N kò fìgbà kankan sọ pé Naira Marley ló pa Mohbad - Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Instagram
Gbajugbaja oṣerebinrin, Iyabo Ojo ti sọrọ sita pe oun ko fi igba kankan sọ pe Azeez Fashola, ti ọpọ mọ si Naira Marley, lo ṣekupa Ilerioluwa Aloba ti ọpọ mọ si Mohbad.
Iyabo Ojo sọrọ yii lasiko to n sọrọ ninu fidio kan to se loju opo ayelujara Instagram rẹ.
Ojo sọrọ lori ibi ti nnkan de duro lori ayẹwo oku Mohbad ti wọn ṣe lọwọ ni ile iwosan General niluu Ikeja.
O ni pupọ awọn eeyan, paapa awọn ololufẹ Naira Marley lo ti bẹrẹ si ni naka si oun pe oun sọ pe Naira Marley lo pa Mohbad, to si jẹ pe ọrọ ko ri bẹẹ rara.
“Ẹ lọ gbọ nnkan ti mo sọ tẹlẹ loju opo mi, n ko fi igba kankan sọ pe Naira Marley lo pa Mohbad.
"Ohun ti mo n beere lọwọ Naira Marley ni pe ki lo se lasiko lasiko ti Sam Larry n duunkoko mọ Mohabad?"
Ninu ọrọ rẹ Iyabo Ojo tẹsiwaju pe “Naira Marley ni mọlẹbi oun ni oloogbe, ti mo si ni pẹlu gbogbo fọnran ti a ri lori ayelujara, a ri pe Sam Larry jẹ ọrẹ timọtimọ rẹ, ti mo si bi pe ki lo ṣe lasiko ti wọn dunkoko mọ oloogbe yii, ki lo ṣe si.
“Ibeere ti mo bi niyẹn, mo tun sọ pe Naira Marley ni lati wa sọ fun wa idi ti ko ṣe ti san owo ajẹmọnu Mohbad, eyi ti awọn mọlẹbi ati eeyan Mohabd ni ko ti i san, ko si ri pe o san awọn owo naa.
“Mo binu si Sam larry pupọ nitori fọnran ti gbogbo wa ri lori ayelujara nibi to ti lọ ṣe ikọlu si Oloogbe, ti kii ṣe ẹẹkan tabi ẹẹmeji.”
“Mo tun sọrọ sipe pe ki NDLEA wa sọrọ lori ẹsun ti Mohbad fi kan, pe wọn fun oun ni kan mu, ti wọn si sọrọ lori rẹ.”
"Mo pariwo sita nitori mo fẹ idajọ odoodo fun Mohbad"
Ojo jẹ ko di mimọ pe oun ko wa sori ayelujara lati wa ma pariwo lasan sugbọn nitori oun fẹ idajọ odoodo lori ohun to waye nipa iku Mohbad ni.
O ni oun sisẹ pọ pẹlu ajọ ati ileeṣẹ to n wa idajọ odoodo.
“Naira Marley ati Sam Larry wa ni ahamọ Ọlọpaa, ti wọn si ti fohun silẹ lori nnkan ti wọn mọ, to ba di lọla, ti wọn ba ni wọn lẹjọ lati jẹ, ko si nnkan to buru.
“Nnkan ti mo ṣe ni pe, mo pariwo pe ki wọn gba wa, ti Ọlọpaa si da si ọrọ naa lati mojuto iwadi lori ohun to sokunfa iku Mohbad.”
Iyabo Ojo wa jẹ ko di mimọ pe ayẹwo oku Mohbad ko ni pẹ jade, ti yoo si han si gbogbo araaye.
Naira Marley dúnkokò láti wọ́ òṣèrébìnrin méjì àti K-Solo lọ ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ibanilórúkọjẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram
Awọn ikọ agbẹjọro gbajugbaja olorin takasufe, Azeez Fashola, ti ọpọ eeyan mọ si Naira Marley ti n dunkoko lati wọ gbajugbaja agbeorin larugẹ, Solomon Oyeniyi, ti ọpọ mọ si K-Solo ati awọn oṣerebinrin meji lọ ileẹjọ fun ẹsun ibanilorukọ jẹ.
