Wo kókó mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara

Omobinrin to n gba abere ajesara

Oríṣun àwòrán, UNICEF NIGERIA/X

Iléeṣẹ́ ètò ìlera Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti gbógun ti àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara lójúnà àti dènà bí obìnrin tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ṣe máa ń kú ní ọdọọdún.

Jẹjẹrẹ ojú ara jẹ́ ọ̀kan lára àwọn jẹjẹrẹ mẹ́ta - jẹjẹrẹ ọyàn, jẹjẹrẹ ilé ìtọ̀ - tó máa ń ṣokùnfà ikú àwọn obìnrin jùlọ ní Nàìjíríà.

Adarí àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdé ní àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ìyẹn United Nations Children's Fund, UNICEF ní Nàìjíríà, Dókítà Rownak Khan ní bí àìsàn náà ṣe lágbára tó, ó ṣeéṣe láti mú àdínkù ba pẹ̀lú ìdá àádọ́rùn-ún tí àwọn ọmọdébìnrin bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára tó yẹ láti dènà rẹ̀.

Àjọ ètò ìlera àgbáyé, World Health Organization, WHO ní ìrètí àwọn aláṣẹ ni láti dá ààbò bo mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún ọmọbìnrin Nàìjíríà lọ́wọ́ àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2025.

Ọjọ́ márùn-ún, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun tí wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára náà, ni wọ́n fi máa fún àwọn ọmọbìnrin ní abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí ní àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún àti olú orílẹ̀ èdè yìí, Abuja.

Àwọn nǹkan mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara nìyí;

Jẹjẹrẹ ojú ara

Lára ẹ̀yà ojú ara tó ń jẹ́ cervix, ojú ọ̀nà láti wọ ibi tí ẹyin máa ń wà ni jẹjẹrẹ yìí máa ń mú tí yóò sì máa dàgbà síbẹ̀.

Ìdá mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara ló máa ń wáyé lára kòkòrò àìfojúrí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ human papillomaviruses (HPV), èyí tí ó wọ́pọ̀, tí èèyàn sì máa ń kó látara ìbálòpọ̀.

Kòkòrò àìfojúrí yìí máa ń lọ fúnra rẹ̀ àmọ́ tí ènìyàn bá ń ko ní gbogbo ìgbà ó lè fa àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara.

Jẹjẹrẹ ojú ara ni jẹjẹrẹ kẹrin tó wọ́pọ̀ jùlọ nínú àwọn jẹjẹrẹ tó máa ń mú àwọn obìnrin.

Ní ọdún 2018, bíi obìnrin 570,000 ló ní àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara káàkiri àgbáyé tí àwọn 311, 000 sì bá a lọ ní ọdún náà.

Kí ni ipa jẹjẹrẹ ojú ara?

Àìsàn tó lágbára tó lè ṣekúpa ènìyàn ni àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara.

Mínísítà fún ètò ìlera Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Muhammad Ali Pate ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àwọn obìnrin ló máa ń pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àìsàn yìí ní Nàìjíríà ní ọdọọdún.

Pate ní nínú àwọn ẹgbẹ̀rún méjìlá obìnrin tó máa ń pàdánù ẹ̀mí wọn ní Nàìjíríà ní ọdọọdún ni ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ máa ń wáyé látara àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara èyí tó ní ó ṣe é dènà àti pé òpin gbọ́dọ̀ bá àkọ́ọ́lẹ̀ yìí.

Adarí iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára kan ní Nàìjíríà ìyẹn Gavi International Vaccines Center in Nigeria, Thabani Maphosa ní àdánù ńlá ni jẹjẹrẹ ojú ara ń kó bá ní gbogbo ìgbà.

Pate ní àwọn òbí lè dá ààbò bo àwọn ọmọ wọn nípa gbígba abẹ́rẹ́ yìí fún àwọn ọmọbìnrin wọn láti dènà àìsàn náà fún wọn.

Abẹ́rẹ́ àjẹsára HPV

Eto ifilole abere ajesara HPV

Oríṣun àwòrán, Ali Pate/X

Àjọ WHO ní abẹ́rẹ́ àjẹsára HPV mẹ́fà ni àwọn ti buwọ́lu káàkiri àgbáyé báyìí.

WHO ní gbogbo rẹ̀ ló wà fún àti dá ààbò bo àwọn kòkòrò àìfojúrí kẹrìndínlógún àti kejìdínlógún tó jẹ́ pé àpapọ̀ rẹ̀ ló máa ń fa àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara káàkiri àgbáyé.

Wọ́n ní gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí yóò dènà títan àìsàn náà kalẹ̀ àti àyẹ̀wò rẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé abẹ́rẹ́ àjẹsára HPV kò ní ìpalára kankan.

Àwọn ìpínlẹ̀ wo ló máa kọ́kọ́ jẹ àǹfàní abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí?

Àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún ni yóò kọ́kọ́ ní àǹfàní láti gba abẹ́rẹ́ yìí.

Àwọn náà ni Abia, Adamawa, Akwa Ibom, Enugu, Lagos, Osun, Bauchi, Bayelsa, Benue, Jigawa, Nasarawa, Kano, Kebbi, Ogun, Taraba àti Abuja.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹrìnlélógún sí ọjọ́ Àìkú ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni ètò gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára náà máa fi wáyé.

Ní oṣù Karùn-ún ọdún 2025 ni ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ máa wáyé ní àwọn ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún yòókù.

