"2019 ní bàbá Justina ti kú, òun nìkan ní obìnrin, ìyá rẹ̀ sì ń jìyà láti tọ́ òun àti ẹgbọ́n rẹ̀ mẹ́ta ní fásitì"

Oríṣun àwòrán, Rivers state police
Ikú akẹkọbinrin kan, Justina Otuene Nkang, ti ọpọ eeyan mọ si Tiffany, ti n mu ki ọkan eeyan gbọgbẹ, paapaa ọna ti akẹkọbinrin naa gba jade laye.
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ọmọbinrin naa, tii se akẹkọọ ọlọdun kẹta ni fasiti Portharcourt, ni wọn ba oku rẹ nile ọrẹkunrin rẹ.
Ọrọ naa si ti n da awuyewuye silẹ, paapaa lori ayelujara.
Ni ọjọ ẹti ni ileesẹ ọlọpaa se ipade akọroyin lati fi to araalu leti nipa bi isẹlẹ naa se waye ati ọna ti ọwọ wọn fi ba ọrẹkunrin Tiffany.
Òórùn òkú Tiffany ló ń dá àwọn aládùúgbò láàmú, tí wọn ṣe wá fi tó ọlọ́pàá létí - Kọmisana ọlọpaa
Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Rivers, Polycarp Nwonyi si ti fidi rẹ mulẹ pe Justina Nkang, ẹni ogun ọdun ni ọkunrin naa pa.
O ni deede aago meji ọsan ọjọru, ọjọ Kẹẹdọgbọn osu kẹwa ọdun 2023 ni awọn aladugbo kan wa fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpa Ozuoba.
Koko ẹsun ti wọn mu wa si ni pe oorun buruku kan n jade latinu ile afurasi naa, ti ọga ọlọpaa ibẹ si ni kawọn osisẹ rẹ lọ wo ile naa wo.
“Awọn osisẹ wa fi tipatipa ja ilẹkun wọle, ti a si ri baagi Ghana Must Go, ti wọn di oku ọmọbinrin naa si.
Ọwọ wa si ti tẹ ọkunrin naa lasiko to n gbinyanju lati salọ.”
Kọmisana ọlọpaa ni ọrẹkunrin naa, tii se ẹni ọdun mẹrinlelogun lo jẹ akẹkọọ nipa imọ ẹrọ ni fasiti Portharcourt.
O si sẹsẹ ko de adugbo naa ni bii ọsẹ kan sẹyin ko to di pe isẹlẹ buruku yii waye.
Kọmisana ọlọpaa ni wọn ti gbe ẹjọ ọrẹkunrin naa lọ si ẹka ileesẹ ọlpaa ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii to yẹ.

Oríṣun àwòrán, Rivers Police Command
"Wọn ti ge ẹya ara Tiffany lọ amọ ọrẹkunrin rẹ ko tii salaye bo se jẹ"
Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Rivers fikun pe ọpẹlọpẹ ọdẹ adugbo kan to n sisẹ loju ọna ileesẹ amohunmaworan ijọba apapọ ilẹ wa, NTA-Mgbuoba nilu Portharcourt, to se awari oku ọmọdebinrin naa.
Ọwọ si tẹ ọrẹkunrin akẹkọbinrin naa, tii se ẹni ọdun mẹẹdọgbọn lasiko to n gbe oku rẹ lọ, ti ọdẹ naa si ransẹ pe awọn ọlọpaa.
Awọn fidio ti wọn n pin lori ayelujara lo se afihan ọrẹkunrin naa ti awọn ọlọpaa ti ko sẹkẹsẹkẹ si lọwọ, to si mu awọn agbofinro naa lọ sile rẹ.
Ile ti ọrẹkunrin ọhun si mu awọn agbofinro lọ lo dabi ibudo ti wọn ti n ya aworan (Studio), ti kẹkẹ ọmọlanke kan si wa nibẹ.
Ninu kẹkẹ naa si ni oku ọrẹbinrin rẹ wa, ti wọn si ti ge awọn ẹya ara rẹ kan kuro, bẹẹ ni ọkunrin naa ko le salaye ohun to sẹlẹ si awọn ẹya ara Justina naa.
Ọkunrin naa si jẹwọ pe inu ile oun ni ọmọbinrin naa ku si.
Nigba to n salaye idi ti ko fi lọ sọ fun awọn ọlọpaa pe Justina ọrẹbinrin oun ti ku sinu ile oun, o ni oun se aisan, ti oun ko si le jade.
Bi o tilẹ jẹ pe oku Tiffany ti n run, sibẹ kunrin naa si ku sinu ile naa lai naani oorun buruku to gba gbogbo ibẹ kan.
A fẹ idajọ ododo lori iku ọmọ wa tori ko ni baba laye, iya rẹ nikan lo n da tọ - Ẹbi Justina
Wayi o, Ọgbẹni John Otuene tii se aburo baba Justina ti salaye fun BBC pe ẹbi awọn n beere fun idajọ ododo lori iku to pa ọmọ wọn, ti wọn lo jẹ ọmọbinrin kansoso ti awọn ni, to si jẹ oun ni ọmọ awọn kẹrin.
Ọdun 2019 lo salaye pe baba Justina ku, ti iya rẹ nikan soso si n sa ipa rẹ lati tọ oun ati awọn ẹgbọn rẹ, ti gbogbo wọn jẹ akẹkọọ ni fasiti Uniport.
John ni ọjọ Ẹti to kọja ni wọn se akiyesi pe Justina ko pada wa sile lati ibi to ti n se idanilẹkọ imọ ẹkọ rẹ (Internship), ti wọn si n wa kiri lai ri.
Idi ree to ni awọn se lọ fi isẹlẹ yii to awọn agbofinro leti, ti wn si ri oku rẹ nile ọrẹkunrin rẹ.
“Inu wa ko dun rara, ti ọkan wa gbọgbẹ pe ọmọ wa ku, a si n fẹ idajọ ododo nipa iku rẹ.
A ko fẹ ki awọn ọlọpaa da asọ bo isẹlẹ yii gẹgẹ ba se n gbọ nipa awọn isẹlẹ miran, a fẹ idajọ ododo fun mọ wa.”
O wa se apejuwe Justina bii oniwa tutu bii adaba, to si maa n se awada, a si nireti pupọ lori rẹ pe yoo de ibi giga lai mọ pe ẹnikẹni le da ẹmi rẹ ni egbodo.

