Ohun tí a bá bọ̀ nílé ẹjọ́ lónìí réè lórí ẹjọ́ tí àwọn gómìnà pè tako ìdásílẹ̀ EFCC

Oríṣun àwòrán, EFCC/BBC
Awọn gomina Nàìjíríà àti ìjọba apapọ ti gbe ara wọn sile ẹjọ́ t ga julọ ni Naijiria, eyii to wa niluu Abuja lori ẹsun pe ofin ti wọn fi da ajọ EFCC ati ICPC ko tẹle ìlànà ofin ọdún 1999.
Awọn gomina ni ko yẹ ki ofin yii le mu awọn ìpínlẹ̀ tó wà lorilẹede Naijiria.
Adajọ meje lo joko nile ẹjọ lati gbọ ẹjọ ọhun labẹ adari adajọ agba Uwani Abba-Aji.
Awọn gomina ni o yẹ ki awọn ile igbimọ aṣofin ti ipinlẹ le jiroro lori abadofin ọhun, ki wọn to gbe lọ sile igbimọ aṣoju-ṣofin ilu Abuja.
Wọn tẹsiwaju pe ofin ajọ iṣọkan agbaye, UN, ni Nàìjíría fi da ajọ EFCC ati ICPC silẹ, ti ko si ni ṣe pẹ̀lú ofin orilẹede Naijiria.
Lara awọn ipinlẹ to gbe ìjọba apapọ lọ sile ẹjọ́ giga ọhun ni ipinlẹ Ondo, Ogun, Ọsun, Nasarawa, Katsina, Sokoto, Jigawa, Enugu, Benue, Anambra, Plateau, Cross River ati Niger.
lasiko ti igbẹjọ ń lọ lọwọ ni awọn ipinlẹ mẹ́ta yọ ara wọn kuro ninu eto ipẹjọ yii.
Awọn ipinlẹ naa ni Ebonyi, Taraba àti Adamawa, ti wọn si sọ pe àwọn ko ṣẹjọ mọ.
Wayi o, adajọ ti sún ètò ìdájọ́ siwaju.
Awọn adajọ naa ni awọn yóò kan sì àwọn agbẹjọro ijoba ati agbẹjọro awọn gomina lori ọjọ́ tí àwọn yóò gbeb idajọ kalẹ lori ẹjọ ti awọn onibara wọn pe.
Wọ́n tẹ̀síwájú pe ijọba ko lẹtọọ lati maa sọ bi àwọn ipinlẹ yoo ṣe maa na owo wọn.
Ṣé ìdásílẹ̀ EFCC bá òfin mu bí? Òní ni ilé ẹjọ́ tó gà jùlọ ní Nàìjíríà yòó gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹjọ́ t'áwọn gómìnà kan pè takò ó

Oríṣun àwòrán, Getty image/ EFCC
Oni, ọjọ kejilelogun oṣu kẹwaa ọdun 2024 ni idajọ yoo waye lori ẹjọ kan ti awọn gomina mẹrindinlogun pe tako ajọ Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) to n ri si ajẹbanu lorilẹede Naijiria.
Awọn gomina ati EFCC paapaa n foju sọna lati mọ ibi ti ẹjọ naa yo wo si lonii, boya EFCC lẹtọọ labẹ ofin tabi idasilẹ wọn lodi s’ofin bi awọn gomina yii ṣe sọ.
Ṣaaju ni awọn gomina naa ti tako ofin to da EFCC silẹ, wọn ni agbẹkalẹ EFCC ko tẹle ofin, nitori wọn yọ abala kejila ofin Naijiria ti ọdun 1999 silẹ lai tẹle.
Bakan naa ni awọn gomina wọnyi tun sọ pe labẹ ofin, o ye ki wọn jẹ ki awọn fọwọ si idasilẹ EFCC ki wọn too sọ ọ di ajọ labẹ ofin, eyi ti ko ṣẹlẹ.
Wọn ni EFCC ko lẹtọọ lati ṣiṣẹ ni ipinlẹ ti ko fọwọ si idasilẹ rẹ lati ibẹrẹ.
Ati pe ẹgbẹkẹgbẹ ti wọn ba ṣe bayii da silẹ, ko ni orukọ meji ju pe ko ba ofin mu lọ.
Ijọba ipinlẹ Kogi lo kọkọ bẹrẹ ẹjọ itako EFCC yii, awọn yooku to kun wọn lọwọ ni Ondo, Edo, Oyo, Ogun,Nasarawa,Kebbi,Katsina,Sokoto,Jigawa, Enugu, Benue, Anambra, Plateau, Cross-River ati Niger.
Kí ni EFCC wí?
EFCC ni tiẹ sọ pe ijọniloju gbaa ni iru ẹjọ ti awọn gomina yii pe, wọn ni awọn ti ida iṣẹ awọn n ge ni wọn n pariwo.
Adari ẹka to n ri si ọrọ to ba kan EFCC, Wilson Uwujaren, sọ eyi nibi ifọrọwerọ kan to ṣe lorii tẹlifiṣam Channels lọjọ Aje ọsẹ yii.
Uwujaren sọ pe idasilẹ EFCC ko lodi si ofin nibi kankan, nitori o wa fun gbigbe ogun ti iwa ajẹbanu ni.
“ O jọ wa loju gan-an pe iru nnkan bayii n ṣẹlẹ.
O yẹ kawọn ọmọ Naijiria fi oju ṣunnukun wo ọrọ yii, nitori emi o mọ bi orilẹede yii yoo ṣe daa lai si EFCC, ta a ba n wo iru iṣoro ajẹbanu to n ṣẹlẹ.
“ O daamu ọkan mi gan-an, pe pẹlu iru iṣoro magomaog to wa ni Naijiria yii, awọn kan tun ṣi n lọ si kootu lati tako idasilẹ EFCC. “
Uwarejen lo ṣalaye bẹẹ.
O ni awọn gomina yii fẹẹ da oju otitọ delẹ ni, wọn fẹẹ yi ajọ naa lọkan pada nipa iṣẹ ifọlumọ ti wọn n ṣe.
“Ṣe awọn eeyan ti wọn nifẹẹ si akoyawọ ati otitọ yoo fẹẹ pa EFCC bi, ẹ jẹ ki n sọ ọ bẹẹ yẹn, nitori ero wọn ni lati pa EFCC.
‘’Wọn ko fẹẹ jiyin ohun ti wọn n ṣe, wọn ko fẹ akoyawọ nipinlẹ wọn.’’
Bẹẹ ni Wilson Uwajaren wi.
BBC Yoruba yoo mu abajade igbẹjọ naa wa fun yin bo ba ṣe lọ nile-ẹjọ














