EFCC tún wọ́ gómínà Kware tẹ́lẹ̀, Abdulfatah Ahmed, padà lọ sílé-ẹjọ́

Aworan Abdulfatah Ahmed

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ to n gbe ogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC , ẹka ipinlẹ Kwara ti wọ gomina tẹlẹ nipinlẹ Kwara, Abdulfatah Ahmed ati kọmisana fun eto isuna lasiko ijọba rẹ, Ademola Banu lọ si ile ẹjọ.

Ẹsun mẹrinla ni EFCC ka si Ahmed ati Banu lẹṣẹ, to fi mọ siṣe owo ilu to le ni bilọnu marun un naira mọkumọku niwaju onidajọ Mahmud Abdulgafar ni ile ẹjọ giga to n jokoo niluu Ilorin.

Wiwọ pada lọ si ile ẹjọ yii lo waye lẹyin ti Adajọ Evelyn Anyadika ni ki wọn gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ miiran .

Gomina Abdulfatah ati Banu ni wọn kọkọ ka ẹsun mejila si lẹṣẹ niwaju Onidajọ Anyadika ni ọjọ kọkandinlọgbọn, Oṣu kẹrin ọdun 2024, eyi ti wọn ni awọn ko jẹbi ẹsun naa.

Orukọ gomina tẹlẹ naa wa ninu ẹsun mẹrinla, ti orukọ Banu si wa ninu ẹsun meje ti wọn ka si wọn lẹṣẹ.

Ọkan lara ẹsun naa ti bi gomina tẹlẹ naa se kuna lati kede iye dukia rẹ sinu iwe ti EFCC gbe si ni iwaju eyi ti o tako ofin.

Lara ẹsun na ni pe Gomina Abdulfatah naa owo to le ni bilọnu kan naira to jẹ owo abo ati iṣẹ ilu fi gun baluu pẹlu Travel Messengers Limited .

Gomina ati Kọmisana rẹ ni wọn tun fi ẹsun kan pe wọn gbimọpọ lati ji owo to yẹ ki wọn fi san owo oṣu awọn olukọ ati owo to yẹ ki wọn fi mu idagbasoke ba ilu pamọ.

Igbẹjọ naa bẹrẹ ni ago mẹsan an owurọ ọjọ Aje, ọjọ kọkanlelogun.

Lẹyin ọpọlọpọ atotonu, Adajọ Abdulgafar gba baali gomina tẹlẹ naa ati kọmisana rẹ , Banu pẹlu apapọ owo to jẹ Ọgọrun un milọnu naira ati oniduro meji.

O wa sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrin ati karun un oṣu kejila ọdun 2024.

Ki lo sẹlẹ saaju?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nibi igbẹjọ to waye lọjọ Aje, ọjọ Kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ni Abdulfatah Ahmed yọju sile ẹjọ pẹlu Kọmisanna fun eto isuna ni saa rẹ gẹgẹ bi gomina, Ọgbẹni Ademola Banu.

Awọn mejeeji ni wọn jọ pe lẹjọ onibeji fun sise owo ilu mokumoku.

Ademola Banu ti kọkọ kọ lati yọju sile ẹjọ nibi igbẹjọ akọkọ ti ile ejọ si kede ki ọlọpaa nawọ gan-an fun titapa sofin ile ẹjọ.

Sugbọn ile ẹjọ ti wọgile ikede naa nitori pe o pada yọju lati jẹ ẹjọ rẹ.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party PDP nipinlẹ Kwara ṣe ifẹhonuhan lọ si ileesẹ ajọ to n gbogun ti iwa jìbìtì, ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, (EFCC), to n bẹ niluu Ilọrin lẹyin ti wọn nawọ gan gomina ana nipinlẹ naa.

Iwọde alaafia ọhun lo waye niwaju ọfiiṣi ajọ EFCC, niluu Ilọrin, nibi ti wọn ti n pariwo pe ajọ naa ti rufin, latari pe gomina tẹlẹ naa wa ni akoso wọn kọja ọjọ meji to wa ninu iwe ofin ilẹ wa.

Wọn salaye pe ni se ni o yẹ ki wọn gbe e lọ sile ẹjọ gẹgẹ bi iwe ofin Naijiria ti laa kalẹ.

Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, ni Kwara, Ọgbẹni Oluṣọla Adewara Shollyment, to ṣọrọ niwaju ọga ajọ EFCC, fẹsun pe ijọba ipinlẹ Kwara ati ajọ naa pe wọn lẹdi apo pọ lati fi Maigida si ahamọ ki ara rẹ le rọ, ti yoo si yi ipinnu rẹ pada lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC,

O tẹsiwaju pe ohun to ṣokunfa ifẹhonu yii ni pe, gbogbo awọn n beere fun ki wọn tu gomina tẹlẹ ọhun silẹ ni kiakia nitori pe ẹgbẹ PDP tako bi wọn ṣe fi si akata wọn.

Bakan naa lo ni awọn ti gbọ pe EFCC, ti gbe iwe kan siwaju Ile ẹjọ pe ki wọn lọ fi gomina tẹlẹ ọhun pamọ ṣọgba ẹwọn ṣugbọn kọọtu ko gba si wọn lẹnu, ti wọn si n ṣe idajọ lọwọ ara wọn nipa fifi si ahamọ arawọn.