Ẹ̀mí méjì bọ́, ilé 18, ṣọ́ọ̀bù 27 jóná báwọn ọ̀dọ́ ṣe dáná sun ààfin ọba l’Osun

Osun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹṣọ alaabo Civil Defence kan ati ọdọ kan ti padanu ẹmi ninu rogbodiyan to waye ni ilu Araromi Owu, to wa ni ijọba ibilẹ Ayedaade, nipinlẹ Osun.

Yemisi Opalola, to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa lo fidi iroyin yii mulẹ fun BBC Yoruba.

Opalola ni ootọ ni pe ẹmi eeyan meji lo lọ si ikọlu to waye niluu Araromi Owu.

Isẹlẹ naa lo bẹrẹ ni deede agogo meji ọsan ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keje, ọdun 2024 ti a wa yii.

Opalola salaye pe, ẹmi ẹsọ alaabo Civil Defence kan lọ si ikọlu naa ati ẹmi ọkan lara awọn ọdọ to ṣe ikọlu si aafin ilu ọhun.

Osun

"Ohun to fa aawọ naa ni ọrọ ọlọba de, eyi ti ko yẹ ko fa aawọ rara bo ti wu ko ri"

Bakan naa ni wọn se ikọlu si Aafin Araromi Owu, ti wọn si jo aafin naa kanlẹ.

Yatọ si aafin ti wọn dana sun, wọn tun jo ile mejidinlogun, ile itaja mẹtadinlọgbọn, to fi mọ ọkọ ayọkẹlẹ meji.

Ninu alaye alukoro ọlọpaa, ohun to fa aawọ naa ni ọrọ ọlọba de, eyii ti ko yẹ ko fa aawọ rara bo ti wu ko ri.

Osun

Oríṣun àwòrán, bbc

"Ọwọ ọlọpaa tẹ afurasi mẹta lara awọn ọdọ to n fa wahala, ti wọn si ti wa ni kolo ọlọpaa"

Opalola fi kun un pe, ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ afurasi mẹta lara awọn ọdọ to n fa wahala naa ti wọn si ti wa ni kolo ọlọpaa bayii.

O ni iwadii ti bẹrẹ ati pe awọn ti da awọn ọlọpaa kogbọregbe siluu Araromi Owu bayii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ko si aye fun ẹnikẹni lati kọja lọ si iluu Araromi Owu lọwọ lọwọ titi tawọn yoo fi pẹtu si awọ naa.

Akitiyan akọroyin BBC Yoruba lati de ilu Araromi Owu lo ja si pabo latari bi awọn awakọ ero ṣe kọ lati lọ siluu naa lasiko yii nitori rogbodiyan ọhun.