Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógún ní Naijiria fọwọ́ sí ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá agbègbè

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force
Gomina mẹrindinlogun ni Naijiria lo ti fi atilẹyin wọn han fun idasilẹ ọlọpaa agbegbe ni Naijiria.
Nibi ipade ilu kan l’Abuja ni wọn ti sọ pe o yẹ ki atunṣe wa si ofin Naijiria, eyii ti yoo faye gba idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ.
Ọrọ yii o jẹ nibni ipade ilu naa to waye nile ijọba, Aso Rock, niluu Abuja, ti igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima tukọ rẹ.
Agbẹnusọ igbakeji Aarẹ, Stanley Nkwocha lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan lẹyin ipade ọhun lọjọbọ.
Nkwocha sọ ninu atẹjade naa pe ijọba apapọ ṣi n reti iroyin lati ọdọ ipinlẹ ogun nipa erongba wọn lori ọlọpaa agbegbe.
Atẹjade ọhun ni “Akọwe igbimọ ijọba sọrọ lorukọ awọn ipinlẹ to nifẹ si ọlọpaa agbegbe.
“A ti gbọ lati ọdọ awọn ipinlẹ mẹrindilogun lori idasilẹ ọlọpaa agbegbe, ipinlẹ ogun ni ko tii fi ohun ranṣẹ si wa.”
Gbogbo ipinlẹ ni Naijiria lo ti sọ pe awọn n fẹ ọlọpaa ipinlẹ.”
Ti ẹ ko ba gbabe, ẹnu ọjọ mẹta yii ni iṣẹlẹ ijinigbe bẹrẹ si n peleke si ni Naijiria ti ọpọ si gbagbọ iṣẹ ọwọ awọn Fulani darandaran ni.
Apapọ iye eeyan ti awọn agbebọn ti ji gbe lẹnu lọlọ yii ni ipinlẹ Kaduna, Sokoto ati Borno ko din ni 495.
Oniruru ijinigbe naa atawọn ipenija eto abo mii lo ṣokunfa ipe fun idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun.














