Bukky Wright, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, ṣàlàyé ohun tó kàn lẹ́yìn ọdún pípẹ́ lókè òkun

Aworan Bukky Wright

Oríṣun àwòrán, Bukky Wright/ Instagram

Àkọlé àwòrán, Bukky Wright
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajumọ ọsere obinrin nni, Oluwabukola Ajoke tawọn eeyan mọ si Bukky Wright, ti ṣalaye ohun ti yoo maa ṣe bayii lẹyin ọdun pipẹ to lo loke okun.

Ẹ o ranti pe o ti le lọdun mẹẹẹdogun ti arẹwa obinrin naa ti kuro lorilẹede Naijiria ati lagbo tiata Yoruba, to si fi Richmond, Texas, ṣe ibugbe, lorilẹede America.

Imọ ẹrọ to ni i ṣe pẹlu yiyẹ owo ileeṣẹ wo finni-finni (Information System Auditor), Business analysis, Salesforce adminstration and data analytics ni iṣẹ ti oṣere yii kọ ni gbogbo igba to fi wa loke okun, o si gba oye nipa rẹ.

Ni bayii ti ọmọ bibi ilu Abeokuta, nipinlẹ Ogun naa ti pada si Naijiria, eyi lohun to ni ohun yoo maa ṣe.

'Ìmọ̀ ẹ̀rọ tí mo kọ́ kò dí iṣẹ́ tíàtà lọ́wọ́'

Bukky Wright

Oríṣun àwòrán, Bukky Wright/ Facebook

Gẹgẹ bi Bukky Wright ṣe ṣalaye ninu ifọrọwerọ kan to ṣe laipẹ pẹlu ẹka ayelujara kan, o ni:

" Mo maa maa ṣiṣẹ imọ ẹrọ pọ mọ iṣẹ amuludun ni.

''Pe mo tiẹ ya kuro loju ọna afẹfẹyẹyẹ ati faaji, mo wọnu ohun to yatọ gedegbe, jẹ ohun ti ọpọ eeyan ro pe mi o le ṣe.

"Ohun ti mo maa sọ fawọn to n wo mi kọṣẹ ni pe ti emi ba le ṣe e, awọn naa le ṣe e niyẹn."

O fi kun un pe ẹkọ nipa imọ ẹrọ ko ni i di iṣẹ tiata oun lọwọ lasiko yii rara.

"Ohun to wu mi lati ṣe bayii ni pe ki n ba awọn akẹgbẹ mi lagboo tiata ṣiṣẹ papọ, ki n si jẹ amala ilẹ Naijiria gidi

Mo ti de digbi."

Nipa ẹwa rẹ ti ko ṣa bo ṣe ti n dagba to, Bukky Wright sọ pe aṣiri naa ni pe oun maa n sun daadaa.