Àwọn àpẹrẹ tó yẹ kí òbí mọ̀ bóyá ọmọ wọn tí n kojú ìfipábánilopọ̀

Ọmọbinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Laipẹ yi ni ileẹjọ ijọba ipinlẹ Eko to n mojuto iwa ipa si eeyan dajọ ẹwọn gbere fun Dokita kan Femi Olaleye ti wọn ri pe o jẹbi ifipabọmọde lopọ.

Dokita Olaleye ni oludari ileewosan Optimal Cancer Care Foundation ti wọn si fẹsun kan an pe o fipa ba ibatan iyawo rẹ ọmọ ọdun mẹẹdogun lopọ.

Ileẹjọ yi to fidi joko si agbegbe Ikeja sọ pe lootọ ni dokita naa hu iwa buruku yi lẹyin ti wọn ri pe gbogbo aijare ti wọn mu ko o jẹri si pe gbogbo ọrọ ti ọmọdebinrin yi sọ nipa rẹ jẹ otitọ.

Lẹnu lọọlọ yi ni Naijiria, awọn iṣẹlẹ ifipabọmọde lopọ jẹ nkan to gbode.

Tohun ti pe wọn n dajọ ijiya fawọn to n hu iwa yi, ọpọ lo ṣi mura si fifi ipa bọmọde lopọ laibikita.

Idi ree taa fi tọ awọn onimọ lọ lati bawa ṣalaye ohun to yẹ ki obi maa fura si lati le tete mọ ti ọmọ wọn ba ti n koju ifipabanilopọ.

Ati ọmọ ọkunrin ati obinrin lo n koju iwa buruku yi gẹgẹ bi ohun ti akọṣẹmọṣẹ Elizabeth Azubuike kọkọ fi bẹrẹ alaye rẹ fun wa.

Azubike jẹ oludasilẹ ajọ ẹlẹyinju aanu Total Child Initiative to si tun jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ to n mojuto aabo ẹkọ ati idaabo ọmọde.

Awọn aami pataki tabi apẹẹrẹ ree to ni o yẹ ki obi kọọkan maa fura si to ba ti n waye pẹlu ọmọ wọn to n koju ifipabanilopọ.

Ọmọ yoo bẹrẹ si ni ka sio sio

Akọkọ ni pe ọmọ to maa n ṣere daada yoo bẹrẹ si ni ka siosio ti ko si ni maa ṣere daada bi ti tẹlẹ mọ.

Dokita Azubuike sọ pe apẹẹrẹ kan ree to le tọka si pe awọn kan ti n ṣe ọmọ yi ni aburu ti awọn obi rẹ ko si mọ.

O ni bawọn obi ba ti ri pe ọmọ wọn n ka siosio, ki wọn pe sọdọ lati le mọ nkan to n ba iru ọmọ bẹẹ finra.

''To ba ṣe pe ọmọ naa yi kere, ẹkun ni yoo maa sun ni paapa ti wọn ba ranti nkan ti ẹni to ṣe aburu si wọn yi ṣe fun wọn.''

BBC tun ba akọroyin kan to n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ redio Wazobia FM Uche Nwanyiocha.

Lori eto rẹ, a maa saba sọrọ nipa ifipaba ọmọde lopọ.

Oun naa ba wa dasi ọrọ yi to si ni ''Ti ọmọde ba ti n da wa lọtọ, apẹrẹ nla ree wipe o ṣeeṣe ki eeyan kan ti maa fipabaalopọ.''

O ni awọn obi yẹ ko fura pe nkan ti ṣẹlẹ''ti ọmọ to ba n ba wọn sọrọ daad ṣadede n ka siosio lai da si eeyan kankan''

''Ni paapa ọmọ taa mọ pe ọlọyaya lo jẹ to fẹran lati maa ṣere,ti o ba ti n da wa lọtọ, ki a tete wa nkan ṣe''

Ọmọ yoo maa bẹru ẹni to n yọ mọ tẹlẹ

Apẹrẹ mii tawọn onimọ ṣalaye fun wa ni pe ti ọmọ ba ti n sa fun ẹni to maa n yọ mọ daada tẹlẹ, nkan to jọ mọ ifipabanilopọ le ti maa waye.