Oríṣun àwòrán, Tiffany Otuene
A dá ọkunrin to pa Justina mọ bii ọrẹkunrin rẹ tori aburo wa fi aworan rẹ soju foonu rẹ - Awọn ẹgbọn oloogbe
Bakan naa ni awọn ẹgbọn Justina salaye pe awọn mọ ọrẹkunrin aburo awọn naa nitori awọn ti ri aworan rẹ lori foonu rẹ ni aimọye igba.
Wọn ni idi ree ti awn fi tete da ọkunrin naa mọ nigba ti awọn ọlọpaa se afihan rẹ.
Amọ wọn ni awọn ko mọ pe o le sekupa aburo awọn tabi ba oku rẹ ninu ile rẹ.
Wọn ni awọn sẹsẹ tu ọfọ iku Justina fun iya awọn ni, ti ọkan rẹ si ti bajẹ pupọ amọ awọn ni ireti ninu Ọlọrun pe idajọ ododo yoo waye lori iku rẹ.

Oríṣun àwòrán, AWAJIS GEORGE/TIFFANY OTUENE
Ọ̀rẹ́kùnrin pa akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Uniport, gbé òkú rẹ̀ sínú ilé títí tó fi ń rùn
Iku akẹkọọ Fasiti ilu PortHarcourt, Justina Otuene Nkang lo ti da ọpọlọpọ rogbodiyan silẹ lẹyin ti awọn ẹsọ alabo sawari oku rẹ ninu apo saka ninu ọmọ lanke ti ololufẹ rẹ gbe si.
Tiffany lo jẹ akẹkọọ ipele UNIPORT to wa nipinlẹ Rivers lorilẹede Naijiria.
Bakan naa ni awọn mọlẹbi Justina Otuene Nkang kede pe awọn n wa lẹyin to di awati lọjọ mẹrin sẹyin.
Nkang lo n se idanilẹkọ lọwọ ni ile iwosan aladani kan niluu Port Harcourt, to si jẹ pe ibẹ lo wa gbẹyin, ko to di awati.
"Ọpọlọpọ ẹjẹ lo wa layika ibi ti ọkunrin naa gbe oku akẹkọọ naa si"
Iroyin to tẹ wa lọwọ ni awọn ẹsọ alabo to n sọ ọna NTA ni agbegbe Mgbuoba niluu Port Harcourt, lo sawari oku ọdọmọbinrin naa.
Awọn ẹsọ alabo ni ọwọ awọn tẹ ọkunrin naa, ẹni ti wọn pe ni ọrẹkunrin Nkamg nigba to fẹ gbẹyin gbe oku naa jade kuro ni agbegbe naa, ti wọn si ransẹ pe Ileeṣẹ Ọlọpaa.
Fọnran to wa lori ayelujara safihan bi ọkunrin naa ṣe ti wa ni sẹkẹsẹkẹ, to lewaju ileeṣẹ ọlọpaa lọ si ibi to oku akẹkọọ naa.
Bakan naa ni fọnran naa safihan pe ọkunrin naa gbe oku akẹkọọ naa to jẹ ọrẹbinrin rẹ ninu Ọmọlanke , ti ẹjẹ si pọ ni ayika ile naa.
Ọpọlọpọ ẹjẹ lo wa layika ibi ti ọkunrin naa gbe oku akẹkọọ naa si.
Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Rivers ti ransẹ pe awọn akọroyin lati salaye ohun to waye lẹkunrẹrẹ lonii.
















