Kò sí ilé ẹjọ́ Sharia ní ìpínlẹ̀ Ekiti, ẹni bá fẹ́ fi ẹ̀sìn dá wàhálà sílẹ̀ á fojú winá òfin - Ìjọba Ekiti

Àwòrán ìdàjọ́

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ìjókòó ìgbìmọ̀ Sharia tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Ekiti ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Kìíní, ọdún 2025 ló ti ń fa awuyewuye káàkiri ilẹ̀ Yorùbá.

Ohun tó ń fa awuyewuye kò ṣẹ̀yìn báwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ náà àti ilẹ̀ Yorùbá lápapọ̀ ṣe ń kọminú pé àwọn kan ti fẹ́ gbé ilé ẹjọ́ Shariah kalẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá.

Àwọn èèyàn yìí ń fẹ̀sùn kàn pé níṣe wọ́n ni wọ́n fẹ́ máa gbé àwọn òfin máṣu mátọ̀ wọ ilẹ̀ Yorùbá àti pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti ló ń ti ètò náà lẹ́yìn.

Ẹ̀wẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti ti wá jáde pé àwọn kò lọ́wọ́ nínú ìdásílẹ̀ ilé ẹjọ́ Shariah ní ìpínlẹ̀ náà àti pé àwọn mọ nǹkankan nípa ìgbìmọ̀ Independent Sharia Arbitration Panel táwọn kan gbé kalẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹjọ́rò àgbà, tó tún jẹ́ Kọmíṣánnà fétò ìdájọ́ ìpínlẹ̀ Ekiti, Dayo Apata fi léde lọ́jọ̀bọ̀, ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kìíní ṣàlàyé pé ìgbìmọ̀ Sharia náà kò sí lábẹ́ ètò òfin kankan ní ìpínlẹ̀ Ekiti.

Apata ní ètò òfin àti ìdájọ́ tó ti wà nílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ekiti ìyẹn ti Customary Court àti ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti Customary Court tó fi mọ́ ilé ẹjọ́ gíga ló ti máa ń gbọ́ ẹjọ́ tó bá jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn yálà ní ìlànà tí ẹ̀sìn Islam tàbí ti àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi.

Ó wòye pé àwọn ilé ẹjọ́ Shariah tó wà ní apá àríwá Nàìjíríà ló wà ní ipele kan náà pẹ̀lú àwọn Customary Courts tó wà lápa gúúsù àti pé kò sí ìnílò fún ìdásílẹ̀ ilé ẹjọ́ Sharia rárá.

Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn jẹ́ ohun tí èèyàn gbọdọ̀ fi pẹ̀lẹ́ kùtù ṣe, síbẹ̀ ó rọ àwọn adarí ẹ̀sìn láti jìnà sáwọn nǹkan tó le máa fa awuyewuye tàbí da omi àláfíà ìlú rú.

Ó ní ìjọba kò ní fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ìwà tó le mú àyípadfà bá ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ náà.

'Àmójútó aáwọ̀ láàárín àwọn Mùsùlùmí ni ìgbìmọ̀ Independent Shariah Panel tí a dá sílẹ̀ wà fún'

Aworan Amofin Tajudeen Olutope Hammed
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣáájú ni igbákejì adarí ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn mùsùlùmí ní ìpínlẹ̀ Ekiti ìyẹn Supreme Council For Islamic affairs tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ekiti Amofin Tajudeen Olutope Hammed sọ fún BBC News Yoruba pé ìgbìmọ̀ Independent Sharia Panel táwọn mùsùlùmí gbé kalẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ekiti wáyé láti máa mójútó àwọn awuyewuye tó ń wáyé láàárín ara wọn ni.

Amofin náà ṣàlàyé pé láti ọdún tó kọjá ni àwọn mùsùlùmí ní ìpínlẹ̀ náà kó ara wọn jọ, tí wọ́n sì pinnu láti gbé ìgbìmọ̀ náà dìde láti fi máa yanjú aáwọ̀ tó bá ń wáyé láàárín ara wọn.

Ó ní ìgbìmọ̀ náà kìí ṣe ilé ẹjọ́ táwọn nílò àṣẹ ìjọba kí àwọn tó gbe kalẹ̀ nítorí ó dàbí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹjọ́ nínú ìdílé tàbí àwùjọ kan ni.

Ó sọ pé àwọn ní ìmọ̀ dájú pé gbogbo nǹkan tí yóò máa wáyé nínú ìgbìmọ̀ náà kò gbọdọ̀ lòdì sí òfin ìjọba tàbí tako ìwé òfin Nàìjíríà àti pé gbogbo àwọn aláṣẹ tó yẹ kó mọ̀ nípa ìgbìmọ̀ náà bí àwọn agbófinró ni àwọn kọ̀wé ránṣẹ́ lórí ìjókòó ìgbìmọ̀ náà.

Ó ṣàlàyé pé àwọn mùsùlùmí nìkan ni ìgbìmọ̀ náà wà fún àti pé kò pọn dandan fún mùsùlùmí tí kò bá wù láti máa gbé ẹjọ́ rẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn.

Tajudeen fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn kò ní èròńgbà láti fi ìgbìmọ̀ náà da omi àláfíà ìpínlẹ̀ Ekiti rú nítorí ìgbìmọ̀ náà ti wà láwọn ìpínlẹ̀ míì bíi Osun àti Eko, tí kò sí sí wàhálà kankan láti bíi ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ti wà láwọn ìpínlẹ̀ náà.

Bákan náà ló ṣàlàyé pé ìgbìmọ̀ náà kò ní máa fìyà jẹ ẹnikẹ́ni nígbà tí wọ́n bá gbé ẹjọ́ wọn bíkòṣe láti máa fi pẹ̀ẹ̀tù sáwọn mùsùlùmí tí gbọ́nmi si omi ò to bá ń wáyé láàárín ara wọn àti pé kò ní máa gbọ́ ẹjọ́ ọ̀daràn bíkòṣe àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ju agbára lọ.

Ó ní àwọn tó bá fẹ́ wá síwájú ìgbìmọ̀ náà gbọdọ̀ fẹnuk]o láàárín ara wọn kí wọ́n tó wá, tí wọn kò sì gbọdọ̀ fi dandan tàbí agidi mú ẹnikẹ́ni láti gbé ẹjọ́ síwájú ìgbìmọ̀ náà.

Ó sọ pé àwọn àgbààgbà nídìí ẹ̀sìn Islam àtàwọn agbẹjọ́rò ni àwọn tó jẹ́ adájọ́ tó ń gbọ́ ẹjọ́ ní ìgbìmọ̀ náà.

"Tí ìgbìmọ̀ Sharia bá gbé ìdájọ́ kalẹ̀, wọn kò le fi agidi mú èèyàn láti tẹ̀le bíi ti kóòtù ti ìjọba."