Ariwo sọ nílé ẹkọ́ ọ̀gbìn n‘Ibadan báwọn òṣìṣẹ́ EFCC ṣe ń yìnbọn lásìkò tó wá afurasí ọmọ Yahoo wọnú ọgbà iléẹ̀kọ́

Aworan bi awọn akẹkọọ ṣe n fẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Edonehappen

Ariwo sọ lọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹrindinlogun oṣu kẹwaa nigba ti iroyin jade pe awọn osisẹ EFCC dero ahamọ awọn akẹkọọ Federal College of Forestry, Jericho niluu Ibadan.

Iroyin to jade salaye pe awọn osisẹ EFCC na sabẹwo si ọgba Ile ẹkọ naa lati sawari awọn afurasi onijibiti ayelujara ti wiwa wọn si da ọpọlọpọ rogbodiyan silẹ ni Ile ẹkọ naa.

Awọn osisẹ naa ni awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa ti mọle ile kan, ti awọn akẹkọọ si kora wọn jọ lati fẹhonuhan lori ikọlu naa.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ EFCC nipinlẹ Oyo, Dele Oyewale, fi le lede lori isẹlẹ naa, EFCC fẹsun kan osisẹ kan ati awọn akẹkọọ Ilẹ ẹkọ Federal College of Forestry fun bi wọn ṣe ti osisẹ EFCC meje mọ ninu ile kan.

"Awọn osisẹ ati akẹkọọ ile ẹkọ dena de wa, ti wọn si sekọlu si awọn osisẹ EFCC to n ṣe isẹ wọn"

O salaye pe awọn osisẹ n ṣe isẹ wọn lati ṣe iwadi lori oniduro kan ti o pe orukọ rẹ ni Azeez Kazeem Oluwakemi nigba ti awọn akẹkọọ kọlu wọn.

“Awọn osisẹ wa ni ile ẹkọ yii lati ṣe iwadii lori agbegbe ti Oluwakemi fi lelẹ lati ṣe oniduro fun Alakinde Khalid Kolawole, afurasi onijibiti ayelujara to wa ni agọ wa.

“Fun idi kan tabi omiran, awọn osisẹ ati akẹkọọ ile ẹkọ dena de wa, ti wọn si sekọlu si awọn osisẹ EFCC to n ṣe isẹ wọn.

“Saaju ni a ti fi to awọn alasẹ ile ẹkọ leti pe a ṣabẹwo si ọgba naa sugbọn adari awọn akẹkọọ ati osisẹ kan gbimọ pọ lati ṣekọlu si awọn osisẹ EFCC.”

“A ko yinbọn lu ẹnikẹni, a kan fi dẹru ba wọn ni”

Oyewale tẹsiwaju pe iroyin ofege ni iroyin to fẹsun kan awọn pe awọn yinbọn lu awọn akẹkọọ tabi osisẹ ile ẹkọ naa.

O jẹ ko di mimọ yinyin ibọn lo waye lati le ṣeruba awọn akẹkọọ to n ṣe ikọlu si awọn osisẹ EFCC.

“Ko si nnkan to jọmọ pe a yinbọn lu osisẹ atbi akẹkọọ, oke ni osisẹ EFCC yinbọn si lati ṣeruba awọn akẹkọọ naa.

“A wa n rọ gbogbo araalu lati ma foya sugbọn ajọ EFCC ko dẹkun igbogun ti iwa ọdaran lawujọ wa.”

Awọn alasẹ ti Ilẹ ẹkọ Federal College of Forestry pa

Aworan IWE ASE

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Awọn alasẹ ti ileẹkọ pa, wn ni kawọn akẹkọọ kuro ni ilegbe wọn lẹsẹkẹsẹ

Lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ ni ilẹ ẹkọ naa, awọn alasẹ ile ẹkọ naa ti pasẹ pe ki ile ẹkọ naa wa ni titi pa.

Igbesẹ yii awọn alasẹ fi ransi gbogbo awọn lọgalọga ni ile ẹkọ naa, ti akọwe ile ẹkọ naa, Arabinrin Abei Agun buwọlu salaye pe ki gbogbo ọrọ to ba jẹ mọ ẹkọ ni ile ẹkọ naa lọ mo omi lodo fun igba diẹ naa.

Bakan naa lo pasẹ ki awọn akẹkọọ kuro ni gbogbo ile wọn lẹsẹkẹsẹ, ki wọn si mo rile ile awọn obi wọn.

“Saaju ohun to waye eyi to eto alaafia ati eto ẹkọ ru lẹyin tawọn osisẹ EFCC kan dero atimọle, ti awọn akẹkọọ si se iwọde, gbogbo osisẹ ati akẹkọọ ile ẹkọ ni ki onikaluku wọn ma lọ si ile wọn nitori a ti ile ẹkọ yii pa fun igba diẹ.

“Bakan naa ni ki awọn akẹkọọ kuro ni gbogbo ile ti ile ẹkọ naa pese lẹsẹkẹsẹ.”