Làásìgbò bá MAPOLY, olùkọ̀ọ́ yanṣẹ́lódì torí owó oṣù mẹrin tó há, akẹ́kọ̀ọ́ ń yarí lórí àfikún owó ẹ̀kọ́
Ki saba wọpọ ki awọn olukọ atawọn akẹkọọ maa kọju oro sile ẹkọ kan lasiko kan naa.
Amọ eyi ko ri bẹẹ pẹlu ile ẹkọ Gbogbonse Polytechnic ti Moshood Abiola (MAPOLY) to wa nilu Abeokuta, nipinlẹ Ogun.
Idi ni pe lati bii ọsẹ diẹ sẹyin ni wọn ti sọ agadagodo sẹnu ọna ile ẹkọ naa nitori bawọn akẹkọ se fọnmu lori ele to gun owo ẹkọ wọn.
Ko si pẹ lẹyin eyi naa tawọn olukọ naa gunle iyansẹlodi tori bi ile ẹ kọ naa se jẹ wọn ni owo osu mẹrin lai san.
Bawọn akẹkọ se n fa ile ẹkọ giga naa lọtun lori ele to gun owo ẹkọ wọn, ti wọn si n beere fun ẹdinwo, pẹlu afikun pe laisi igbesẹ naa, ko le si alaafia.
Bakan naa lawọn olukọ ni ni tawọn ko ba ri owo osu atawọn ajẹmọnu awn gba, omi alaafia ko le toro lọgba ile ẹkọ naa.
Ọrọ ile ẹkọ MAPOLY yii wa di kaka ki ewe agbọn dẹ, ko ko ko lo n le si.
Eyi lo mu ki BBC Yoruba gba ile ẹkọ naa lọ, lẹyin ti ọgọ n gori ọjọ, ti awọn aawọ yii ko lojutu, tile ẹkọ naa si wa ni titipa.
A fẹ mọ ibi ti ọrọ naa de duro ati igbesẹ tawọn alasẹ ile ẹk naa ati ijọba n gbe lati fi eegun Otolo to ọrọ yii, ki eto ẹkọ le bẹrẹ pada nile ẹk MAPOLY.

Ileẹkọ MAPOLY gbe owo igbaniwọle wa lati N35,500 si N50.500, a ko ni gba - Ẹgbẹ akẹkọọ
Nigba to n ba BBC Yoruba, aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ nile ẹkọ MAPOLY sọ pe koko ohun ti awọn akẹkọ ile ẹkọ naa n ja fun ni pe ele se ba owo tile ẹkọ naa n gba lọwọ awọn akẹkọọ.
O ni owo ‘Mo fara mọ’ lati jẹ akẹkọ ile ẹkọ yii, eyiun Acceptance Fee to jẹ N35,500 tẹlẹ ni ile ẹkọ naa ti gbe lọ soke si N50,500 bayii.
Eyi si lo mu ki ẹgbẹ akẹkọ ile ẹkọ MAPOLY fi faake kọri, ta si se iwọde eyi to mu kawọn alasẹ ti ile ẹkọ wa.
“ Nigba ta ba wọn se ipade, wọn sọ fun wa pe owo acceptance fee tile ẹkọ naa n gba lo kere julọ, pe a le lọ beere lawọn ile ẹkọ yoku.
Nigba ta si lọ kaakiri, a ri pe irọ ni wọn n pa nitori owo tile ẹkọ wa lo lọ soke ju tawọn ile ẹkọ yoku l.
A si ti sọ fun wọn pe wọn gbọdọ dinku bi bẹẹ kọ, a ko ni gba.”
Bakan naa, aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ fikun pe lati ọdun 2018, awọn ko se ayẹyẹ ikẹkọjade, nigba tawọn si bi awọn alasẹ, wọn ni ko si owo lati fi se ni.”

Ileẹkọ MAPOLY jẹ wa lowo osu mẹrin, a ko ni owo mọ lati maa wa sibi isẹ la se pinnu lati joko sile wa – Ẹgbẹ Olukọ
Nigba tawọn naa n ba BBC Yoruba sọrọ, olukọ kan nile ẹkọ MAPOLY salaye pe ile ẹkọ naa jẹ awọn ni owo osu mẹran lo mu ki awọn maa wosẹ niran.
O ni nnkan ko dẹrun fun awọn olukọ ile ẹkọ naa lasiko yii tori airi owo osu gba, ti ko si si owo lọwọ awọn lati maa wọ ọkọ wa sibi isẹ.
O fikun pe “Ile ẹkọ naa n yọ owo ifẹyinti ti a n da ninu owo osu wa, amọ MAPOLY ko san owo naa fun ajọ olowo ifẹyinti to yẹ lati ọdun marun sẹyin.
Eyi tumọ si pe gbogbo awn to ti fẹyin ti lati ọdun marun sẹyin ati awn to n mura lati fẹyinti, ko si ọjọ ọla to dara fun wọn.
Eyi buru jai, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ, ti a si tẹsiwaju lati maa wo isẹ niran titi ti awọn alasẹ yoo fi wa nnkan se si ọrọ wa.”

Owo ti a n pa nile ẹkọ MAPOLY la fi n sanwo osu awọn osisẹ, owo kekere ni ijọba Ogun n fun wa – Agbẹnusọ MAPOLY
BBC Yoruba tun kan si ọdọ alasẹ ile ẹkọ MAPOLY lati mọ ohun to faa, ti awọn wahala yii se fọnna soju.
Nigba to n ba wa sọrọ, osisẹ alarena fun ile ẹkọ gbogbonse MAPOLY, ọgbẹni Yemi Ajibola sọrọ, ilẹ kun nipa awn isoro tile ẹkọ naa n la kọja.
“Epo Disu la n lo fi tan ina lati ipasẹ ẹrọ amunawa wa, nitori ko si ina ọba rara.
Owo ti ile ẹkọ naa n pa wọle la fi n sanwo osu osisẹ, gbọ awn bukata pẹ pẹ pẹ mii.
Owo tijọba n fun ile ẹkọ naa ko to nnkan rara nitori bii ile ẹkọ adani nile ẹkọ yii jẹ, owo ti a ba pa, la n na.
Idi ree tile ẹkọ naa se gbọdọ fi owo kun owo ile ẹkọ tawọn akẹkọ n san, nitori owo ti wọn n san lọwọ lọwọ bayii, ko le se nkankan.”

Ijọba Ogun ti gbiyanju lati da si aawọ MAPOLY ni ẹẹmẹrin ọtọọtọ - Kọmisana feto ẹkọ
BBC Yoruba tun morile ọdọ ijọba Ogun lati mọ ohun to n se lati yanju aawn to n fa aago ilsiwaju ati eto ẹkọ nile ẹkọ MAPOLY sẹyin.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Kọmisana feto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Abayomi Arigbabu ni kii se pe ijọba kaw gbera lori isẹlẹ yii nitori awọn ti gbe igbesẹ lati yanju rẹ.
“Ẹmẹrin ọtọọtọ la ti yanju aawọ ile ẹkọ MAPOLY, paapaa lori afikun owo ile ẹkọ naa.
A si ti fun awọn alasẹ ile ẹkọ naa lati wa ojutu si awn wahala to n koju ile ẹkọ naa.






