Èyí ni àpẹẹrẹ mẹ́wàá tí o fi lè mọ̀ bí ọmọ rẹ bá ti ń mu ìmukúmu

Oríṣun àwòrán, iStock
Ọkan ninu awọn iṣoro to n koju awujọ eeyan fun ọdun pipẹ, paapaa nilẹ Africa ti Naijiria jẹ ọkan ninu wọn, ni aṣilo oogun, ijẹkujẹ ati imukumu.
Bi awọn ijọba lẹka ọtọọtọ ṣe n sa ipa wọn lati dẹkun iṣoro yii to, titi kan ajọ to n gbogun ti oogun oloro; 'Nigerian Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), sibẹ, iṣoro naa ko tan.
To ba ṣe bii ti ọti mimu to jẹ ọkan lara wahala yii ni, awọn ọdọ ni wọn sabaa maa n kopa ninu rẹ ju.
Ajọ NDLEA fidi eyi mulẹ.
Lọpọ igba si ree, bi wọn ba ti n yọ ọti mu lo maa n di pe wọn yoo bẹrẹ awọn iwa ipanlẹ miran bii jagidijagan, iwa ọdaran, ole jija ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bí o ṣe lè dá ọmọ tó ti ń yọ́ ọtí tàbi sìgá mu mọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty image
Abdullahi Sardauna, Igbakeji ọga agba ajọ NDLEA to n mu awọn arufin nipinlẹ Borno, ṣalaye awọn apẹẹrẹ mẹwaa fun BBC
1 – Àyípadà ìwà
Nnkan akọkọ ti obi yoo fura si nipa ọmọ to ba ti n yọ ọti mu ni ayipada ninu iwa ọmọ naa.
" Bi ọmọ rẹ ba jẹ ọmọluabi tẹlẹ, ti o si ri i pe o deede yipada si awọn iwa aburu, wadii rẹ daadaa."
2 – Àyípadà àwọn ọ̀rẹ̀ àti alájọṣe
Bi o ba ri i pe awọn ọrẹ ti ọmọ rẹ n ba rin tẹlẹ kọ lo tun n tẹle mọ, fura."
3) Àyípadà ìgbésí ayé
Abdullahi Sardauna sọ pe, "Fun apẹẹrẹ, ọmọ rẹ ọkunrin tabi obinrin to maa n tete sun tẹlẹ, di ẹni to n pẹẹ ko too lọọ sun.
Tabi eyi to maa n tete ji tẹlẹ, to di alasun ba oorun yọ lojiji, fura."
4) Àyípadà oúnjẹ
Nigba ti ọmọ ba bẹrẹ si i mu ọti, bi o ṣe n jẹun tẹlẹ maa yipada, gẹgẹ bi ọga NDLEA yii ṣe sọ.
"To ba jẹ pe ọmọ rẹ ki i jẹun pupọ tẹlẹ, o si deede ri i pe o ti n jẹun ju ti tẹlẹ lọ, tabi to ba jẹ pe o maa n jẹun daadaa tẹlẹ to si di pe ko le jẹun daadaa mọ, wadii ohun to n ṣẹlẹ."
5) Bí nǹkan bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọnù nílé
To ba di pe awọn nnkan n sọnu ninu ile, apẹẹrẹ to yẹ ki o mojuto ni.
" Waso sọnu lonii, ọgọrun-un naira sọnu lọla, ko si ki n ri bẹẹ tẹlẹ, wadii ọmọ rẹ."
O ni awọn ọmọ mi-in maa n ji nnkan obi wọn ti wọn yoo si ta a, o le jẹ aṣọ, goolu ati bẹẹ lọ. Wọn yoo fi owo rẹ mu ọti tabi imukumu ti wọn ba n yọ mu.
Irọ́ pípa
Irọ pipa jẹ apẹẹrẹ kan ti o gbọdọ fura si lẹnu ọmọ rẹ.
" Yoo maa hu awọn iwa to yatọ, ti o ba si beere lọwọ rẹ, aa parọ pe oun kọ. Obi gbọdọ mọ pe o ni nnkan kan ti ọmọ naa fi n pamọ. "
7) Inú fùfù
Eyi jẹ apẹẹrẹ kan ti o maa ri bi ọmọ rẹ ba ti n mu imukumu tabi jẹ ijẹkujẹ.
8) Bíbá àwọn agbófinró bínú
Nigba ti ọmọ rẹ ba ri agbofinro lori amohunmaworan to si bẹrẹ si i binu, to n ṣepe fun wọn to si n fi aidunnu rẹ han, fura si ọmọ rẹ.
O ti le maa huwa ọdaran ti ko ba ofin mu.
9) Ìyípadà nínú ìrísí
Bi ọmọ ba pupa tẹlẹ, ẹ maa ri i pe awọ rẹ n yipada si dudu. Bi eyin ẹnu rẹ ba funfun tẹlẹ, yoo bẹrẹ si i dudu, bẹẹ ni awọ ara rẹ, ẹsẹ ati ọwọ. Obi to ba ni afiyesi lo le ri i.
10) Ọmọ yóò maa pẹ́ẹ́ kó tóó wọlé
Ọkan lara awọn apẹẹrẹ pe ọmọ ti n mu ọti ni pe yoo maa pẹẹ de lati ode ju ti tẹlẹ lọ.
"Bi o ba ri i pe ọmọ to maa n tete pada sile ti di apẹlẹyin to n foru wọle, o yẹ ki o wadii ọmọ rẹ boya o ti n jokoo faaji ọti nibi kan."
Kí ló ń mú àwọn ọ̀dọ́ mu ọtí?
Igbakeji ọgba agba ajọ NDLEA ni Borno, Abdullahi Sardauna, ṣalaye pe awọn nnkan to n mu awọn ọdọ mu ọti ni :
*Aisi abojuto to peye lati ọdọ obi
Nigba ti obi ko ba bojuto iwa ọmọ rẹ, tabi to n dagunla si aye ọmọ, le fa a ti ọmọ naa yoo fi wọ ẹgbẹkẹgbẹ to n kọ wọn ni iwakiwa.
Ipinya laaarin awọn obi tun jẹ idi miran, bi Sardauna ṣe ṣalaye.
*Ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ : Iru ọrẹ ti ọmọ n ba rin ati ẹgbẹ to n ko, le fa a ti yoo fi maa mu imukumu tabi jẹ ijẹkujẹ, hu iwakiwa pẹlu.
*Àìbalẹ̀ ọkàn: Abdullahi Sardauna ṣalaye pe aibalẹ ọkan ko jẹ ki aye roju.
O ni ko sibi ti eeyan lọ ti ko si jagidijagan, eyi si n fa a ti awọn ọdọ miran fi n wọ
ẹgbẹ onimukumu.
*Pípọ̀ yanturu àwọn ìmukúmu yìí:Bi eeyan sẹ le ya ile olounjẹ ko jẹun to wu u, bẹẹ naa ni awọn ọti ati ohun mimu oloro ṣe wa fawọn to n mu wọn lai ṣe wahala rara.
*Ọwọ́ tó dilẹ̀: Airikanṣekan jẹ idi kan ti awọn ọdọ fi n wọ ẹgbẹ ọmuti ati onimukumu
"Ọmọ to jokoo laaarin awọn eeyan ti ko niṣẹ, oun naa yoo maa ronu ohun ti awọn alainiṣẹ n ṣe, yoo si fẹẹ ṣe e."












