.
Laarin oṣu mẹfa àkọkọ ninu ọdun 2023 yii, eeyan 778 lo ti ku l'ọna irinajo wọn sí erekusu Canary Islands gẹgẹ bi akọsilẹ Caminando Fronteras to mọ nipa agbegbe naa fun bi ogun ọdun ṣe sọ.
Drame ni "a rìnrìn ajo wa fun ọjọ mẹta, ọjọ kẹrin ni a de ibi ti a n lọ," Ohun ti Drame sọ ninu fidio kan niyii fun BBC Mundo nipa irinajo rẹ lọdun 2006 ọdun ti ijọba pe ni ọdun ijamba ọkọ oju omi.
Igba ti oorun ba wọ lo buru julọ.
Ohun ti iwọ oorun tumọ si ni iya, otutu, ati okunkun birimu.
Drame ni oru ni otutu maa n pọju nítorí awọn kii le sun titi ti irinajo naa yoo fi pari.
O rántí b'awọn eeyan kan ṣe n bi ati oorun to lagbara ninu ọkọ oju omi.
Erekusu Canary Island yoo gbami ẹyẹ pẹlu awọn arìnrìn-àjò aṣatipo 7,500 to dé síbẹ loṣu Kẹwaa ọdun yii nìkan.

Oríṣun àwòrán, COURTESY
Èèyàn mokandinlogun lo wa pẹlu rẹ.
Eeyan bíi 30 sí 50 ni pateras, ọkọ oju máa n saba ko.
Amọ, awọn to wọ ọkọ oju omi pẹlu rẹ mọ níwọ̀n.
Irinajo lori okùn ko rọrun rara, Drame ti ko jẹ ti ko mu ninu irinajo lo sọ bẹẹ.
O ti rẹ wa nígbà ti a de ebute tan.
Awọn agbalagba n sunkun, awọn ni kini ọhun ṣakoba fun julo.
Ni igba gbogbo ni a maa n gbọn omi to ba wọ inu ọkọ oju omi ti a wà ninu rẹ kuro.
Lojoojumo ni a máa n ri ẹsẹ sinu omi.
Drame ṣalaye nipa nkan to ṣe okunfa arun to mu ùn lara.

Nigba mii, àìsí oúnjẹ ati omi maa n jẹ ki wọn mu omi okun.
Bayii ni awọn ẹya ara bẹrẹ sí ni da iṣẹ silẹ.
Nigba mii lara kò ní mọ igba ti wọn bẹ sí omi pẹlu ero pe wọn ti dé ibi ti wọn n lọ ti yoo si ri loju agbami.
Ori ko Drame yọ ni tiẹ tori wọn le ri ẹnjinni ọkọ oju omi wọn tun ṣe.
Ọpọ ọkọ oju omi lo da iṣẹ silẹ yala tori epo tan tabi ki wọn dẹnu kọlẹ̀.
Caminando Fronteras ni ọkọ oju omi 244 lo poora laarin ọdun 2018 sí 2022.

Agbẹnusọ Caminando Fronteras, Helena Maleno sọ pe ọna ori omi okun lo léwu jùlọ́ lagbaaye.
Nọmba awọn to ku ju ìyè awọn ti iroyin gbe lọ tori Caminando Fronteras gangan an ni orisun iroyin to wa nibẹ.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ IOM to n tọ pinpin awọn aṣatipo to poora, eeyan 422 lo ti ku tabi poora lọdun yii, eleyii to fi idà mọkanlelogun ju awọn eeyan to ku lọ lọdun 2022.
Ajọ IOM ni oun gbagbọ pe awọn ọkọ oju omi to ri ju ìyè ti iroyin gbe jade lọ.
Pẹlu akọsilẹ yii, Drame mọ pe ori lo koun yọ.
O ni awọn eeyan kan ku nini ọkọ oju omi tàwọn kan wa rẹ.
Amọ, iru rẹ ko ṣẹlẹ sí awọn.

