Àwọn adigunjalè yawọ ilé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ l'Ogun, bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin lòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Tai Solaring University/Facebook
Akẹkọọ obinrin mẹrin ni fasiti Tai Solarin, ijagun, Ijebu Ode ni awọn adigunjale kan yawọ ile wọn, ti wọn si ba wọn lopọ ni agbegbe Abapawa ni ilu naa.
Iroyin to tẹ ileeṣẹ BBC News Yoruba lọwọ sọ pe awọn afurasi adigunjale naa lo fọ ile awọn akẹkọọ lọjọ Isẹgun, ti wọn si tun ji ọpọlọpọ nnkan lọ lẹyin ti fipa ba awọn akẹkọọ naa sun.
Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ fun Ileeṣẹ BBC, Aarẹ fẹgbẹ akẹkọọ ni ile ẹkọ, Akinjenta Emmanuel ni nnkan bi ago mẹta ooru ọjọ Isẹgun ni isẹlẹ naa waye, ti wọn si ni lati gbe awọn akẹkọọbinrin naa lọ si ile iwosan.
O ni yatọ si awọn akẹkọọ obinrin ti awọn adigunjale yii fipa lopọ, ọpọ dukia awọn akẹkọọ mii ni gba lọ ni ooru ti isẹlẹ naa waye.
"Awọn akẹkọ ti wọn fipa ba lopọ n gba itọju lọwọ nile iwosan"
Akinjenta Emmanuel tẹswaju pe “Gẹgẹ bi aṣoju akẹkọọ, nnkan bi ago ooru ni wọn pe mi, mo si sure lọ si bẹ pẹlu awọn ẹsọ alabo ni ile ẹkọ.
Sugbọn a ko ba awọn adigunjale nibẹ mọ amọ wọn ti ba awọn akẹkọọ obinrin mẹrin lopọ, ti wọn si tun gba foonu wọn.
Yatọ si ile ti wọn ti ba awọn akẹkọọ lopọ, awọn adigunjale yii tun ya si awọn ilegbe akẹkọọ miran, ti wọn si tun gba dukia wọn lọ.
Sugbọn ko ba wọn sun nibẹ.
“A gbiyanju lati wa awọn adigunjale yii sita sugbọn a ko ri wọn mu.
Lẹsẹkẹsẹ ni awọn alasẹ ile ẹkọ da si isẹlẹ yii, ti a si ti gbe awọn akẹkọọ naa lọ si ile iwosan, ti wọn si ti n gba itọju bayii.”
"Eyi kọ ni igba akọkọ ti isẹlẹ yii yoo waye, a ti pinnu lati se iwọde ti gomina ko ba da si ọrọ naa"
Adejetan tun jẹ ko di mimọ pe isẹlẹ yii kii ṣe igba akọkọ ti iru rẹ yoo waye ni agbegbe ile ẹkọ Fasiti naa.
Amọ o ni awọn ti pinnu lati ṣe iwọde lori rẹ ti Gomina ko ba da si ọrọ naa.
“O ti n pọju ni agbegbe wa, ki wọn gba foonu, ki wọn ṣe ijamba, fipa ba awọn akẹkọọ lopọ.
A ko si le wa ni awujọ yii, ka tun wa ma la nnkan bayi kọja, ki Gomina ipinlẹ Ogun ma tiẹ sopo yọju si wa.
“Erongba wa ni lati gbegi dana lati fẹhonuhan sugbọn nigba ti Gomina ati igbakeji rẹ wa lana, ti wọn si ṣeleri pe awọn yoo wa nnkan ṣe si, a da ifẹhonuhan naa duro.”
Ki ni ijọba sọ?

Oríṣun àwòrán, Niomot Salako Oyedele
Igbekeji Gomina ipinlẹ Ogun, Noimoy Salako Oyedele ṣabẹwo si awọn akẹkọọ ni ile iwosan, to si fi awọn akẹkọọ loju pe irufẹ isẹlẹ yii ko ni waye mọ
Igbekeji Gomina, ẹni to kọwọrin pẹlu Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abiodun Alamutu, Kọmisana fun eto ẹkọ, Ọjọgbọn Abayomi Arigbabu ati awọn osisẹ ijọba mii ṣe ipade pọ pẹlui awọn akẹkọọ lati gbe igbesẹ lori eto abo to mẹyẹ ni agbegbe ile ẹkọ naa.
“Mo yọju si awọn akẹkọọ Fasiti TASUED ti awọn janduku kan ṣekọlu si, ti wọn si fipa ba wọn lopọ.
“Ijọba ti dasi ọrọ naa, ti wọn si ti pese itọju fun awọn akẹkọọ naa ti yoo mu wọn gbagbe isẹlẹ buruku naa.
“Ijọba n fi da araalu loju pe ki wọn ma foya rara, dukia ati ẹmi wọn ju ijọba loju pupọ ti wọn yoo si ri pe wọn da bobo wọn.”
Ki ni ile ẹkọ sọ?
Akọwe Ile ẹkọ naa, Dapo Oke, ninu atẹjade to gbe sita salaye pe ile ẹkọ ti da eto idanwo ipele keji ti awọn akẹkọọ n ṣe lọwọ nitori isẹlẹ naa.
“Saaju isẹlẹ buruku to waye ni fasiti wa to ni ṣe pẹlu awọn akẹkọọ wa, awọn alasẹ ilẹ ẹkọ fasiti ẹto ẹkọ Tai Solarin, Ijagun nipinlẹ Ogun da eto idanwo to n lọwọ duro.
“Gbogbo osisẹ ati akẹkọọ ni a rọ pe ki ṣe ni oju ni alankan fi n sọri ni agbegbe wọn.”