Wọn sọ fun wa pe tawọn obi ba darukọ ẹni naa tabi ti wọn ni ki ọmọ lọ ṣere lọdọ rẹ ti ẹru si bẹrẹ si ni ba ọmọ bayii, ka fura si pe o le ti maa ṣe aburu si ọmọ yi ni nipa ibalopọ.

''Apẹrẹ nla leyi jẹ ti wọn ba ti n bẹru eeyan ti wọn fẹran tẹlẹ.Awọn obi ni lati beere lọwọ ọmọ pe''ki lo de to fi n sa fun buọda lagbaja tabi anti tamẹdun'' Ugbochukwu sọ pe ohun ti obi yẹ ko gbe ni igbesẹ ree ko ma ba lewu lọjọ iwaju.

Labẹ isọri kekere kan lawọn apẹrẹ bi pe ki ọmọ tun maa tọọle ni ọmọ to ṣepe kii ṣe bẹ tẹlẹ.

Dokita Azubuike sọ pe bẹẹ naa lo yẹ ki obi maa fura ti ọmọ ba n ja haunhaun si awọn eeyan.

Ọmọ ti kii fa wahala le bẹrẹ si ni koju ija si eeyan latari pe o le ro wipe iru eeyan bẹẹ fẹ hu iwa ifipabanilopọ si.

Ki ni obi le ṣe ti ọrọ ba di bayii?

Ti awọn obi ba ti ri wi pe awọn ọmọ wọn ti n foju wina ifipabanilopọ ki wọn tara gbe wọn lọ si ọdọ awọn onimọ iṣegun lati ri aridaju pe iru nkan bayii n waye.

Bẹẹ naa lo ṣe pataki ki obi ri wi pe awọn fi ifẹ to pọ gaan an han si iru ọmọ bẹẹ.

Loore koore lo ṣe pataki ki obi maa fi da ọmọ naa loju pe kii ṣe ẹbi rẹ ni pe iru nkan aburu yi waye ati pe awọn ko da lẹbi pe o ṣe gba alaburu laaye .

Lẹhin igba naa, o yẹ ki obi wa fi da ọmọ bẹẹ loju pe awọn yoo ṣa gbogbo ipa latui daabo bo ati pe iru nkan bayii ko ni de si mọ ni aburu.

Awọn akọṣẹmọṣẹ taa ba sọrọ tun sọ fun wa pe ka obi ti wọn ba fipabaọmọ rẹ lopọ ri pe o kan si ẹka ijọba to n pese itọju ati aabo lọwọ iwa ipa si ọmọde.

Bakan naa ni ẹka to n risi iru ọrọ bayii ni ileeṣẹ ọlọpaa naa wa lati ṣe iranwọ ti wọn ba ri pe nkan bayii ṣẹlẹ.

Ki awọn obi ati awọn ọmọ yi naa gbiyanju lati lọ fun idanilẹ tori pe iru iṣẹlẹ bayii a maa da ọgbẹ si ọkan ọmọ ati obi .

Iwa ifipabọmọde lopọ n peleke si lawujọ

Ni nkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin niṣe laa n gbọ iroyin lorisi nipa awn to n fipa ba ọmọde lopọ jakejado Naijiria.

Ni ipinlẹ Rivers ẹka to n risi ọrọ ẹtọmọniyan nileeṣẹ ọlọpaa mu arakunrin ẹni ọdun mejlelogoji kan lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdọ ọmọ ọdun mọkanla kan lopọ nipa lagbegbe Eneka ni ijọba ibilẹ Obio-Akpor,ipinlẹ Rivers.

Ni ọjọ Aje ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹwaa ni awọn agbofinro mu baba yi to bi ọmọ mẹta tiẹ lẹyin tawọn araadugbo kan ta awọn agbofinro lolobo.

Iroyin taa gbọ ni pe oṣiṣẹ ileeṣẹ to n pọnpo rọbi ni arakunrin yi ti kii si saba wa nile.

Lawọn igba to ba wa nile ti iyawo rẹ ko si si nile a maa fipa ba ọmọ-ọdọ ton gbe lọdọ wọn lo pọ.

Ọjọ ti akara tu sepo, ọmọ ọdọ naa sa jade nigba to fẹ fipa baa lo p to si lọ fẹjọ ohun ti oju rẹ n ri fawọn alabagbe to wa ni itosi ọdọ wọn.