Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkọ tó fi ọ̀bẹ gún ìyàwó rẹ̀ pa

Oríṣun àwòrán, Other
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue ti fidi rẹ mulẹ pe ọkunrin kan to fi ọbẹ gun iyawo rẹ pa ti wa ni gbaga ọlọpaa bayii.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue, Anene Catherine sọ fun BBC Yoruba pe ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ Bem Matthew to n gbe ni ilu Korinya ni ijọba ibilẹ Konshisha lori ẹsun pe o ṣekupa iyawo rẹ.
Laarọ ọjọ Isẹgun ni a gbọ pe iṣẹlẹ ọhun eleyii to mú kí awọn pejọ sí ile ọkunrin yii.
Ni kiakia naa ni awọn ara adugbo mu ọkunrin yii ti wọn sí fa a le awọn agbofinro lọwọ.
Awọn ọlọpaa ẹkun Konshisha naa lo mu Ọgbẹni Matthew lọ ti wọn sí gbe oku arabinrin naa lọ si mosuari.
Enikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe ṣe ni ọkunrin naa fi ọbẹ gun iyawo rẹ ni aya, ni itan ati ni ẹyin.
Iroyin tun fidii rẹ mulẹ pe ọmọ mẹrin ni obinrin naa bi fun ọkunrin yii.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni "otitọ ni pe ọkunrin naa gun iyawo rẹ pa.
Amọ, ko tii sọ idi ti o fi ṣekupa obinrin naa titi di bi mo ṣe n sọrọ lọwọ yii.
O ti gba pe lootọọ ni oun pa obinrin naa, ṣugbọn o gbọdọ sọ fún wa idi ti o fi pa a."















