Mudashiru Obasa: Èmi ṣì ni olórí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko, ìyọnípò mi kò bá òfin mu

Oríṣun àwòrán, Hesso Photo
Agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ti wọn yọ nipo bii jiga, Mudashiru Obasa ti sọ pe oun ṣi ni ojulowo olori ile naa.
Ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, ọdun 2025 yii ni wọn yọ Obasa nipo lẹyin ti mejilelọgbọn ninu aṣofin ogoji fọwọ si iyọnipo rẹ.
Ilẹ Amẹrika ni Obasa wa lọjọ ti awọn akẹgbe rẹ gbe igbesẹ ọhun.
Ni bayii to ti pada de lati irinajo, ọgọrọ awọn ololufẹ rẹ ti korajọ siwaju ile aṣofin naa to n ṣoju ẹkun kinni ni Agege lati ki kaabọ.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ nibẹ, ọkunrin naa sọ pe iyọnipo oun ko tẹle ilana ofin, nitori naa, oun ṣi ni olori ile aṣofin ọhun ayafi ti awọn to yọ oun nipo ba tẹle ofin.
O ṣalaye pe ẹru iyọnipo ko ba oun amọ wọn gbọdọ gbe igbesẹ naa ni ilana to ba ofin mu.
O ni "Ni gbogbo ipinlẹ Eko, ẹ jẹ ki eyikeyi adari jade sita ki wọn si sọ ni gbangba pe mo wa ba awọn pe mo fẹ di gomina.
"Lati yọ olori ile aṣofin nipo, a gbọdọ tẹle ofin. Ko kan mi o ṣugbọn pẹlu ọkunrin to sọ pe mo wa lara awọn to yọ olori ile tẹlẹ, Jokotade Pelumi, igbakeji, Funmi Tejuosho atawọn aṣofin mii ti wọn ni ki wọn lọ rọọkun nile, a ṣe e ni ilana ofin.
"Pelumi wa ninu ile nigba ti wọn yọ ọ nipo, bẹẹ naa ni Tejuosho atawọn ti a ni ki wọn lọ rọọkun nile wa nikalẹ, bẹẹni ọlọpaa ko da si ọrọ naa rara.
"Amọ nigba ti yoo di ori temi, bawo ni ọgọrọ ọlọpaa, ti kọmiṣọna ọlọpaa dari wọn, ṣe yabo ile aṣofin, ti ikọ awọn ọlọpaa mii si yabo ile ti mo n gbe?
"Won ti ilẹkun mọ awọn ọmọ mi sita ti iya wo mi si wa ninu ile.
"Ọdun mẹwaa gbako ni mo fi ṣe olori ile aṣofin, ti wọn ko ba fẹ mi mọ, ọdọ Ọlọrun ni a ti wa, ọdọ rẹ si ni a maa pada si amọ ẹ ko le lo ayederu ọpa aṣẹ ile aṣofin lati yọ olori ile nipo."















