'Ó tẹ́mi lọ́rùn láti di àgbẹ̀ ju kí n padà sílé ẹ̀kọ́ lọ'

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma/BBC
- Author, Azeezat Olaoluwa
- Role, Senior Journalist Reporter, West Africa
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Mariam, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún ní ìrètí láti padà sí ilé ẹ̀kọ́ lọ́jọ́ bí ó ṣe jòkòó sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé àwọn òbí rẹ̀ lẹ́yìn tó darí ilé kéwú.
"Inú mi kò dùn pé mi ò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àmọ́ mo ní ìgbàgbọ́ pé mà á padà sẹ́nu ẹ̀kọ́ lọ́ja kan."
Mariam wà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 280 táwọn ajínigbé jí gbé ní ilé ẹ̀kọ́ wọn ní Kuriga, ìpínlẹ̀ Kaduna nínú oṣù Kẹta ọdún 2024. Ọjọ́ Mẹ́tàdínlógún ni wọ́n l]o ní àhámọ́ àwọn ajínigbé lásìkò náà kí wọ́n tó gba ìtúsílẹ̀.
Òun àtàwọn yòókù rẹ̀ kò ì tíì padà sílé ẹ̀kọ́ láti ìgbà náà.
Nàìjíríà wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tó ní àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn ọmọdé tí kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tó pọ̀ jùlọ àmọ́ àìsí ààbò tó péye àti ìjínigbé tó ń wáyé pàápàá ní apá àríwá tún ń mú ìwà peléke si.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma/BBC
Gẹ́gẹ́ bí àjọ UNICEF ṣe sọ, àwọn ọmọdé tí iye wọn tó 18.3m ni kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Afíríkà. Ọ̀pọ̀ wọn ló wà ní apá àríwá èyí tí àìsí ààbò àti ìṣẹ́ ń ṣokùnfà rẹ̀.
Àjọ náà sọ nínú ìjábọ̀ kan tí wọ́n fi léde lọ́dún tó kọjá pé ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé mọ́kàndínlógún ló wà ní àkọ́ọ́lẹ̀ láàárín ọdún 2022 àti 2023, èyí tó ṣokùnfà títi ilé ẹ̀kọ́ 113 pa ní ìpínlẹ̀ Borno Adamawa àti Yobe nìkan látàrí ètò ààbò tó mẹ́hẹ.
Ìjínigbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kuriga jẹ́ èyí tó lágbára lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá táwọn ajínigbé jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Chibok gbé. Ìjínigbé yìí fa awuyewuye káàkiri àgbáyé.
BBC ṣe ìrìnàjò lọ sí Kuriga tí a sì ní àǹfàní láti wọ ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gbé àti láti fọ̀rọ̀ wá lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé náà lẹ́nu wò. Kò sí nẹ́tíwọọ̀kì ní gbogbo ojú ọ̀nà fún bíi wákàtí méjì tí ikọ̀ ìròyìn BBC lò lójú ọ̀nà. Àwọn ọlọ́pàá sọ fún wa pé Kuriga jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi tó léwu gidi ní ìpínlẹ̀ Kaduna.
Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú kéréje tó wà lójú ọ̀nà ìlú Kuriga ló ti di ahoro tán látàrí ìkọlù àwọn ọ̀daràn tó máa ń ṣe ìkọlù sí wọn.
Bàbá Mariam, Idris Alhassan pinnu láti kó àwọn ẹbí rẹ̀ kúrò ní Kuriga, tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti má dé ìlú rẹ̀ mọ́ láéláé.
"Èmi ni wọ́n kọ́kọ́ jí gbé kí ìjínigbé ilé ẹ̀kọ́ náà tó wáyé. Ọjọ́ mẹ́rin ni mo lò ní àhámọ́ wọn kí n tó móríbọ́ lọ́wọ́ wọn. Ọja díẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n padà wá láti jí ọmọ mi àtàwọn yòókù rẹ̀ gbé.
"Èyí ló jẹ́ àmì fún mi láti kó àwọn ẹbí kúrò níbẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan tí wọ́n jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé ni mo kúrò níbẹ̀, ìgbà tí wọ́n tú wọn sílẹ̀ ni mo padà lọ síbẹ̀ láti lọ mú Mariam. Mi ò rò pé má à padà síbẹ̀ mọ́."
Ìlú Rigasa, tó wà ní ẹ̀bá olú ìlú Kaduna ni Mariam àtàwọn ẹbí rẹ̀ ń gbé báyìí, pẹ̀lú àwọn ẹbí míì táwọn náà sá kúrò ní ìlú wọn nítorí àìsí ètò ààbò.