Ìdàgbàsókè abẹ́rẹ́ àjẹsára HPV

Mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún abẹ́rẹ́ àjẹsára dènà jẹjẹrẹ ojú ara tí àjọ Unicef gbé kalẹ̀ fún Nàìjíríà jẹ́ ojúná láti dá ààbò bo àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́rin káàkiri àgbáyé lọ́wọ́ jẹjẹrẹ ojú ara.

Nàìjíríà, Bangladesh, Cambodia, Eswatini, Kiribati, Mongolia àti Togo ti ní àwọn yóò fi abẹ́rẹ́ àjẹsára HPV kún abẹ́rẹ́ àjẹsára tí wọn yóò máa fún àwọn ọmọdé.

Unicef ní àwọn obìnrin tó lé ní 600,000 ló ní àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara lọ́dún 2020 tí àwọn 340,000 sì pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àìsàn náà.

Àjọ náà ní àwọn orílẹ̀ èdè tí kò tíì gòkè àgbà ni àìsàn yìí ti máa ń wáyé jùlọ nítorí kò sí ètò ìlera tó péye láti tọ́jú rẹ̀.

WHO ń gbìyànjú láti gbé àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn obìnrin tó tó ìdá ọgọ́ta ti ní àìsàn yìí látàrí pé wọn kò gba abẹ́rẹ́ àjẹsára rẹ̀ rí.

Unicef ní orílẹ̀ èdè ogún ni àwọn ń gbèrò láti pín abẹ́rẹ́ àjẹsára náà sí láàárín ọdún méjì.

Àwọn wo ló yẹ kó gba abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí?

Ìrètí wà pé Nàìjíríà yóò fún àwọn ọmọbìnrin tó lé ní mílíọ̀nù méje àbọ̀ ní abẹ́rẹ́ àjẹsára HPV.

WHO ní iye ló pọ̀ jùlọ tí yóò gba abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí láàárín ọdún kan ní ẹkùn Adúláwọ̀.

Lẹ́yìn tí wọ́n bá gbé abẹ́rẹ́ àjẹsára lọ sí ojúlé sí ojúlé fún ọjọ́ márùn-ún yìí, wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí ní fi sára abẹ́rẹ́ àjẹsára tí àwọn ọmọ yóò máa gbà lẹ́yìn tí wọ́n bá ti bí wọn tán.

Ọmọ ọdún mélòó ló lè gba abẹ́rẹ́ yìí?

Àwọn ọmọbìnrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́sàn-án sí ọdún mẹ́rìnlá ni wọ́n máa kọ́kọ́ fún níbi ipele àkọ́kọ́.

Mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún àwọn ọmọbìnrin ni ìrètí wà pé yóò ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí ní Nàìjíríà láàárín ọdún méjì.

WHO ní iye abẹ́rẹ́ àjẹsára tí ọmọ kọ̀ọ̀kan yóò gbà dá lórí iye ọjọ́ orí rẹ̀.

Ìjọba Nàìjíríà ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan ni wọ́n máa fún àwọn ọmọbìnrin lásìkò yìí àti pé ẹyọ̀kan náà yóò ṣe iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ kó ṣe.

A máa ṣe àtìlẹyìn fún abẹ́rẹ́ àjẹsára náà - Sultan Sokoto

Lára àwọn tó kópa níbi ìfilọ́lẹ̀ abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ni Sultan ti Sokoto, Alhaji Sa'ad Abubakar Kẹta tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ àtìlẹyìn tó péye fún ètò náà.

Ó ní pẹ̀lú àtìlẹyìn àwọn ìjọba ní gbogbo ẹ̀ka, wọn yóò rí àwọn ọmọbìnrin fún ní abẹ́rẹ́ náà bó ṣe tọ́.

Mínísítà fún ẹ̀tọ́ ìlera Nàìjíríà náà ní òun yóò ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin òun ló gba abẹ́rẹ́ náà.

Ọ̀fẹ́ ni abẹ́rẹ́ àjẹsára HPV

Iléeṣẹ́ ètò ìlera Nàìjíríà yóò máa pèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára yìí lọ́fẹ̀ẹ́ gbọwọ́ àjọ tó ń rí sí ètò ìlera alábọ́dé.

Gavi, Vaccine Alliance, Unicef, WHO àtàwọn míì ló ṣe àtìlẹyìn ètò yìí fún Nàìjíríà.

WHO ní àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n ni àwọn ti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ní Nàìjíríà lórí abẹ́rẹ́ àjẹsára náà.

Wọ́n ní láti ri dájú pé ọmọbìnrin kankan kò yọ sílẹ̀, àwọn ti pèsè bí wọn ṣe máa gbé àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára náà lọ sí ẹsẹ̀ kúkù.

HPV dára fún àwọn ènìyàn láti gbà

Mínísítà fún ètò ìlera Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Muhammad Ali Pate ní abẹ́rẹ́ àjẹsára HPV dára fún àwọn ènìyàn láti gbà àti pé wọ́n ti fún ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin ní àgbáyé kí wọ́n tó gbe wá sí Nàìjíríà.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé abẹ́rẹ́ àjẹsára náà kìí ṣe dandan, ó rọ àwọn òbí láti jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn gba abẹ́rẹ́ náà.

Àwọn obìnrin tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ló lè kó àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara.

Àwọn obìnrin tó wà láàárín ọjọ́ orí ọdún mẹ́ẹ̀dógún sí mẹ́rìnlélógójì ló lè ní àìsàn náà jùlọ.