Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkọ tó kun ìyàwó rẹ̀ wẹ́lẹwẹ̀lẹ sínú àpò

Aworan Afurasí

Oríṣun àwòrán, Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá Kenya

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Kenya ti mu ọkùnrin to ṣekupa iyawo rẹ ẹni ọdun mọkandinlogun, to si ge ẹya ẹya ara wẹlẹwẹlẹ sinu apo.

Afurasi naa, John Kiama Wambua, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ni ọwọ tẹ ni agbegbe Huruma lorilẹede ọhun.

Wambua ni awọn ọlọpaa furasi pe o n gbe nnkan pamọ nigba ti wọn da duro, to si jẹ ohun iyalẹnu nigba tí wọn tu apo ọwọ rẹ, ti wọn si ba oku eeyan ti wọn ti ṣa si wẹwẹ.

Ohun to sẹlẹ yii ki n ṣe ohun tí wọn le gbe pamọ nítori orilẹede Kenya ni orilẹede tí wọn ti ń se ṣekupa obinrin ju ni Afrika.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lede, wọn ni afurasí naa sọ fun awọn pe oku iyawo oun, Joy Fridah Munani loun ge sinu apo.

Lẹyin ọpọlọpọ iwadii, Wambua mu awọn agbofinro lọ sí ile rẹ nibi ti wọn ti sawari ìbọn pẹlu aṣọ ẹjẹ ni abẹ ibusun rẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa jẹ ko di mímọ pe afurasi ọhun yoo foju ba ile ẹjọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe laarin oṣu kẹjọ ati kẹwaa ọdun to kọja, o le ni obìnrin mẹtadinlọgọrun to padanu ẹmi wọn.

Ní oṣu Kejila ọdun to kọja, ọpọ obìnrin lo ya sita lati ṣe ifehonuhan niluu Nairobi ti ọlọpaa si yín gaasi taju taju si wọn.

Ọpọ awọn obinrin to ni okiki lo ti padanu ẹmi sọwọ awọn agbenipa lorilẹede Kenya.