Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá yóò wáyé ní Nàìjíríà láàrín óṣù karùn ún àti ìkẹfà - NiMET

Ọkọ bọọsi akero kan ninu ẹkun omi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n mojuto ọrọ oju ọjọ lorilẹede Naijiria, NIMet ti kede pe ojo arọrọda to ṣeeṣe ko ja si ẹkun omi o waye loṣu karun ati ikẹfa lorilẹede Naijiria.

Eyi jẹyọ ninu ẹkunrẹrẹ iroyin iwadii oju ọjọ fun ọdun 2025 eyi ti ajọ naa gbe jade, ninu eyi ti wọn ti sọ igba ti ojo ṣeeṣe ko bẹrẹ, igba ti ọwọja ojo yoo le ju ati igba to ṣeeṣe ki ojo da ni ọdun 2025.

Iwe akọsilẹ naa eyi ti minisita fun igbokegbodo ọkọ ofurufu lorilẹede Naijiria, Amofinagba Festus Keyamo fi sita tun ṣalaye awọn ipinlẹ ti iji lile yoo ti waye.

Amọṣa iwe akọsilẹ iwadii naa ko ṣai sọ awọn ipinlẹ kan ti yoo foju wina iji lile ati arọrọda ojo lọdun 2025.

Oru yoo tun gbilẹ lawọn akoko kan lọsan ati loru

Ajọ NiMET tun sọrọ pe ọwọ ojo yoo tunbọ pọ sii laarin oṣu karun un si ikẹfa ọdun 2025 lorilẹede Naijiria. O ni eyi yoo gbilẹ lawọn ilu to wa lẹsẹ odo lorilẹede Naijiria.

Ajọ naa ni eyi le fa ẹkun omi lawọn agbegbe ati ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria lasiko naa.

Bakan naa ni wọn sọ pe oru yoo mu kọja bo ṣe yẹ kaakiri orilẹede Naijiria. Ajọ naa woye pe ooru yoo tubọ mu lọsan ati loru laarin oṣu kinni, oṣu keji, ikẹta ati oṣu karun un.

Amọṣa wọn ni oju ọjọ yoo tutu loṣu kẹrin ọdun 2025, ṣugbọn oju ọjọ yoo mooru lpọ ipinlẹ lapa oke ọya Naijiria.

Awọn ipinlẹ ti ọda ojo yoo ti ṣokunfa idaduro akoko ikore

Ọmọde kan ninu agbara ojo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ NiMET woye pe awọn ipinlẹ kan wa lẹkun aringbungbun ariwa ati ni apa ariwa Naijiria ti ojo yoo ti pẹ ko to bẹrẹ. Awọn ipinlẹ naa niwọnyii:

Plateau

Kaduna,

Niger,

Benue,

Nasarawa,

Taraba,

Adamawa,

Kwara.

Awọn ipinlẹ ti ojo yoo ti tete bẹrẹ

Awọn eeyan ninu ẹkun omi kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa ni ajọ ọhun tun ni awọn ipinlẹ kan, paapaajulọ lẹkun gusu orilẹede Naijiria yoo tete ri ọwara ojo lọdun 2025. Awọn ipinlẹ naa niwọnyii:

Delta,

Bayelsa,

Rivers,

Anambra,

Oyo,

Ogun,

Osun,

Ondo,

Lagos,

Edo,

Enugu,

Imo,

Ebonyi.

Awọn ipinlẹ ti ojo yoo ti tete da

Ẹkun omi ni agbegbe kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ NiMET tun ṣalaye pe ojo yoo tete da lawọn ipinlẹ bii:

Zamfara,

Katsina,

Kano,

Kaduna,

Jigawa,

Plateau,

Bauchi,

Borno,

Yobe,

Adamawa,

Taraba,

Niger,

Kwara,

Kogi,

FCT,

Ekiti,

Ondo

Awọn ipinlẹ ti ojo yoo ti rọ pẹ daadaa

Nigba ti ajọ naa tun woye pe lawọn ipinlẹ miran, ọwọja ojo yoo rọ pẹ, yoo si ṣe diẹ ki ọgbẹlẹ to wọle nibẹ. Awọn ipinlẹ ti ọrọ yii kan naa ni:

Kaduna,

Nasarawa,

Benue,

Lagos,

Kwara,

Taraba,

Oyo,

Ogun,

Cross River,

Delta,

Akwa Ibom,

Ebonyi,

Anambra,

Enugu

Arakunrin kan ninu ẹkun omi niwaju ile kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Umar Sale Anka to jẹ kan lara ọmọ ajọ to n ri si idaabobo ayika lorilẹede Naijiria, ṣalaye pe awọn asọtẹlẹ oju ọjọ ti ajọ NiMET fi sita yii yẹ ko le awọn gomina ipinlẹ lere lna ati tete gbe igbesẹ to ba yẹ lati dena awọn iṣẹlẹ ajalu oju j lọdun 2025.

O ni pẹlu ohun ti wọn sọ kalẹ yii, o fihan pe o ṣeeṣe ki ọda ojo ati ọgbẹlẹ nitori aisi ọjo lasiko.

"O yẹ ki eto ọgbin tete waye lawọn agbegbe ti ojo yoo ti tete da."