Kílódé tí àwọn èèyàn fi ń bínú sí Elon Musk lẹ́yìn ìbúrawọlé Trump?

Elon Musk

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, George Wright
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Baba olowo, Ellon Must ti mu inu bi ọpọ ọmọ ilẹ Amẹrika latari bo ṣe ju ọwọ si awọn eeyan lọjọ iburawọle Aarẹ Donald Trump.

Lọjọ iburawọle naa ni Musk dupẹ lọwọ araalu fun atilẹyin wọn lati jẹ ki Trump wọle ipo Aarẹ, lẹyin naa lo gbe ọwọ si aya rẹ to si n ju ọwọ keji si awọn eeyan niwaju, o tun ṣe bẹẹ si awọn eeyan to wa lẹyin rẹ pẹlu.

Ọpọ eeyan loju opo X to jẹ ti oun funra lo bu ẹnu atẹ lu u nibẹ, ti wọn si n sọ pe o n ki awọn eeyan gẹgẹ bii iṣe awọn eeyan Nazi laye igba Hitler lọpọ ọdun sẹyin.

Amọ nigba to n fesi, o ni ko tu irun kankan lara oun bi awọn eeyan se n fi oun we Hitler.

Asiko ti Musk, to jẹ ọkunrin to lọrọ julọ lagbaye, o tun jẹ ọrẹ timọtimọ Aarẹ Trump n sọrọ lọjọ iburawọle naa lo ki awọn eeyan bẹẹ.

O sọ lọjọ naa pe "Mo dupe lọwọ gbogbo yin ti ẹ jẹ ki a le gba ọjọ iwaju to dara mu."

Ni kete to sọrọ tan lọjọ naa lawọn eeyan bẹrẹ si n fi oko ọrọ ranṣẹ si lori ayelujara.

Claire Aubin, to jẹ onimọ nipa itan Nazi nilẹ Amẹrika sọ pe bi Musk ṣe ki awọn eeyan ni wọn n pe ni "sieg heil" eyii to jẹ bi awọn Nazi ṣe n ki ara wọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aubin ni ohun ti awọn eeyan n ro gan ni Musk ṣe lai ṣe iyemeji, gẹgẹ bii iwoye toun.

Ruth Ben-Ghiat, to jẹ Ọjọgbọn nipa itan ni fasiti New York naa tun sọ pe bi awọn eeyan Nazi ṣe maa n ki ara wọn niyẹn.

Andrea Stroppa, to jẹ ọrẹ timọtimọ Musk ti sọ pe ikini naa jẹ ti awọn eeyan ilu Rome.

Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Benito Mussolini lo kọkọ n ki ara wọn bẹẹ ki Adolf Hitler to bẹrẹ si n sẹ bẹẹ ni Germany lọdun naa lọhun.

Stroppa gbe fidio ikini naa jade loju opo ayelujara rẹ nibi to ti sọ pe "Ijọba Rome ti pada pẹlu ikini Rome."

Bo tilẹ jẹ pe o ti yọ fidio ọhun bayii, awọn iwe iroyin kan ni Italy ni ikini naa n tumọ si pe Musk n sọ pe oun fẹ fi ọkan oun fun awọn eeyan.

Wayi o, ẹgbẹ kan, Anti-Defamation League ti sọ pe Musk ko ki awọn eeyan ni ikini Nazi rara, amọ ohun to ṣe waye latari bi inu rẹ ṣe dun to lọjọ iburawọle ọrẹ rẹ.

Igbagbọ wa pe Musk yoo kopa ninu ijọba Trump lẹyin ti iroyin sọ pe yoo jẹ ọkan lara awọn adari ẹka ti yoo mojuto awọn aṣeyọri ijọba, iyẹn Department of Government Efficiency.