Ọkọ, ìyàwó àti àwọn ọmọ wọn kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ amala àti jéró

Eeyan mẹfa ninu idile ẹlẹni mẹwaa ti jade laye lẹyin ti wọn jẹ ounjẹ tan nijọba ibilẹ Shagari to wa nipinlẹ Sokoto, orileede Naijiria.
Awọn ara abule Naman Goma ti iṣẹlẹ ọhun ti waye sọ fun BBC pe lati Ọjọbọ, ọsẹ to kọja ni awọn mọlẹbi ọhun ti dubulẹ aisan lẹyin ti wọn jẹ amala ati jeero (millet) ti wọn ro papọ tan.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti wọn yoo maa jẹ iru ounjẹ naa.
Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?

Abdullahi Dandare to jẹ ẹgbọn baale ile naa sọ fun BBC pe nigba ti wọn ri ipo ti wọn wa, lo jẹ ki wọn sare fve wọn lọ si ọsibitu.
Dandare sọ pe, "ọjọ Ẹti la pinnu lati gbe wọn lọ si ile iwosan nitori pe ọrọ naa ti fẹẹ bẹyin yọ."
O fi kun ọrọ rẹ pe, "oju ọna la wa ti ọkan lara awọn ọmọ naa fi ku, nigba ti a de ile iwosan, ni mama awọn ọmọ naa ku."
"Awọn meji tun ku lẹyin iṣẹju diẹ ti mama wọn jade laye."
Dandare ni baba wọn wa lara awọn to ṣeto adura isinku fun awọn mọlẹbi rẹ marun-un to ku.
"Lẹyin eto isinku naa la ṣakiyesi pe ara baba naa ko da, idi si ree ti a fi gbe oun naa lọ sile iwosan, ṣugbọn to jẹ pe laarọ oni lo ku."
Dandare tẹsiwaju pe "awọn ọmọ mẹrin yooku wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju lori majele ti wọn jẹ."
Ọkan lara awọn ara adugbo to pe orukọ ara rẹ ni Abdullahi sọ fun BBC pe awọn mọlẹbi naa n gbe pẹlu alaafia ti wọn ko si ba ẹnikẹni ni gbolohun asọ labule.
"Emi pẹlu mọlẹbi jọ n gbe ninu ile kan naa ni, a ko si ni gbolohun asọ ri, wọn n ba wa gbe pẹlu alaafia ati iṣọkan."
Olori abule Naman Goga sọ pe oun ko si ni abule lasiko ìṣẹlẹ ọhun
O sọ pe oun mọ awọn mọlẹbi naa gẹgẹ bi oniwa tutu nitori pe wọn ko figba kan fa wahala ri.
Ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Sokoto sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori ohun to ṣẹlẹ

















