Ta làwọn tó le dín agbára Ààrẹ Trump kù?

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Ángel Bermúdez
- Role, BBC News Mundo
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7
Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump tí jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe kan ní orílẹ̀ èdè náà ní sáà kejì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ yìí.
Lẹ́yìn tí wọ́n búra fún un tán ló buwọ́lu àwọn òfin kan tó fi mọ́ kíkéde ẹnubodè Amẹ́ríkà sí Mexico bíi ibi tí nǹkan kò ti fararọ, kíkéde oríkò àwọn tó ń ta egbògi olóró bíi ìgbéṣùmọ̀mí àti fífi orí ji àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìjà gboro ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kìíní.
Lásìkò ìpolongo ìbò, Trump ṣèlérí láti lé ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò wáyé rí kúrò ní Amẹ́ríkà, mú àdínkù bá iye owó orí, gbé owó orí ọjà tuntun jáde fáwọn ọjọ́ tí wọ́n ń kó wọ orílẹ̀ èdè náà láti ilẹ̀ òkèrè.
Kí àwọn ìlérí rẹ̀ yìí tó le wá sí ìmúṣẹ, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Republican ló gbọ́dọ̀ pọ̀ jùlọ ní ilé aṣòfin àtàwọn Adájọ́ ní ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ṣùgbọ́n àwọn nnkan wà tó lè ṣe ìdíwọ́ láti mú àlá Trump wá sí ìmúṣẹ.
Àwọn nǹkan mẹ́fà rèé táwọn onímọ̀ kà kalẹ̀ pé ó le jẹ́ ìpèníjà fún Trump.
1. Àwọn aṣòfin

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Republican ló pọ̀ jùlọ ní àwọn ilé aṣòfin méjèèjì lóòótọ́ àmọ́ ipa tí wọ́n le ní kéré púpọ̀.
Ní ilé aṣojúṣòfin, aṣòfin 220 ló jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Republican, tí ẹgbẹ́ òṣèlú Democrat sì ní 215. Àwọn aṣòfin Republican méjì ló ti kọ̀wé fipò wọn sílẹ̀ tí ìrètí sì wà pé aṣòfin mìíràn yóò tún kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ èyí tí yóò sọ ọmọ ẹgbẹ́ wọn di 217 nílé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Mark Peterson, onímọ̀ nípa ètò, òfin àti òṣèlú ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of California, Los Angeles sọ fún BBC Mundo pé iye táwọn aṣòfin Republican fi ju àwọn Democrats lọ yìí ni èyí tó kéré jùlọ lóde òní.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn aṣòfin Republican yìí kìí se gbogbo ìgbà ni ẹnu wọn yóò máa kò lórí gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tó bá mú awuyewuye dání.
Ní ilé aṣòfin àgbà, àwọn aṣòfin ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Republican ni iye wọn jẹ́ 53 nígbà tí Democrats sì ní 47. Èyí túmọ̀ sí pé wọn ò ní aṣòfin ọgọ́ta tí wọ́n nílò láti buwọ́lu àbá di òfin.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Peterson ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin kan fàyè gba aṣòfin 51 láti buwọ́lu àbá síbẹ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Democrats le ṣe ìdádúrò ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan fún wọn.
Ọ̀jọ̀gbọ́n náà wòye pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Trump ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ nígbà sáà rẹ̀ àkọ́kọ́, òfin tó rí ṣe lọ́dún méjì àkọ́kọ́ ìgbà náà kò ju mímú àdínkù bá owó orí lọ.
2. Ẹ̀ka ètò ìdájọ́ tó dá dúró

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Supreme Court" ni ilé ẹjọ́ to ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, tó sì jẹ́ pé Ààrẹ ló máa ń yan Adájọ́ fún wọn tó bá ti ṣí sílẹ̀.
Mẹ́fà nínú àwọn Adájọ́ ilé ẹjọ́ náà ló jẹ́ "conservatives" tó sì jẹ́ pé Trump ló yàn mẹ́ta sípò nínú wọn nígbà sáà rẹ̀ àkọ́kọ́.
Ṣùgbọ́n èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ máa gbé kalẹ̀ lórí ìjọba Trump ló máa ṣègbè lẹ́yìn rẹ̀.
Lọ́dún 2022, àwọn Adájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ tako àwọn ètò ìjọba àpapọ̀ kan lórí oyún ṣíṣẹ́, lára àwọn ìlérí Trump níbi ìpolongo ìbò lọ́dún 2016.
