Àwọn obìnrin ṣe ìwọ́de alẹ̀ torí dókítà obìnrin tí wọn pa lẹ́yìn tí wọn fipá bá a lòpọ̀ nílé ìwòsàn

Aworan awọn oluwọde naa

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn oluwọde naa.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ẹgbẹẹgbẹrun awọn obinrin ni wọn ya jade ni Iwọ-Oorun Bengal, lorilẹede India lalẹ Ọjọru,ọjọ kẹrinla oṣu kẹjọ ọdun 2024 yii, lati fẹhonu han lori iku dokita obinrin ti wọn fi ipa ba lo pọ, ti wọn tun pa lọsẹ to kọja.

Ilu kan ti wọn n pe ni Kolkata gan-an ni iṣẹlẹ yii ti waye, ọjọ Ẹti to kọja yii lo si ṣẹlẹ, ni ileewosan RG Kar Medical College.

Ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ni dokita to n kọṣẹ iṣegun oyinbo to lugbadi ibalopọ ipa ati iku ojiji naa.

Iwọde alẹ Ọjọru yii lo lagbara ju ninu gbogbo eyi ti wọn ti n ba bọ lẹyin iṣẹlẹ ọhun, nitori awọn obinrin kaakiri ẹka ni wọn dahun si ipe idajọ ododo naa.

Pẹlu bi ojo ṣe n rọ lalẹ Ọjọru naa to, awọn obinrin to n fi ẹhonu han naa gbe patako ọlọkan-o-jọkan dani, wọn si n beere idajọ ododo kaakiri igboro Kolkata titi de Iwọ-Oorun Bengal.

Bo tilẹ jẹ pe ifẹhonuhan wọn naa ko mu rogbodiyan dani, awọn ọlọpaa ati awọn ẹgbẹ kan ti wọn jẹ ọkunrin, di iwọde ọhun lọwọ nigba ti wọn yawọ ileewosan ti wọn pa dokita naa si, ti wọn si tu ẹka itọju pajawiri ibẹ ka yẹbẹyẹbẹ.

Awọn ọlọpaa yin ẹrọ tajutaju lati tu awọn oluwọde ka, bẹẹ ni awọn mọto ọlọpaa kan naa bajẹ ninu wahala naa.

Yatọ si iwọde Bengal, awọn ilu mi-in ti wọn tun ti wọde ni india ni Delhi, Hyderabad, Mubai ati Pune.

Àwọn ọmọdé àti àgbàlagbà ọkùnrin kan darapọ̀ mọ́ ìwọ́de

Awọn olufẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Jeet Sengupta

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati fi bi wọn ṣe fẹ idajọ ododo han si, awọn ọkunrin kan naa darapọ mọ iwọde yii, ko si yọ ọmọde ati agbalagba wọn silẹ.

Ni awọn igboro ilu mi-in, awọn obinrin n yan bii ologun bi wọn ṣe n rin ninu okunkun.

Ina abẹla, foonu, ati ina ti wọn tan funra wọn nikan ni wọn gbe dani lati fi ri ran bi wọn ṣe n wọde, bẹẹ ni awọn mi-in mu asia orilẹede wọn dani.

Awọn miran di ọwọ ara wọn mu, wọn gbe patako ẹhonu soke, akọle to han nibẹ n beere idajọ ododo.

Awọn oluwọde naa tun n fi ẹnu fọn ikarahun igbin, wọn lọ kaakiri agbegbe yunifasiti, ibudokọ, ile sinima ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Nigba to di ọwọ oru ọjọ naa, ti orilẹede India pe ọdun mẹtadinlọgọrin (77) ti wọn ti gba ominira, awọn oluwọde ọhun yi ọwọ́ iwọde yii pada.

Wọn bẹrẹ si i kọ orin orilẹede India, nigba naa ni ojo si bẹrẹ si i rọ, ṣugbọn awọn oluwọde ko kuro ninu ojo naa.

Awọn eeyan naa n rin ninu ojo, wọn n fi aburada bo ori wọn.

“ A ko ti i ri iru nnkan bayii ri niluu yii, ki awọn obinrin pọ to bayii laarin oru,” akọroyin kan ti iwọde naa ṣoju ẹ lo sọ bẹẹ.

Bakan naa ni iya kan to darapọ mọ iwọde naa pẹlu ọmọ rẹ obinrin, ẹni ọdun mẹtala, sọ pe, “Ẹ jẹ ka maa wo o boya iwọde elero rẹpẹtẹ yii le yi nnkan pada si daadaa. O yẹ ki obinrin mọ ẹtọ rẹ”.

