Ìdádúró dé bá ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin lẹ́yìn tí rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn aṣòfin

Ghana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Idaduro ti de ba ile igbimọ aṣofin orilẹede Ghana fun igba diẹ.

Igbeṣe yii lo waye lẹyin rogbofiyan to bẹ silẹ laarin awọn aṣofin ẹgbẹ oṣelu to wa lori oye atawọn ọmọ ẹgbẹ alatako.

Rogbodiyan naa bẹrẹ lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ alatako gba awọn aga to wa ninu ile naa, eyii to mu ki awọn ọmọ ẹgbẹ to wa lori oye binu jade.

Ibẹrẹ ọrọ ọhun ko ṣẹyin idajọ ilẹ ẹjọ to ga julọ nilẹ naa nipa awọn aṣofin mẹrin kan ti wọn fi ẹgbẹ oṣelu wọn silẹ.

Ṣaaju ni olori ile naa ti kọkọ kede pe aye awọn to fi ẹgbẹ oṣelu wọn silẹ ti ṣofo amọ ile ẹjọ wọgile aṣẹ aṣẹ ọhun.

Nigba ti wọn pade lonii ninu ile aṣọfin naa lati mọ ohun ti olori ile yoo sọ nipa idajọ naa ni rugudu bẹ silẹ nibẹ ti wọn ko si le gbe igbesẹ kankan.

Awọn aworan lati ile naa ṣafihan ọpọ awọn alatilẹyin awọn oloṣelu nita amọ awọn agbofinro tu wọn kan ki wọn to da wahala silẹ nibẹ.

Ki ọgọrọ ero naa to de ni wọn ti kọkọ ko awọn ologun lọ sibẹ lọna ati dena rogbodiyan to ṣeeṣe ko waye.

Wayi o, awọn ọmọ ẹgbẹ to pọju ninu ile naa ti sọ pe awọn ti ṣẹtan lati pada bẹrẹ ijoko ti olori ile ba paṣẹ bẹẹ.