À ń retí kí wọ́n fi Bobo B sílẹ̀ ní ilé ìwòsàn láàrín ọ̀sẹ̀ kan ní mo gbọ́ ìròyìn ikú rẹ̀ - Mr Latin, ààrẹ ẹgbẹ́ òṣèré TAMPAN

Bobo B
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọlọpọ awọn oṣere tiata lo pejọ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun Mudashiru Olabiyi, ẹni ti ọpọ eeyan mọ si Bobo B, to di oloogbe.

Lara awọn to pejọ sibi adura Fridau ọjọ kẹjọ lẹyin iku Mudashiru ni Bolaji ‘Mr Latin’ Amusan, to jẹ alaga apapọ ẹgbẹ awọn oṣere tiatia, TAMPAN.

Eto Adura ọlọjọ kẹjọ fun oloogbe oṣerekunrin Mudashiru Olabiyi lo waye ni ile rẹ to wa ni agbegbe Orisumbare Eku, to wa lagbegbe Amuloko niluu Ibadan.

Ọsẹ to kọja ni iroyin ipapoda oloogbe naa lu sita lori ayelujara.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, alaga ẹgbẹ oṣere, mr Latin sọ pe ibanuje ọkan lọ jẹ nigbati iku Mudashiru Olabiyi to ohun leti.

Latin tẹsiwaju pe ipo akọwe agba ni oloogbe Mudashiru dimu ninu ẹgbẹ awọn oṣere ṣaaju ipapoda rẹ.

O ni Mudashiru da bii afaara laarin awọn oṣere tiata agba ati awọn ọdọ to ṣẹṣẹ n bọ ni.

Mr Latin wa fi oloogbe naa we Baba, ọrẹ, alabaṣiṣẹ ati alajọṣe.

O tẹnumọ pe ẹgbẹ oṣere tiata ni yoo mo iku Bobo B lara nitori ipa ribiribi to ti ko ninu ere tiata nigba aye rẹ.

Mudashiru Olabiyi lo dagbere faye lọṣe to kọja lẹyin ti wọn ṣe itọju rẹ latari aisan kan to n ba finra, ọmọ ọdun mẹrindinlaadorin ni Bobo B ko to jade laye.

Òní ni àdúrà ìsìnkú ojọ́ kẹjọ́ fún gbajúmọ̀ òṣèré, Mudashiru Olabiyi (BOBO B)

Bọbọ̀ B

Oríṣun àwòrán, others

Oni ni awọn mọlẹbi oloogbe Mudashiru Ayobami Olabiyi yoo se adura ọjọ fun un niluu Ibadan.

Ọsẹ to kọja ni iroyin nipa ipapoda oloogbe naa lu sita ori ayelujara.

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, agba oṣere n ni, Toyin Adegbola, tawọn eeyan mọ si Aṣẹwo to re London sọ pe oloogbe naa lọ sinmi ni tori o ti to bi oṣu meji to ti n ṣaisan.

Arabinrin Adegbola ṣalaye pe Ọgbẹni Olabiyi to doloogbe naa ni arun itọ ṣuga, ṣugbọn ko tete fura.

Aworan eto fidau fun Bobo B

Oríṣun àwòrán, others

Bakan naa, awọn aburo oloogbe ati ọmọ rẹ ni Ayobami Olabiyi sẹsẹ jẹ oye Baalẹ ni oko wọn ni, eyi ti wọn n pe ni Alágùnsà.

Koda, wọn ni awọ̀n n palẹ mọ fun ayẹyẹ iwoye baalẹ naa ni Ọlọjọ de ba.

Kabiru Olabiyi tii se aburo oloogbe ni oni Ọjọ Ẹti gan ni wọn n si Mọsalasi ti Ayobami Olabiyi ba wọn gba lati ọdọ awọn Saudia, ti wọn wa kọ si oko wọn naa.

"O se ni laanu pe Ayobami Olabiyi ko si laye lati peju sibi ayẹyẹ sisi Mọsalasi naa, ka si tun wuye Baalẹ Alagunsa to jẹ.

Baba wa wulo pupọ nigba aye rẹ, o wulo fun ẹbi, idile iya ati baba, o dara laarin awọn ti wọn jọ n sisẹ tiata, to si tun wulo laarin ilu ati awujọ.

Abiamọ tootọ ni, amọ ko duro jẹun ọmọ, oun ti Ọlọrun se fun yẹ ko pọ ju bayi lọ"