"Ko si ọ̀wọ̀ fun obinrin, iyì wa ko to ti maaluu ati ti ewurẹ."

"Igba wo la fẹ gba ominira, igba wo ni ọkan wa maa too balẹ lati ṣiṣẹ lai si ibẹru, ṣe aadọta ọdun miran ni.? Bẹẹ ni ọmọbinrin akẹkọọ kan beere.

Obinrin kan, Sanchari Mukherjee, sọ pe oun rin pẹlu awọn eeyan ẹgbẹrun, lati ibudokọ Jadavpur. Awọn eeyan nla-nla, awọn ko-la-ko-ṣe agbe ati awọn talika, ojo to n rọ ko tiẹ jẹ nnkan kan si awọn.

" Mo ri awọn agbalagba tọkọ-tiyawo kan, ọkọ lo n ran iyawo lọwọ lati rin.

"Idile kan mu ọmọ wọn obinrin wa, boya to ba n ranti iwọde yii, bi awọn obi rẹ ṣe wọde tako ai si idajọ ododo, oun naa le ṣe bẹẹ lọjọ kan."

’’A fẹ idajọ ododo lo di akori iwọde yii’’

" O ba awa ọdọbinrin lọkan jẹ pe iru nnkan bayii ṣi n ṣẹlẹ ni 2024."

Bí wọ́n ṣe pa dókítà náà lẹyin tó ṣiṣẹ́ fún wákàti mẹ́rìndínlógójì lai sinmi

Aworan ọmọbinrin to mu abẹla dani, to n fi atẹlẹwọ rẹ beere fun idajọ ododo.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Aworan ọmọbinrin to mu abẹla dani, to n fi atẹlẹwọ rẹ beere fun idajọ ododo.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe ro o, ọmọbinrin to n kọṣẹ iṣegun oyinbo naa ti ṣiṣẹ fun wakati mẹrindinlogoji lai sinmi l’Ọjọbọ ọsẹ to kọja.

Lẹyin iṣẹ naa lo sun sinu gbọngan kan, nitori wọn ko pese aaye kankan to le sun si, nibẹ ni awọn kan ti lọọ fipa ba a lo pọ.

Aarọ ọjọ keji ni awọn akẹgbẹ rẹ ba oku rẹ nibi pepele, ti wọn ti bọ aṣọ lara rẹ de idaji, bẹẹ ni wọn ri awọn apa lara rẹ to pọ gan-an.

Awọn ọlọpaa pada mu oṣiṣẹ ileewosan kan lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn awọn eeyan n fi ẹsun kan wọn pe wọn n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu u.

Eyi lo fa a ti awọn afẹhonuhan fi jade yanturu lati gbe ọrọ naa dide fun idajọ ododo.

Wọn ti gbe ẹjọ naa kuro lọdọ awọn ọlọpaa abẹnu, o si ti wa ni ibudo iwadii ijọba apapọ bayii.

Ṣaaju iwọde naa ni wọn ti ni awọn ọkunrin le darapọ, ṣugbọn oloṣelu kankan ko gbọdọ da si i, bẹẹ ni ẹnikẹni ko gbọdọ mu asia ẹgbẹ oṣelu kankan wa.

Ifẹhonuhan waye ni India ni 1978, nigba ti wọn fipa ba obinrin kan lo pọ

Awọn oluwọde

Oríṣun àwòrán, Jeet Sengupta

Eyi kọ ni igba akọkọ ti ifẹhonuhan iru eyi yoo waye ni India, o ṣẹlẹ ni ọdun 1978, lẹyin ifipabanilopọ ti wọn ṣe fun obinrin kan.

Wọn kora jọ ni Bombay ti wọn n pe ni Mumbai bayii, wọn si wọde lati beere fun ẹtọ lati le rin loru lai si ifoya.

Bakan naa ni Blank Noise, agbẹkalẹ kan to n kede pe awọn obinrin ni ẹtọ lati rin loru, ti ṣeto aarin oru bi eyi ri ni Delhi.

Lati ki awọn obinrin laya pe wọn lẹtọọ lati rin loru, ṣugbọn ko ti i si eyi to tobi to ti Kolkata yii ninu iwọde.

"A ko ti i ri iru eyi ri niluu yii, ireti mi ni pe yoo jẹ ki awọn alaṣẹ ji giri si ojuṣe wọn.

Oluwọde kan, Chaitali Sen, lo sọ bẹẹ.