Oríṣun àwòrán, COURTESY
€700 ni o san lapapọ.
Ọpọ oloselu lo maa n sọ nipa fifi eeyan ṣe katakara, amọ "awọn eeyan gan an fun ra wọn lo maa n beere ibi ti wọn ti le ri tikẹẹti ra.
Drame ni apẹja l'awọn awakọ oju omi maa n saba jẹ ti wọn si ti ṣiṣẹ naa fun ọpọlọpọ ọdun.
Ṣe ni wọn maa n ri bi apo anọma.
Drame nikan ni ọmọde to wa lara awọn arinrin ajo yii.
"Awọn obinrin kii saba wọ ọkọ oju omi lati orilẹ ede Mauritania, tori ọpọ ninu ko mọ odo wẹ."
Amọ, eleyii ko da Drame duro lati ma rìnrìn ajo naa.
Manuel Barroso to jẹ adari ileeṣẹ ijọba to n doola ẹmi awọn eeyan lori omi sọ pe"a ti n doola ẹmi awọn eeyan fún ọpọlọpọ ọdun ṣugbọn nkan to yẹ kí a mọ ni pe wọn o mọ odo wẹ.
Ìyẹn ni wọn maa n fi tete lọ si isalẹ omi tori wọn le lefoo lori omi.
Barroso ni kete ti ẹnikẹni ba ti bọ sinu agbami, ninu ki ẹ doola ẹmi ẹni naa tabi ki o bá omi lọ ikan maa ṣẹlẹ níbẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ewu n bẹ fun onikaluku kete ti a ba ti tẹsẹ bọ omi.
Oju ọjọ, bi ọkọ oju omi ṣe ri, ìye eeyan to wa ninu ọkọ naa, gbogbo lo ni ipa wọn.
Barroso ni agbami okun lewu púpọ.
Oju ọjọ maa n yipada tàwọn eeyan ba ti dé agbami okun lati Afirika.
Bayii ni agbami okun ṣe di saare ti a kò foju ri pẹlu bi a kò ṣe mọ iye eeyan to n ku sinu rẹ ti wọn ko si ni wa soke laelae.
Ida merindinlaadorun eeyan to ku sinu okun laarin ọdun 2021 sí 2023 ni oku wọn poora gẹgẹ bi Cruz Oran ṣe sọ.
Awọn oṣiṣẹ adoola emi to le ni 300 lo n ṣiṣẹ lojumọ ni erekusu Canary Islands nìkan.
Barroso ni irinajo to dàbí ki eeyan wa ninu ọkọ ni ẹkun kan to to ilọpo mẹta orilẹ ede Spain.
Asiko to lewu ni asiko idoola emi, niṣe ni ẹru maa n ba awọn eeyan to wa ninu ọkọ oju omi yii.
Gbogbo wọn a sa lọ sibi kan naa ninu ọkọ oju omi eleyii ti yóò mu ọkọ danu.
Bayii ni a sí bẹrẹ sí ni maa ko eeyan bíi àádọta sí ọgọrin kuro ninu omi.
Barroso ni oju awọn to n rìnrìn ajo yii maa n kọrẹ lọwọ ati pe o ti maa n rẹ wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Barroso sọ pe ni ṣe l'awọn maa n da oku awọn to ba ti ku sinu omi ti irinajo bá jiná.
Wọn maa n fun mọ ara wọn débi pe kò ni saye rara fún ẹnikẹ́ni.
Nigbeyin gbẹyin, oru lo maa n p'awọn eeyan to ba wa ni isalẹ.
Ìdí niyii ti irufẹ ọkọ oju omi ati bi Irinajo ba ṣe jina si fi ṣe pàtàkì.
Àkọsílẹ Frontex fidi rẹ mulẹ pe awọn aṣatipo lati orilẹ ede Morocco, Guinea, Ivory Coast ati Senegal lo gunlẹ sí Canary Islands lọdun 2022 ni irinajo to maa n gba wọn ní ọjọ mẹsan an.
A gbọ iroyin Thiambou Samb ọmọ ọdun metadinlogun to wọ ọkọ oju omi lati Senegal lọdun 2006 to sí gunlẹ sí Tenerife pẹlu eeyan 137 mii.

Oríṣun àwòrán, COURTESY
"Lẹyin ọpọ ọdun ti mo ri fiimu kan ti wọn n pe ni "The Diary of Anne Frank" ni mo mọ pe mo wa ni ipagọ," Samb lo sọ bẹẹ.
Mi o mọ pe iriri buruku n duro de mi ni Spain ju ohun ti oju mi ri nínù ọkọ oju omi lọ.
Oṣu mẹta ni Samb fi sun sí abẹ afara niluu Valencia lori odo Turia.
Mo wọ ọkọ oju omi lọ sí orilẹ ede Spain lati mọ ìtumọ iṣẹ ati osi.
Orilẹ ede Spain ni mo ti mọ ìtumọ ki eeyan jẹ alawọdudu.

Oríṣun àwòrán, COURTESY
Enikan lo bi mi lere lọjọ kan pe ki ni mo fẹ jẹ gan an.
Mo salaye fun ẹni naa pe apẹja ni mi sugbọn mo fẹran lati maa ṣe eré ori itage.
Ibeere pada se iranwọ tori pe o pada darapọ mọ ẹgbẹ oṣere kan nibi to ti pade oludari ẹgbẹ William Shakespeare to wa ni ilu Valencia ti ri i.
Lati ibẹ lo ti lanfaani lati kópa ninu ere bii "The Silence of the Swamp," "Black Beach" ati "Riot gear" to jẹ ilumọọka.
Ni bayii, o gbèrò lati gba ami ẹyẹ Goya ati lati maa ri owo tabua lori ìkànnì TikTok nibi ti o ti n ṣe ilanilọyẹ nipa ìṣòro tàwọn eeyan n doju kọ.












