Wòlíì Adegoke ní kí Chef Dammy san N20m lórí ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́

Oríṣun àwòrán, X/Chef Dammy
Aawọ to n waye laarin gbajumọ alase nni, Damilola Adeparusi ti ọpọ eeyan mọ si Chef Dammy ati Pasitọ ijọ kan, Wolii Jeremiah Adegoke, ti n ba ọna miran yọ.
Bẹẹ ba gbagbe, ọpọ awuyewuye lo ti n waye laarin awọn mejeeji lẹyin ti Chef Dammy kopa ninu idije ounjẹ sise fun ọpọ wakati.
Olusọagutan ijọ Spirit World Global Missioon, Wolii Jeremiah Adegoke si lo se agbatẹru idije ounjẹ sise naa fun Chef Dammy.
Amọ se ni ariwo sọ lẹyin osu diẹ ti idije naa waye, nigba ti Dammy kede loju opo ayelujara rẹ pe ti ohunkohun ba se oun, wolii Adegoke ni ki aye mu.
Ọjọ Kọkandinlogun osu kẹwa ọdun 2023 ni Chef Dammy kede pe Wolii Adegoke n dunkooko mọ ẹmi oun
Ikede naa si ni Dammy kede lọjọbọ ọjọ Kọkandinlogun osu kẹwa ọdun 2023.
O fikun pe wolii naa ti ni ki oun dira fun ogun lati ja, ti awọn mejeeji si ti tẹsẹ bọ sokoto kannaa,
Bi o tilẹ jẹ pe Dammy kede lati se ipade akọroyin, ki oun si tu asiri ohun to fa aawọ laarin awọn amọ ko pada pe ipade awọn oniroyin naa mọ.
Se ni ẹnu si n ya ọpọlọpọ eeyan pe ki lo lee waye, to fa aawọ laarin awọn mejeeji?
Chef Dammy, san ogun miliọnu Naira fun mi laarin ọjọ meje tabi ka pade nile ẹjọ - Wolii Adegoke
Ni owurọ ọjọru ni ariwo sọ lori ayelujara pe Wolii Adegoke ti n beere ogun miliọnu Naira lọwọ Chef Dammy lori ẹsun ibanilorukọjẹ.
Iwe naa, ti agbẹjọro wolii naa, Amofin Busayo Sule fọwọsi lo n salaye pe awọn ohun ti ọmọdebinrin naa kọ soju opo ayelujara rẹ ko dara to.
Iwe agbẹjọro naa ni ikede Chef Dammy lori ayelujara ọhun ba orukọ wolii naa, tii se onibara oun jẹ.
Agbẹjọro Sule wa n beere pe ki Dammy gbe awọn igbesẹ wọnyi ti ko ba fẹ foju bale ẹjọ fun ẹsun ibanilorukọjẹ.
Wolii Adegoke sọ awọn ohun ti Chef Dammy gbọdọ se ti ko ba fẹ foju bale ajọ
Akọkọ, Chef Dammy gbọdọ pahunda lori awọn ‘ọrọ ibanilorukọjẹ’ to kọ soju opo ayelujara rẹ nipa Wolii Jeremiah Adegoke, ko si ni oun ko sọ bẹẹ mọ.
Bakan naa lo si gbọdọ pa ikede naa rẹ lori awn oju opo ayelujara rẹ.
Ekeji, Dammy tun gbọdọ kede igbesẹ sisẹ awọn ọrọ to sọ naa ninu iwe iroyin ojoojumọ meji to gbajugbaja julọ nilẹ wa, eyi ti ọpọ eeyan maa n ka julọ.
Ikẹta ni pe Dammy yoo say milinu lọna ogun miliọnu Naira fun Wolii Adegoke gẹgẹ bii owo gba ma binu nitori ikede ibanilorukọjẹ naa.
Ikẹrin ni pe o fun Dammy lọjọ meje lati dahun sawọn ohun to n beere yii, ko si ṣe ohun totọ ati iyi to yẹ, to ba si kọ lati ṣe bẹẹ, ko pade ni ileẹjọ.

Oríṣun àwòrán, X
Ki ni Chef Dammy sọ nipa ibeere Wolii Adegoke naa?
BBC Yoruba wa kan si Agbẹjọro Chef Dammy, (ẹni ti a ko ni darukọ sita), o salaye pe awọn naa ti ṣetan lati pade awọn olupẹjọ ni ileẹjọ lori ẹsun ibanilorukọ jẹ.
Agbẹjọro naa salaye pe olupẹjọ n dunkoko mọ Chef Dammy ni, ti igbesẹ yii si jẹ iwa ọdaran labẹ ofin.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe owo ti wọn beere lọwọ Chef Dammy lo jẹ ọrọ lẹnu lasan, ti mimi kan ko si mi wọn lati pade ni ileẹjọ lọsẹ to n bọ.
“Idunkoko ti wọn fun Chef Dammy ti pọju, wọn dẹru ba, wọn ko fẹ sọrọ, eyi lo si jẹ iwa ọdaran labẹ ofin.
“A yoo pade ni ile ẹjọ lọsẹ to n bọ.”















