Wo àwọn ọmọ Áfíríkà tó wá lára èèyàn tí Hamas mú nígbèkùn láti Israel

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ilẹ Israel ti kede pe awọn ọmọ Afirika mẹta lo wa lara awn eeyan ti ikọ ologun Hamas ko lẹru lasiko ti wọn kogun ja ilẹ naa.
Awọn adulawọ naa ni wọn jẹ ẹnikan to jẹ ọmọ bibi orilẹede Tanzania ati South Africa meji amọ wọn ko darukọ wọn.
Bẹẹ ba gbagbe, eeyan okoolerugba ati mẹrin (224) ni apapọ eeyan ti ikọ ologun Hamas ko sigbekun wọn lasiko ti wọn ja orilẹede Israel logun lọjọ keje osu Kẹwa ọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ọmọ bibi orilẹede mẹẹdọgbọn lo wa ni igbekun ikọ ologun Hamas"
Ilẹ Tanzania si ti fidi rẹ mulẹ pe ọkan lara awn ọmọ orilẹede wọn ti di awati.
BBC ba ọkan lara awọn ẹbi ti eeyan wa ni ahamọ Hamas naa sọrọ, Joshua Mollel, tii se akẹkọọ nipa eto ọgbin ni Kibbutz, nibi ti ikọ Hamas ti ko awọn eeyan naa lọ si ahamọ.
Lọwọlọwọ bayii, awọn ọmọ bibi orilẹede mẹẹdọgbọn lo wa ni igbekun ikọ ologun Hamas, gẹgẹ bi orilẹede Israel ti fidi rẹ mulẹ.