Saaju ni K-Solo, ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Channels TV, fẹsun kan Naira Marley pe o lọwọ ninu iku ọkan lara ọmọ lẹyin rẹ to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ mọ si Mohbad, ẹni to jade laye lọjọ Kejila oṣu kẹsan an ọdun 2023 ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn.
O ni, “Naira Marley mọ nipa iku rẹ. Ko le sọ fun mi oun pe oun ko mọ nipa rẹ. O lọwọ ninu iku Mohbad.
“Eeyan ko le wa labẹ ileeṣẹ rẹ, ki awọn eeyan kan ma dunkoko mọ, ti o si kọ lati jade sọrọ.
O wa ni o mọ nkankan nipa iku rẹ.
“O wa n fi atẹjade sita?, Ko si ẹni ti ko le fi atẹjade sita . Naira Marley mọ nipa isẹlẹ yii. Ko le sọ fun mi pe rara.
“Ẹ jẹ ko bọ sita, ko wa fọ ara rẹ mọ, ko si ni, Emi, Naira Marley, n ko mọ ohun ko ohun nipa rẹ, lẹyin iyẹn ki ọlọpaa bẹrẹ iwadi wọn.”
"K-Solo ati awọn oṣerebinrin meji tabuku Naira Marley lori ẹsun ti ko lẹsẹ nlẹ"
Nigba to n fesi si ẹsun naa, ikọ agbẹjọro Naira Marley ninu atẹjade ti wọn fi lede, ni akọle rẹ jẹ ‘A gbe K-Solo lọ Ileẹjọ lori ẹsun ibanilorukọ to ṣe si Naira Marley”.
Agbẹnusọ fun olori ileeṣẹ orin Marlian, Olamide Akinrimade si lo buwọlu atẹjade naa.
Atẹjade naa ni; “Ikọ agbẹjọro to n soju Naira Marley yoo bẹrẹ igbesẹ lati wọ K-Solo lọ si ileẹjọ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ.
Eyi lo ṣe koko lati ṣe lori irọ nla ati ọrọ odi to sọ sita eyi to ti fa ọpọlọpọ rogbodiyan.
“Ẹsun ti wọn fi kan onibara wa kii n ṣe pe o ba lorukọ jẹ nikan sugbọn awọn ẹsun ti ko lẹsẹ nlẹ yii lo ti tan kaakiri.
K-Solo ati awọn yooku rẹ, paapa awọn oṣerebinrin meji kan, ti wọn jẹ ọga lori pinpin iroyin ofege, tabuku Naira Marley fun idi kan to jẹ pe awọn nikan lo ye.

Oríṣun àwòrán, nmlegalteam/Instagram
"Nitori apọnle ti a ni fun oloogbe Mohbad, ni a fi dakẹ tẹlẹ"
Ikọ naa wa jẹ ko di mimọ pe nitori apọnle ti awọn ni fun oloogbe, eyiun Mohbad, lo jẹ ki awọn dakẹ tẹlẹ.
Sugbọn wọn ni nibayii, awọn ko ni fi aye gba ẹnikẹni lati tabuku si orukọ Naira Marley.
“A ti dakẹ lati ijọ yii nitori a fẹ bọwọ fun oku ọrun ati ibaṣepọ rẹ pẹlu wa sugbọn a ri pe ọpọ eeyan lo ti mu gẹgẹ bi isẹ lati ma gbe iroyin ofege kiri lori Naira Marley.
A ko ni dakẹ mọ, ka ma woran, ki wọn gbe ẹru ti ki ṣe tiẹ le lori.”
Ikọ agbẹjọro naa tun jẹ ko di mimọ pe, ẹnikẹni to ba fẹsun kan Naira Marley lori iku Mohbad gbọdọ ṣetan lati fi ẹri silẹ lori ayelujara ati ileẹjọ.
“Naira Marley ti jẹ ko di mimọ pe oun ko lọwọ ninu iku Mohbad, to si ti wọgile gbogbo ẹsun K-Solo fikan.
A ma fun K-solo ni anfani lati fi ẹri silẹ lori ẹsun to fi kan Naira Marley ,”
















