Adedoyin kò fì ìgbà kankan sanwó iléèwé àwọn ọmọ wa- Mọ̀lẹ̀bí Adegoke

Oríṣun àwòrán, BBC/Others
Molẹbi akẹkọọ fasiti OAU, Timothy Adegoke, to padanu ẹmi si ile itura kan niluu Ile Ife ti ni ọkan lara awọn olujẹjọ to n jẹjọ lori iku oloogbe, Oloye Ramon Adedoyin ko figba kankan san owo ile ẹkọ awọn ọmọ oloogbe naa.
Ẹgbọn oloogbe, Adegoke Olugbade, lo sọ eyi fun BBC .
Olugbade ni awọn mọlẹbi ko gbọ ohunkohun lati ọdọ mọlẹbi Adedoyin saaju idajọ ile ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun niluu Akure.
Bẹ o ba gbagbe, ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun, ni Adajọ Adepele Ojo, ti gbe idajọ kalẹ pe ki wọn yẹgi fun Adedoyin ati awọn meji mi-in, ki Adedoyin si maa san owo ile ẹkọ awọn ọmọ oloogbe naa.
Sugbọn, Adedoyin morile ile ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun niluu Akure lati tako idajọ naa.
Ẹwẹ, Ile ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun to jokoo l'Ọjọbọ niluu Akure, tun fi ontẹ lu idajọ iku ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun ti da tẹlẹ fun Adedoyin ni.
Lati ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa ọdun 2024 ni ile ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun ti ṣe agbekalẹ idajọ naa, ki o too ka a l'Ọjọbọ, ọjọ kẹtalelogun oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.
Ile ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun sọ pe ko si aṣiṣẹ ninu idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun to dajọ iku fun gbajugbaja oniṣowo, Adedoyin.
Ile ẹjọ ni idajọ iku ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun da tẹlẹ fun Adedoyin, tọna labẹ ofin pẹlu nnkan to ṣẹlẹ.
Amọ, ile ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun fagile idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Osun to gbẹsẹ le ile itura Hilton Hotel to jẹ ti Adedoyin.
Bakan naa ni ile ẹjọ Ko-tẹmi-lọrun tun fagile idajọ ile ẹjọ giga to paṣẹ pe ki Ọgbẹni Adedoyin maa sanwo ile ẹkọ awọn ọmọ Oloogbe Timothy Adegoke.
Olugbade ni inu awọn mọlẹbi dun si igbẹjọ naa to tun fi ontẹ lu u pe ki wọn lọọ yẹgi fun Oloye Ramon Adedoyin.















