Kí ni Portable ṣe tí àwọn ẹ̀gbọ́n àdúgbò kan fi ìbọn wá a lọ sí ọ́fíìsì rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, X/@TeniolaYBNL
Gbajugbaja olorin takasufe, Habib Okikiola, ẹni ti ọpọ mọ si Portable ni ori ti ko yọ lọwọ awọn eeyan kan ti wọn furasi pe wọn fẹ gba ẹmi rẹ.
Ninu fọnran kan to lu sita lori ayelujara, ọkunrin kan ni ọwọ tẹ pẹlu ti n saapa lati se ijamba fun Portable ni agbegbe Ota nipinlẹ Ogun.
Ibẹruboju bọ Portable, to n pariwo ninu fọnran pe awọn eeyan kan fẹ gba ẹmi oun.
Ọpọ ero lo kun lori ọkunrin ti ko wọ ẹwu aṣọ ninu fọnran, ti wọn si ka ibọn mọ lọwọ.
Gẹgẹ bii iroyin to tẹ lọwọ se ṣalaye ikọlu si Portable yii waye lasiko to n lọ si ọfisi rẹ, ti o si jọla awọn eeyan ti wọn wa ni adugbo rẹ, ti wọn yọ ninu ewu naa.
Bẹẹ ba gbagbe, ni oṣu kẹjọ ọdun yii ni Portable fi ẹsun kan awọn ẹgbọn adugbo pe wọn n dunkooko mọ oun.
Ninu fọnran ti ọdọmọkunrin ti wọn tun n pe ni Idaamu Adugbo naa gbe sita, o sọ pe ibi toun ti lọ kọrin lagbegbe Iju-Ishaga nipinlẹ Eko ni awọn eeyan naa ti wa lati da ibẹ ru.
O ni ọrẹ oun kan to n ta mọto loun lọ ba ṣe ayẹyẹ, toun si tun kọrin nibẹ pẹlu, ko to di pe wọn kọlu awọn.
Portable ni niṣe lọrọ di ẹni ori yọ, o di ile, toun si sa asala fun ẹmi ara oun, ṣugbọn to loun ko tii ri awọn ọmọ ẹyin oun yooku.
Bakan naa lo sọ pe kii ṣe pe awọn ‘Ẹgbọn Adugbo’ naa lu awọn nikan, bi ko ṣe pe wọn tun ja ẹgba ọrun oun ati awọn dukia miran to jẹ olowo iyebiye gba.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ko ti sọrọ lori iṣẹlẹ yii
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















