Àìsàn òtútù igbáàyà ló mú Pope Francis nínú ẹ̀dọ̀fóró méjèèjì
Pope Francis ni wọn ni o ti lugbadi aisan otutu aya to n da ẹdọforo mejeji rẹ laamu, ti ipo to wa si lagbara bayii.
Ẹni ọdun mejidinlaadọrun ọhun lo ti n ba aisan yii finra fun igba diẹ bayii, to si le ni ọsẹ kan to ti wa ni ile iwosan Rome Gemelli.
"Ayẹwo igbaya ti a se fun ẹni ọwọ naa fi han pe aisan otutu aya, to si nilo itọju ni kiakia," Vatican ṣalaye.
O ni, ayẹwo X-ray ati ipo ti Pope wa fihan pe aisan naa lagbara."
Pẹlu gbogbo eyi, Vatican ni Pope si wa ni erogba gida, to si n lo gbogbo asiko rẹ lojumọ lati ka iwe, sinmi ati gbigba adura.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Pope Francis wa ransẹ ikinni si awọn alatilẹyin rẹ, to si rọ wọn pe ki wọn ma gba adura fun oun.
Saaju ki o to lọ si ile iwosan ni ọsẹo to kọja, Pope ti ni ṣafihan awọn apẹẹrẹ aisan, to si ni lati sọ fun awọn ọmọ lẹyin rẹ pe ki wọn ba ka iwe ni awọn ode ti wọn ti kesi pe ko wa sọrọ.
O yẹ ki Pope lewaju awọn apejọ kan fun ayẹyẹ 2025 Catholic ṣugbọn gbogbo eyi ni Pope ti wọgile nitori ipo ti ilera rẹ wa.
Ni ọjọ Aje, Vatican ni awọn dokita ti parọ oogun fun Pope fun igbakeji lati gbe ogun ti aisan naa.
Aisan yii lo ti n ba Pope finra fun igba pipẹ, ti wọn si ti yọ ọkan ninu apa ẹdọ aforo rẹ nigba to wa ni ẹni ọdun mọkanlelogun.
Lasiko ọdun mejila rẹ gẹgẹ bii olori ijọ aguda, Pope to wa lati orilẹede Argentina lo ti dero ile iwosan fun ọpọ igba paapa ninu oṣu kẹta ọdun 2023 nigba to lo ọjọ mẹta ni ile iwosan fun aisan bronchitis.
