Síbẹ̀, àwọn Adájọ́ náà ṣe àtìlẹyìn fún ìjọba àpapọ̀ lórí àwọn òfin mìíràn bíi ti "Affordable Care Act" èyí tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Obamacare àti ààbò fáwọn LGBT ní àwọn ibi iṣẹ́.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bákan náà ni ilé ẹjọ́ náà tún lòdì sí ṣíṣe àyípadà èsì ìdìbò ọdún 2020 àti fífi òpin sí ètò Daca, tó dá ààbò bo àwọn tó wọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà lọ́nà àìtọ́ nígbà tí wọ́n wà ní ọmọdé.
Yàtọ̀ sí àwọn Adájọ́ "Supreme Court", gẹ́gẹ́ bí ìwádìí Pew Research Center ṣe fi múlẹ̀, ìdá ọgọ́ta àwọn Adájọ́ ní ẹkùn kọ̀ọ̀kan ló jẹ́ pé Ààrẹ Democrats ló yàn wọ́n, tó sì jẹ́ pé ìdá ogójì ni Ààrẹ Republican yàn.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Peterson ní òfin ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ló máa ń de àwọn Adájọ́ àti pé ẹ̀ka ètò ìdájọ́ jẹ́ èyí tó ṣe pàtàkì sí ìṣèjọba, tó sì dá dúró.
3. Ìpínlẹ̀ àtàwọn ìjọba ìbílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìwé òfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà àtúnṣe kẹwàá fi ọ̀pọ̀ agbára sọ́wọ́ àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ pàápàá lórí ètò ààbò, ìlera, ẹ̀kọ́, òfin ìwà ọ̀daràn, òṣìṣẹ́ àti òfin lórí dúkìá.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Peterson gbàgbọ́ pé Democrats máa lo àwọn agbára yìí láti tako ìṣèjọba Trump làwọn ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀.
Ó wòye p ní California tí òun ń gbé, tó tóbi jù lọ ní Amẹ́ríkà kìí ṣe èyí tó fara ti ẹgbẹ́ òṣèlú kan pàtó.
Ó ní ìrètí pé California àtàwọn ìpínlẹ̀ míì yóò ṣe nǹkan tí wọ́n bá fẹ́ lọ́wọ́ ara wọn láì bìkítà ìṣèjọba Trump tàbí kí wọ́n jẹ́ ìpèníjà fún Trump báwọn orílẹ̀ èdè bíi Texas ṣe jẹ́ ìpèníjà fún Biden àti Obama lásìkò ìṣèjọba wọn.
Ní báyìí, àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́tàlélógún ló ní gómìnà tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Democrats.
Lára àwọn èròńgbà Trump, bíi lílé ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò ní Amẹ́ríkà ló nílò àtìlẹyìn àwọn ìjọba lẹ́sẹ̀ kùkú, tó sì ṣeéṣe kí wọ́n má wà á sí ìmúṣẹ táwọn ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìbílẹ̀ bá takòó. Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú àti ìpínlẹ̀ ni wọ́n yí kéde ara wọn bíi ààyè fáwọn tó ń gbé Amẹ́ríkà lọ́nà àìtọ́, èyí tó tako ìpinnu ìjọba àpapọ̀.
4. Òfin iṣẹ́ ìjọba Amẹ́ríkà
Lásìkò sáà àkọ́kọ́ Donald Trump, Republicans kọminú pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan kò jẹ́ kí àwọn rí iṣẹ́ ṣe bó ti yẹ.
Nígbà tó máa fi parí ìṣèjọba rẹ̀ nígbà náà, Trump buwọ́lu àṣẹ kan láti dá ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan dúró lẹ́nu iṣẹ́, kó sì fi àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ rọ́pò wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ààrẹ àná, Joe Biden ṣe àyípadà òfin náà àmọ́ Trump tún ṣe òfin tó farapa jọ bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ kìíní tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní sáà kejì rẹ̀ yìí. Bákan náà ló ní kí gbogbo àwọn tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba tó ń ṣiṣẹ́ láti ilé padà sẹ́nu iṣẹ́ wọn.
Wọ́n ti ń ṣe àkójọ orúkọ àwọn tó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí wọ́n le fi rọ́pò àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí wọ́n bá lé kúrò lẹ́nu iṣẹ́.
