Ohun ta a mọ̀ nípa ọkùnrin tó ṣíná bolè fún èèyàn 11 tó sì tún pa ara rẹ̀ níta ilé ẹ̀kọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkunrin kan ti wọn ko ti kede orukọ rẹ lo ṣadede yawọ ile ẹkọ agba kan, to si sina bọlẹ fun eeyan mẹwaa ko to di pe o ṣekupa ara rẹ.
"A n gbọ ariwo rẹ bi o ṣe tẹlẹ lati inu yara ikawe wa", Hellen Warme, ẹni ọdun marundinlogoji, akẹkọọ nipa eto ile ilera ṣalaye.
"A gbọ iro ibọn, to n dun lera wọn, ti ẹru si bẹrẹ si ni ba wa. Olukọ wa pariwo: "Ẹ ti ilẹkun, ẹ sa pamọ," O ṣo fun ileeṣẹ momaworan Sweden.
Fọnran to jade lori ayelujara ṣafihan bi awọn akẹkọọ se n sa si abẹ tabili wọn lẹyin ti wọn gboro ibọn.
Iṣẹlẹ naa waye ni ile ẹkọ agba Risbergska lorilẹede Sweden.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọrọ nipa afurasi apaniyan naa, lori bi o ṣe ṣekupa eeyan mọkanla to fi mọ ara rẹ ni ilu Orebro.
Afurasi yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ko da mọ, ti wọn si gbagbọ pe o da se iṣẹ laabi naa ni.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni afurasi naa ko ibasepọ kan kan pẹlu ẹgbẹ okunkun
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa fi di rẹ mulẹ pe awọn ko gbagbọ pe iṣẹlẹ ni ọwọ igbesunami ninu.
Wọn ri oku afurasi naa ni agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye , to si farahan pe ni se lo ṣe ku pa ara rẹ.
Awọn alaṣẹ eleto ilera ni obinrin mẹta ati okunrin meji wa ni ẹsẹ kan ẹsẹ kan ọrun lẹyin ti wọn se iṣẹ abẹ fun.
Ọkan ninu mọlẹbi afurasi naa aṣo fun awọn akọroyin pe afurasi ko ni ibasepọ pupọ pẹlu mọlẹbi rẹ, to si padanu iṣẹ rẹ fun igba diẹ bayii..
"Nigba to wa ni ọmọde, o da yatọ. O ṣe daada ni ile ẹkọ ṣugbọn bibi ọdun diẹ sẹyin fẹ nira diẹ ffun."















