Tinubu gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Uju-Ken Ohanenye àtàwọn mínísítà mẹ́rin míì

presidency

Oríṣun àwòrán, presidency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti jawe ẹ lọ gbele yin fun marun un ninu awọn minisita rẹ.

Igbesẹ yii lo n waye lẹyin oṣu diẹ ti awọn araalu ti n ke si Aarẹ pe ko gba iṣẹ lọwọ awọn minisita ti wọn ko ṣe dede.

Yatọ si awọn to gba iṣẹ lọwọ wọn, Aarẹ Tinubu tun gbe awọn minisita mẹwaa lati ileeṣẹ ti wọn wa tẹlẹ lọ si awọn ileeṣẹ mii.

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Presidency

Aarẹ gba iṣẹ lọwọ Uju-Ken Ohanenye to jẹ minisita fun ọrọ awọn obinrin; Lola Ade-John to jẹ minisita irinajo afẹ, Tahir Mamman to jẹ minisita eto ẹkọ, Abdullahi Gwarzo to jẹ minisita abẹlẹ fun ile gbigbe ati idagbasoke ilu ati Jamila Ibrahim to jẹ minisita fun idagbasoke awọn ọdọ.

Presidency

Oríṣun àwòrán, Presidency

Lẹyin naa lo fa Bianca Odumegu-Ojukwu kalẹ gẹgẹ bii minisita abẹle fun ọrọ ilẹ okere, Nentawe Yilwatda gẹgẹ bii minisita ọrọ ọmọniyan ati adinku oṣi, o si fi opin si asiko Better Edu, ti wọn ti ni ko lọ rọọkun nile tẹlẹ.

Presidency

Oríṣun àwòrán, Presidency

Tinubu tun fa Maigari Dingyadi kalẹ gẹgẹ bii minisita fun ọrọ iṣẹ, Jumoke Oduwole gẹgẹ bii minisita iṣẹ, Idi Maiha gẹgẹ bii minisita ohun ọsin ti wọn ṣẹṣẹ gbe kalẹ.

Yusuf Ata gẹgẹ bii minisita abẹle fun ọrọ ile gbigbe ati idagbasoke ilu, ati Suwaiba Ahmad gẹgẹ bii minisita abẹle abẹle fun eto ẹkọ.

Presidency

Oríṣun àwòrán, Presidency

Iléeṣẹ́ àṣà, eré ìdárayá, ìdàgbàsókè ẹkùn Niger Delta faragbá nínú àtúntò ráńpẹ́ tí Ààrẹ Tinubu ṣe sí ìgbìmọ̀ ìṣèjọba rẹ̀

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga

Aarẹ Bola Tinubu ati igbimọ ijọba rẹ ti wọgilẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ Niger Delta ati ileeṣẹ to n ri si idagbasoke ere idaraya.

Agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan loju opo X rẹ lọjọbọ.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ijọba ti paarọ awọn ileeṣẹ naa pẹlu awọn ileeṣẹ mii.

O ni “Ni bayii, ohun ti a o ní ni awọn ileeṣẹ idagbasoke agbegbe ti yoo maa ri si awọn ileeṣẹ idagbasoke Niger Delta, ileeṣẹ idagbasoke ariwa iwọ oorun, ileeṣẹ idagbasoke guusu iwọ oorun, ileeṣẹ idagbasoke ariwa ila oorun.”

Onanuga ṣalaye siwaju si pe ajọ to n ri si eto ere idara kaakiri Naijiria ni yoo maa ṣe iṣẹ ileeṣẹ to n ri si ere idaraya bayii.

Ijọba apapọ tun buwọlu isopọ ileeṣẹ to n ri si irinajo afẹ pẹlu ileeṣẹ to n si ri ọrọ aṣa.

Ninu ọrọ Onanuga, inu ipade igbimọ ilu to waye niluu Abuja lonii yii ni wọn ti fẹnuko lori awọn igbesẹ tuntun ọhun.

Wayi o, ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori igbesẹ tuntun naa.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ohun to tọ ti yoo si mu idagbasoke ba Naiiria ni igbesẹ naa jẹ, lawọn mii ni erongba to yatọ nipa rẹ.