Ẹgbẹ́ kan, National Treasury Employees Union tí pé òfin tuntun tí Trump ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe náà lẹ́jọ́.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Peterson ní òun ń retí káwọn olóṣèlú, òfin àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tako òfin Trump náà.
5. Ẹgbẹ́ Ajàfẹ́tọ̀ọ́ àti iléeṣẹ́ ìròyìn
Ó ṣeéṣe kí Trump kojú àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn àtàwọn ẹgbẹ́ Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn bíi American Civil Liberties Union (ACLU).
Pẹ̀lú ọmọ ẹgbẹ́ 1.7m, ACLU ní àwọn máa gbìyànjú láti dènà Trump, kó má rí àwọn ìlérí rẹ̀ múṣẹ. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ẹbí ni ìpínyà máa bá, mú ìlera àwọn obìnrin wà nínú ewu àti pé ìjọba àpapọ̀ yóò máa tako àwọn tó bá fẹ́ ṣe ìwọ́de àtàwọn tó bá lòdì sí ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀.
Lọ́jọ́ Ajé ni wọ́n pè ẹjọ́ tako òfin fífún ọmọ tí wọ́n bá bí sí Amẹ́ríkà ni ìwé ìgbélùú, èyí tí Trump fòpin sí.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lára àwọn tó jẹ́ alátakò Trump ń kọminú lórí ipò àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn pàápàá bí Washington Post àti LA Times ṣe ti kéde pé àwọn kò ní máa ṣe àgbéjáde olùdíje táwọn kan bá faramọ́ síta mọ́ ṣáájú ètò ìdìbò.
Olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Democrats, Kamala Harris ni ìrètí wà pé wọ́n máa jàn lóǹtẹ̀.
Olùdásílẹ̀ The Post, olùdásílẹ̀ Amazon àti bàbá olówó Jeff Bezos ní ìpinnu yìí wáyé látàrí báwọn kan ṣe ti ń fẹ̀sùn kàn pé àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ń figbá kan bọ̀kan nínú.
6. Àtìlẹyìn tó pọ̀ jùlọ
Ààrẹ Trump yóò tún máa ṣe àgbéyẹ̀wò ohun táwọn èèyàn bá ń fẹ́. Ọ̀jọ̀gbọ́n Peterson wòye pé ìbò tó gbé Trump kò ju idà kan lọ tí a bá bí èrò ṣe dìbò fún wọn.
Ó ní ó túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn tó dìbò fún Trump ló ṣe àtìlẹyìn fún àwọn ètò rẹ̀.
Àwọn tó jẹ́ ọmọ Republican wà nínú wọn tó jẹ́ pé wọn kò fẹ́ràn Trump àmọ́ tí wọ́n ń fẹ́ àdínkù nínú owó orí tí wọ́n ń ṣàn àti pé àwọn mìíràn ríi gẹ́gẹ́ bí ẹni tó le kojú ọ̀wọ́n gógó to ń bá orílẹ̀ èdè fínra.
Ọ̀jọ̀gbọ́n náà ní àpapọ̀ àwọn nǹkan yìí le mú kí ìjọba ṣe àtúngbéyẹ̀wò àwọn ètò rẹ̀ láti ri pé àwọn tó dìbò fún kò kabaamọ àti kí ẹgbẹ́ òṣèlú Republican le rí ìyànsípò níbi ètò ìdìbò tó máa wáyé láàárín ọdún 2026.

Oríṣun àwòrán, Getty
Bákan náà ni àwọn onímọ̀ míì wòye pé ìlérí Trump láti mú ìgboro bá ètò ọrọ̀ ajé àti mímú àdínkù bá ọ̀wọ́n gógó ni àwọn ètò mìíràn, bíi lílé ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò ní Amẹ́ríkà àti fífi owó orí lé àwọn ọjà kan, le ṣàkóbá fún.
Onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé, John Cochrane tí ilé ẹ̀kọ́ Hoover Institution ní ìbéèrè tó ṣe kókó báyìí ni bí Trump yóò ṣe wá paná ìṣòro lórí ètò ọrọ̀ ajé àti ọ̀rọ̀ wíwá ojútùú sáwọn ẹnubodè àti orogún US àti China.
"Gbogbo igun kò lè rí nǹkan tí wọ́n ń fẹ́, èyí ni kò ní jẹ́ ka lè mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, " Cochrane sọ.















