Ilé ẹjọ́ Sharia gbọdọ̀ wọ ìpínlẹ̀ Oyo àti Ekiti, òfin Naijiria faramọ́ kóòtù Sharia – Sultan Sokoto

Muhammad Sa'ad Abubakar, The Sultan of Sokoto

Oríṣun àwòrán, @CCSImpact

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ajọ to n ri si ọrọ awọn Musulumi ni Naijiria, Nigeria Supreme Council for Islamic Affairs, NSCIA, ti koro oju si bi awọn eeyan kan nilẹ Yoruba ṣe sọ pe awọn ko fẹ ile ẹjọ Sharia lagbegbe awọn.

Ọrọ naa lo jade ninu atẹjade kan ti agbẹjọro ajọ naa, Imam Haround Muhammad Eze, kọ lorukọ olori ajọ ọhun to tun jẹ Sultan ilu Sokoto, Alhaji Muhammad Sa'ad Abubakar.

Sultan Sokoto sọ pe inu oun ko dun si bi awọn eeyan kan nilẹ Yoruba ṣe kọ lati gba igbimọ idajọ Sharia laaye nilẹ naa, eyii to dabi igba ti wọn ba n fi ẹtọ awọn Musulumi agbegbe naa dun wọn.

O ni ko tọ bi awọn ara ilu kan, to fi mọ awọn olori kan nilẹ Yoruba, paapaa nipinlẹ Ekiti ati ipinlẹ Oyo ṣe faake kọri lati gba Sharia laaye.

Sa'ad Abuhakar sọ pe ofin orilẹede Naijiria faye gba igbimọ idajọ Sharia, o si jẹ ohun iyalẹnu pe awọn eeyan kan n fi ẹtọ awọn Musulumi dun wọn nipa bi wọn ṣe kọ lati gb Sharia laaye.

O sọ ninu atẹjade ọhun pe igbimọ Sharia "jẹ igbimọ ti yoo maa pari aawọ idile ati aawọ igbeyawo laarin awọn Musulumi lati di alafo ti ijọba ṣi silẹ lẹyin ti wọn kọ lati ṣabekalẹ ile ẹjọ Sahria gẹgẹ bii ofin Naijiria ṣe gbe kalẹ, bo tilẹ jẹ pe ọpọ Musulumi lo wa labegbe naa.

Sultan Sokoto

Oríṣun àwòrán, Sultan Sokoto

"Igbesẹ yii ati bi wọn ṣe kọ lati gba awọn akẹkọọbinrin Musulumi laaye lati maa lo ijaabu lẹyin ti idajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria faye gba a, jẹ ọna ti wọn n gba lati dina mọ awọn Mulusulumi lati ṣe ẹsin wọn."

Sultan Sokoto fi kun pe ofin orilẹede Naijiria ti wọn kọ lọdun 1999 faye gba ile ẹjọ Sharia gẹgẹ bo ṣe faye gba ile ẹjọ ijọba to n da si aawọ laarin araalu.

Atẹjade ọhun tẹsiwaju pe ẹgbẹ awọ Musulumi ni Naijiria faramọ agbekalẹ igbilọ idajọ Sharia nipinlẹ Oyo ati ipinlẹ Ekiti, atawọn ipinlẹ mii ti ko si kootu Sharia.

O fi kun pe niwọn igba ti awọn ipinlẹ kan nilẹ Hausa ti ni ile ẹjọ Sharia, ko si ohun to di awọn ipinlẹ Yoruba lọwọ lati ma le ni irufẹ kootu bẹẹ.

Lẹyin naa lo rọ awọn gomina, awọn ọba alade atawọn olori mii nilẹ Yoruba ti awọn Musulumi pọ si ki wọn gba igbimọ idajọ Sharia laaye ki awọn Musulumi to wa nibẹ le ṣe ẹsin wọn bo ṣe wu wọn.

