Gaza àtàwọn èèyàn ibẹ̀ ti di ilé àti ẹbí wa, à kò le fi wọ́n sílẹ̀ - Àwọn 'Sista' láti gúùsu Amẹ́ríkà

Awọn Sista n ba awọn eeyan kẹdun

Oríṣun àwòrán, AP

Àkọlé àwòrán, María del Perpetuo Socorro (L) ati María del Pilar Llerena Vargas, ti wọn jẹ ibeji, n ba awọn mọlẹbi to lugbadi ikọlu Israeli kẹdun ni Ile ijọsin Saint Porphyrius Orthodox lọjọ Kọkandilogun, oṣu kẹwaa
    • Author, Alejandra Martins
    • Role, BBC World Service

Awọn Sista meji, Peruvian María del Pilar ati María del Perpetuo Socorro Llerena Vargas, ni awọn n jẹ ajirinrere ni Ilẹ ijọsin Holy Family niluu ilu Gaza City, to si Ile ijọsin aguda kan to wa ni ilẹ Palestine.

Awọn Sista yii ti wọn jẹ ibeji lo jẹ ajirirere ile ẹkọ 'Institute of the Incarnate Word (IVE)', pẹlu awọn Sista miiran lati ile ijọsin mii ni wọn n ṣe iranlọwọ fun eeyan Gaza to le ni ẹgbẹta, pẹlu awọn akanda ẹde ọmọde, aliarẹ ati awọn agbalagba

Lẹyin wakati ti ikọlu Hamas si Israel waye lọjọ keje oṣu kẹwa, eyi ti eeyan to le ni ẹgbẹrun kan ti padanu ẹmi wọn, ti eeyan to le ni igba eeyan to wa ni ahamọ ajinigbe, Israel fesi pada pẹlu ado oloro si ilu Gaza.

Ikọlu yii ti sọ ẹgbẹrun marun un eeyan di ẹni ilẹ, pẹlu awọn ọmọde to le ni ẹgbẹrun meji ni Gaza, gẹgẹ bii Ileeṣẹ eto Ilera Gaza ṣe kede, eyi ti Hamas n ṣe adari rẹ.

Aworan Sista María del Perpetuo Socorro (L) ati María del Pilar Llerena Vargas

Oríṣun àwòrán, Familia Religiosa IVE

Àkọlé àwòrán, Aworan María del Perpetuo Socorro (L) ati María del Pilar Llerena Vargas, ni ile ijọsin Aguda kan soso to wa ni Gaza.

Olori ajọ aṣoju orilẹede Peru ni ilẹ Egypt, Giancarlo Pedraza Ruiz, fidi rẹ mu fun BBC pe ileeṣẹ ti ṣe igbiyanju lati ku eeyan rẹ kuro ni Gaza lọ si Egypt.

Pedraza Ruiz fihan pe eeyan mẹrin ọmọ Peru pẹlu ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹfa ati awọn mọlẹbi wọn ni awọn jade kuro ni Gaza sugbọn Sista meji kan yari pe awọn ko ni kuro Gaza .

Sista wa fidi rẹ mulẹ pe o ti tọ ni pe Ileeṣẹ to ṣe asoju ijọba pe wa pe gbogbo nnkna ti wa nilẹ fun wa lati kuro niluu Gaza sugbọn wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ko ni erongba lati kuro niluu Gaza.

"A ko ni fi awọn eeyan wa si lẹ. O ti pe ọdun mẹrin ti mo ti n gbe ni ibi bayii, igbesi aye mi ree. Awọnb eeyan mi ree, ti nko si ni kuro nitoti wọn nilo iranlọwọ wa."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Sista tẹsiwaju pe oun mọ aburu to wa ni diduro ni Gaza, ti oun si gbọ gbogbo ado oloro to n bu gbamu ni gbogbo awọn eeyan mọ sugbọn awọn ko fẹ fi awọn eeyan silẹ.

Eyi ni Sista María del Pilar ni lati sọ fun BBC.

Sister María del Pilar, ẹ ni Ile ijọsin ko ni omi tabi ina mọnamọna. Ipo wo nnkan wa bayii.

A ni to eeyan to le ni ẹgbẹta nibi bayii. Bi awọn ilu yooku, a ko ni omi. Sugbọn a si ni omi to n san, eyi ti a fi ṣe igbọnsẹ ati fifọ nnkan... a ko mọ bi eyi ṣe ma pẹ to fun wa. Ati pe a ti ra omi fun awọn eeyan lati mu, ni ipọpo iye ti a n ra tẹlẹ.

O ni pe o wa nibi eto isinku eeyan mẹrinlogun to ku lasiko ti ado oloro bu gbamu ni Ile ẹjọ Orthodox ti Saint Porphyrius.

Israel ni awọn ko ṣekọlu si ile ijọsin, minisita fun eto oke okun, Lior Hayat sọ fun BBC nnkan to waye ni pe wọn ṣekọlu si dukia Hamas to wa ni ẹgbẹ Hamas.

Njẹ o le salaye ohun to waye ?

Awọn eeyan yii ku nitori ado oloro Israel; ọkan lara yara ni bi ti wọn sun si dawo. Pẹlu eyi, ọpọ ọmọ Kristẹni lo ku, gbogbo awọn ọmọde to wa si ile ijọsin wa lati kẹkọ lo ba isẹlẹ naa lọ.

Igba akọkọ ree ti ma jade sita lati ijọ ti isẹlẹ yii ti bẹrẹ lati ko awọn mọlẹbi Kristi lọ sibi eto isinku awọn eeyan wa, lati ma wọn kẹdun diẹ nitori asiko yii jẹ asiko ti nnkan le fun wọn.

Ni bo ni wọn si awọn eeyan yii si?

Ile ijọsin kọọkan ni itẹ oku tirẹ.

O sọ pe lasiko eto isinku naa, o ri awọn aworan kan ti ko le kuro lọkan rẹ laye

Bẹẹni, o ṣe ni laanu pe o ti tọ ni.

Ti eeyan ba lọ si eto isinku, eeyan yoo ri ọmọ to n dagbere fun Baba pe odabo. Inira to wa nibi ti obi ma sunkun ọmọ jẹ ohun to bani ni inu jẹ.

Awọn mọlẹbi ti awọn ọmọ ku ree. Ati pe o jẹ awọn ọmọ ti awa naa mọ. O duni gan

People inside the Holy Family Church in Gaza

Oríṣun àwòrán, Familia Religiosa IVE

Àkọlé àwòrán, Hundreds of people have taken refuge in the Holy Family Church in Gaza

N jẹ se ẹ ni ounjẹ? Nitori ohun iranwọ ounjẹ lo raye wọle si agbegbe yii?

o you have food? Because only a few trucks with aid have been allowed to enter.

Adupẹ lọwọ Ọlọrun, Ajọ Latin Patriarchate n pese iranlọwọ fun wa ati awọn eeyan naa.

Awọn ile ijọsin meji, Latin ati Orthodox n sisẹ papọ, eyi lo jẹ ibukun lati ọdọ Ọlọruni. A n ra ounjẹ, ra ibusun. O wọn sugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe a ni ounjẹ

The sisters María del Pilar (left) y María del Perpetuo Socorro

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, The sisters María del Pilar (left) and María del Perpetuo Socorro at a religious service in the Catholic church in December 2022