Wọn kò ní ilẹ̀ láti dáko tàbí kọ́ ilé lé lórí èyí tó mú kí wọ́n máa tiraka láti wá ohun ìnílò fún ìgbé ayé wọn. Èyí túmọ̀ sí pé Mariam àtàwọn yòókù rẹ̀ kò ì tíì padà sílé ẹ̀kọ́.
"Ìgbé ayé ní Rigasa lágbára díẹ̀. Kò sí iṣẹ́, kò sí oúnjẹ, kò sí ìlé ẹ̀kọ́ fáwọn ọmọ wa, ká tó wá máa sọ̀rọ̀ ìlera. Kò sí ìlé ẹ̀kọ́ tó súnmọ wa, a sì ń bẹ̀rù láti rán àwọn ọmọ wa lọ sí ọ̀nà tó jìn nítorí ìbẹ̀rù tó wà lára wa fún nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀," Bàbá Mariam sọ.
Nígbà táwọn ọmọ tó bá ti dàgbà bá ti jáde lọ, Mariam àtàwọn yòókù rẹ̀ máa ń jòkòó sílé láti lọ sí ilé kéwú.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma/BBC
Nígbà táwọn ọmọ tó bá ti dàgbà bá ti jáde lọ, Mariam àtàwọn yòókù rẹ̀ máa ń jòkòó sílé láti lọ sí ilé kéwú.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna sọ pé ilé ẹ̀kọ́ tó tó ọ̀ọ́dúnrún (300) ni àwọn ni àwọn ti kó kúró láwọn ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ lọ sí àwọn ibòmíràn.
"Nígbà tí a gba ìjọba lọ́dún 2023, ilé ẹ̀kọ́ tó tó ẹgbẹ̀rin (800) ni ó wà ní títìpa tàbí tí wọ́n ti pa tì nítorí àìsí ààbò," Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Uba Sani sọ fún BBC News.
"Àwọn ọmọdé tí iye wọn tó 736,000 tí kò sí ní ilé ẹ̀kọ́ àmọ́ a ti dá bíi àwọn 300,000 padà sí ilé ẹ̀kọ́."
Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìgbìyànjú ìjọba yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà ló ṣì wà ní títìpa, táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sì ń bẹ̀rù láti padà sí ilé ẹ̀kọ́.
Auwal Adamu, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún sọ fún BBC News pé òun kò fẹ́ padà sí ilé ẹ̀kọ́ nítorí ẹ̀rù ń ba òun àti pé òun tí òun là kọjá nígbà tí wọ́n jí òun gbé kò ì tíì kúrò ní ọpọlọ òun.
"Ẹ̀rù ń bàmí pé àwọn agbébọn le tún wá jí mi gbé. Èmi ni mo mọ àwọn ìpèníjà tí mo là kọjá nígbà tí mo wà ní àhámọ́. A rìn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ láì sinmi àti àìsí oúnjẹ. Ó tẹ́mi lọ́rùn kí n jẹ́ àgbẹ̀ ju kí n lọ sílé ẹ̀kọ́ lọ."
Ìyá Auwal, Hussaina Adamu faramọ́ ìpinnu ọmọ rẹ̀ yìí, bí ó ṣe ṣàlàyé pé òun kò lè fi ààbò ọmọ òun tàfàlà rárá.

Oríṣun àwòrán, Gift Ufuoma/BBC
Cristian Munduate, aṣojú UNICEF ní Nàìjíríà ń fẹ́ kí akitiyan sí láti ọ̀dọ̀ ìjọba kí Mariam àti Auwal le padà sí ilé ẹ̀kọ́.
"Àwọn aláṣẹ nílò láti wá àwọn ọ̀nà tó máa ta àwọn òbí jí láti dá àwọn ọmọ wọn padà sí ilé ẹ̀kọ́."
Gómìnà Sani sọ pé dídá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ìjínigbé ṣàkóbá fún ni ó jẹ́ àkọ́kọ́ táwọn fẹ́ kó padà sí ilé ẹ̀kọ́.
Mariam àtàwọn ọmọ míì ní Rigasa tí wọ́n ṣì ní ìrètí láti padà sí ilé ẹ̀kọ́ ni wọ́n ní ìgbàgbọ́ pé ìjọba àtàwọn òbí àwọn yóò wá ọ̀nà táwọn fi máa padà sílé ẹ̀kọ́.
"Dókítà tàbí agbẹjọ́rò ló wù mí láti di lọ́jọ́ iwájú, ìdí nìyí ló fi wù mí láti padà sí ilé ẹ̀kọ́."
Àfikún ìròyìn látọwọ́ Yusuf Akinpelu