Onírúurú ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá ṣèwọ́de tako ìfilọ́lẹ̀ òfin Sharia l'Ekiti

Awọn oluwọde

Oríṣun àwòrán, Ekiti

Ọrọ lori ofin Shari'ah t'awọn eeyan kan n gbero lati ṣe ifilọlẹ rẹ nipinlẹ Ekiti tun ti ba ọna miran yọ lẹyin ti ẹgbẹ ọmọ Yoruba, YRA at'awọn ẹgbẹ ajijagbara fún ilẹ Yoruba kan korajọ pọ ṣe iwọde tako ifilọlẹ ofin Shari'ah n'ipinlẹ naa.

N'iwaju ile itura kan lagbegbe Adebayo niluu Ado-Ekiti l'awọn olufẹhonuhan naa ti korajọ pọ nibi ti wọn ti n kọ orisirisi orin pẹlu iwe lọwọ wọn ti wọn kọ oriṣiiriiṣi ọrọ si bii "a o fẹ Shari'ah nilẹ Yoruba," Shari'ah yoo da ogun silẹ," "A o gba Shari'ah wọle".

Amọ, awọn ọlọpaa ko gb'awọn laye lati maa rin kaakiri ki rogbodiyan ma ba bẹ silẹ.l

Nigba to n b'awọn akọroyin sọrọ, Kọmureedi Opeoluwa Akinola sọ pe awọn to n pe fun ofin Shari'ah nilẹ Yoruba fẹ fi da wahala silẹ ni.

Kọmureedi Akinola ni ofin Shari'ah tako aṣa ati iṣe ẹya Yoruba.

Ogbeni Akinola sọ pe Yoruba ti n gbe papọ fun ẹgbẹlẹgbẹ lai fi ti ẹsin ṣe.

O ni ko si ipa kankan ti ofin Shari'ah fẹ ni bayii nilẹ Yoruba.

O wa kepe ijọba ipinlẹ Ekiti lati ma faye gba ẹnikẹni lati ṣe ifilọlẹ ofin Shari'ah ni ipinlẹ naa.

Akọle Oluwọde

Oríṣun àwòrán, Ekiti

"Oṣi ati iṣẹ lo n b'awọn eeyan ipinlẹ to n lo ofin Shari'ah lapa ariwa finra"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kọmureedi Akinola ni ko si àpẹẹrẹ idagbasoke ọrọ aje tabi igbayegbadun kankan fawon eeyan ipinlẹ mejila ti wọn n tẹle ofin Shari'ah lapa Oke Oya.

O ni iṣẹ ati oṣi si n bawọn eeyan ipinlẹ yii finra, o ni ọpọ awọn ọmọde nibẹ ko si nile ẹkọ nigba ti eto abo tun mẹhẹ lawọn ipinlẹ naa.

"Fun ọpọlọpọ ọdun lawọn oloṣelu lati apa ariwa Naijiria ti n gbero lati gbe iru ẹsin wọn lọ sawọn apa ibomiran eyi to n da rogbodiyan silẹ.

A fi asiko yii kepe awọn ẹgbẹ musulumi nilẹ Yoruba, ajọ ọmọlẹyìn Kristi CAN at'awọn ẹgbẹ oniṣẹṣe lati bẹnu ẹtẹ lu erongba awọn eeyan kan lati fi Shari'ah da wahala silẹ nilẹ Yoruba," Akinola lo sọ bẹẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, alaga ajọ YONAREC, Kọmureedi Oluwafemi Edafemi naa sọ pe ajọ naa tako ofin Shari'ah nilẹ Yoruba.

Ogbeni Edafemi sọ pe awọn alakatakiti ẹsìn musulumi kan lati apa ariwa lo wa nidi ọrọ naa.

Kọmureedi Edafemi ni ofin Shari'ah tako aṣa ati iṣe ẹya Yoruba ni gbogbo ọna.

O wa rọ gbogbo ọmọ Yoruba nile, loko and nilẹ okeere lati tako ifilọlẹ Shari'ah ki wọn si iṣọkan and ominira orilẹede.