"Ẹni ọdún 73 ni mí, ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn láti máa gbé irin"

Àkọlé fídíò, ‘Ẹni ọdún 73 ni mí, ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn láti máa gbé irin’
"Ẹni ọdún 73 ni mí, ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn láti máa gbé irin"

Iya agba ẹni ọdun mẹtalelaadọrin kan ti sọ fun BBC pe bo tilẹ jẹ pe agbalagba ni oun, oun fẹran lati maa gbe irin gẹgẹ bii ọdọ.

Iya agba naa sọ pe o ti le lọdun mẹwaa ti oun ti maa n ṣe ere idaraya.

O ni ọpọlọpọ anfani lo wa ninu ere idaraya ṣiṣẹ, oun ko si ṣetan lati fẹyinti ninu ere idaraya naa.

Igba mẹta laarin ọṣẹ ni iya agba ọhun ati ọkọ rẹ ,Abdultalib Umar, fi n ṣe ere idaraya ninu ọgba ile wọn to wa niluu Eko.

Lara ere idaraya ti wọn maa n ṣe ni irin gbigbe, ẹṣẹ kikan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O ni “mo fẹran ati maa gbe irin daadaa.

Orokun to n dun Roseline lakoko igba kan, lo mu ko bẹrẹ ere idaraya lẹyin ti dokita fun ni imọran pe ko din ara sisan ku.

Lati igba to ti bẹrẹ ere idaraya naa lọpọ ọdun sẹyin, ko tii dawọ rẹ duro.